Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pàṣẹ pé kí Yahaya Bello fi ara rẹ̀ hàn nílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn jìbìtì N80bn

Oríṣun àwòrán, Alhaji Yahaya Bello/Facebook
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Abuja, olu-ilẹ Naijiria ti paṣẹ fun gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lati jọwọ ara rẹ fun igbẹjọ rẹ to wa niwaju ohun.
Bakan naa ni ile-ẹjọ kotẹmilọrun tun da Yahaya Bello lọwọ kọ lati ma ṣe gbe igbesẹ miran ti yoo tako fifoju ba ile-ẹjọ titi digba ti yoo fi yọju.
Onidajọ Ken Amadi lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Iṣẹgun to kọja lasiko to n tẹwọ gba ẹjọ kotẹmilọrun ti ajo to n gbogun iwa ajẹbanu ati jibiti nilẹ Naijiria, EFCC gbe wa lati tako idajọ Onidajọ Isah Abdullahi Jamil ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kogi nipa ẹjọ ti Bello pe ninu oṣu keji, ọdun 2024 lori ẹtọ rẹ.
Ile-ẹjọ naa ṣakiyesi pe ẹjọ kotẹmilọrun ti agbẹjọro agba, Jibrin Okutepa pe lorukọ EFCC kun oju oṣuwọn, pẹlu bo ṣe sọ pe idajọ ile ẹjọ kekere naa jẹ eyi ti ko bojumu, ati pe niṣe lo n dena Yahaya Bello lati sọ tẹnu rẹ nipa ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
Ile-ẹjọ naa tẹwọ gba awọn koko pataki ti olupẹjọ pe nipa idajọ to ti kọkọ waye nile-ẹjọ giga tipinlẹ Kogi.
O sọ pe onidajọ naa gba ipẹjọ FRN VS. ALI BELLO & ANOR, FHC/ABJ/CR/550/2022 sọwọ, to si ri ohun to wa nibẹ, ṣugbọn sibẹ to tun da Yahaya Bello lara, lori ẹtanjẹ wi pe o ni anfaani si ẹtọ rẹ labẹ ofin.
Bakan naa ni ile-ẹjọ ọhun tun duro lori ipinnu Onidajọ Olubunmi Oyewole JCA in EFCC vs. Alh. Yahaya Bello, CA/ABJ/CV/413/2024 to sọ pe “Ko si ile-ẹjọ to lagbara da awọn ileeṣẹ agbofinro lọwọ kọ lati ṣiṣẹ wọn labẹ ofin.”
Ju gbogbo rẹ lọ, ile-ẹjọ yii wa sọ pe ohun gba gbogbo iwe ẹbẹ EFCC lori ẹjọ kotẹmilọrun naa, to si lọ kun fọnfọn pẹlu ẹri, eyi to mu ko sọ pe ohun gba a wọle.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu Keji, ọdun 2024 ni gomina tẹlẹri naa, Yahaya Bello gba ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kogi lọ lati da ajọ EFCC lọwọ kọ nipa fifi kele ofin gbe oun.
Ninu ipẹjọ lati ni anfaani si ẹtọ rẹ labẹ ofin, Onidajọ Jamil gba ipẹjọ naa wọle, to si gbe aṣẹ kalẹ lati da ajọ EFCC lọwọ kọ nipa bi wọn ṣe fẹẹ gbe Bello.
Ni bayii, ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti wa paṣẹ pe “Ni ibamu pẹlu abala kẹrindinnirinwo-keji (Section 396(2)) ninu iwe ofin onidajọ ọdarana (ACJA), olufẹsunkan to wa ninu ipẹjọ kotẹmilọrun yii, Alaaji Yahaya Bello la paṣẹ fun lati yọju sile ẹjọ lati wa sọ tẹnu rẹ ninu ẹsun FHC/ABJ/CR/550/2022, FRN VS ALI BELLO & ANOR, ko to di pe o gbe igbesẹ kankan lori ẹjọ yii.”















