Wo ìyàtọ̀ tó wà láàrín owó tí ìjọba ń san lórí epo bẹntiróòlù báyìí àti ‘subsidy’ tó yọ kúrò

Aworan ọga agba NNPCL, Mele Kyari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ NNPCL to n ri si ọrọ epo rọbi lorilẹede Naijiria ti sọrọ lori awuyewuye sisan owo iranwọ ori epo bẹntiroolu.

Ọpọ eeyan lo ti n sọ wi pe ijọba ti bẹrẹ si ni san owo iranwọ ori epo bẹntiroolu pada lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu kede ninu ọrọ apilẹkọ rẹ nibi ifilọlẹ ijọba rẹ wi pe ijọba ti yọ owo iranwọ ori epo.

Ṣugbọn ajọ NNPCL ti tan imọlẹ si ọrọ naa lana ọjọ Aje ọjọ kọkandinloogun oṣu Kẹjọ nigba ti o n bawọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.

Lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ọwọngogo epo bẹntiroolu tun ti gbode paapaa julọ niluu Eko ati Abuja.

Ọpọ ile epo ni ko tiẹ ni epo bẹntiroolu ti wọn le ta, nigba tawọn to ni n ta a ni owo gọbọi.

‘’NNPLC ko san ‘subsidy’ fun alagbata epo bẹntiroolu kankan fun oṣu mẹsan an sẹyin’’

Ninu ọrọ rẹ, adari ẹka inawo ajọ NNPCL, Alhaji Umar Ajiya, ṣalaye pe lootọọ ni ajọ naa n gbe epo bẹntiroolu wọle lati ilẹ okeere, ṣugbọn ajọ ọhun ko san owo iranwọ ori epo fun alagbata epo kan kan lati bii oṣu mẹjọ si mẹsan an sẹyin.

Alhaji Ajiya sọ pe ‘’ko si alagbata epo bẹntiroolu kankan to tẹwọ gba owo ‘subsidy’ lọwọ ajọ NNPCL.

Ohun ti o ti n ṣẹlẹ ni pe NNPCL ti n gbe epo bẹntiroolu wọle lati ilẹ okeere eleyii to n ba iye owo kan de.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọ, ijọba apapọ n sọ fun wa pe ki a maa ta epo naa fun araalu pẹlu adinku idaji owo to gbe e de Naijiria.

Iyatọ to wa laarin owo to n gbe epo de Naijiria ati idaji rẹ ti ijọba ni ki a maa ta a fun araalu ni awa n ṣagbatẹru rẹ eyi tawọn oloyinbo n pe ni ‘’shortfall.’’

Alhaji Ajiya ṣalaye pe laarin ijọba apapọ ati ajọ NNPCL ni ọrọ bi awọn ṣe n ta epo bẹntiroolu ni idaji owo to n gbe e de Naijiria wa.

Adari ẹka inawo ajọ NNPCL sọ pe ijọba apapọ maa n fun ajọ naa lowo nigba mii.

Amọ, o tun fidi rẹ mulẹ wi pe NNPCL ko san owo kankan lorukọ owo iranwọ ori epo mọ fun alagbata bẹntiroolu kankan.

Alhaji Aliya fikun ọrọ rẹ wi pe oniruuru ọna ẹyawo lo wa ni ẹka kata-kara epo rọbi lagbaaye.

O ni NNPCL si ti ni ibaṣepọ ati adehun pẹlu awọn to n gbe epo bẹntiroolu ti wọn ti fọ wa si Naijiria lori ati san owo.

Bakan naa ni Ọgbẹni Dapo Segun to jẹ igbakeji aarẹ ẹka ifọporọbi ni ajọ NNPCL sọ pe wiwọ adehun lori ati maa sanwo pẹlu awọn to n gbe epo wa si Naijiria n sọ nipa iru ifọkantan ati igboya ti awọn ileeṣẹ to n gbe epo wa ni ninu ajọ NNPCL.

Ọgbẹni Segun tun sọrọ lori owo ti NNPCL ko tii san fun awọn to n gbe epo wa yii pe ko to N6.8bn ti awọn kan n sọ.

O ni ohun to ṣe pataki ni ibaṣepọ to wa laarin NNPCL atawọn to n gbe epo wa yii.

Eekan ajọ NNPCL naa ṣalaye pe owo yii kii duro soju kan tori o maa n lọ soke lo silẹ ni.

Amọ, o ni ohun to ṣe koko ni pe ki epo bẹntiroolu ti maa wa fun lilo araalu.

Aarẹ IPMAN tẹlẹ sọrọ lori iyatọ laarin owo ti ijọba n san lori epo bayii ati 'subsidy'

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori iyatọ to wa laarin owo iranwọ ori epo ti ijọba yọ kuro ati ohun ti ijọba n san lori epo bẹntiroolu bayii, aarẹ IPMAN, ẹgbẹ awọn alagbata epo bẹntiroolu tẹlẹ ri, Alagba Chinedu Okoronkwo ṣalaye pe nigba ti ijọba n san owo iranwọ lori epo bẹntiroolu, o ni iye kan naa lawọn eeyan gbọdọ maa ra epo kaakiri Naijiria.

‘’Amọ, lọwọ yii, ko si ohun to jọ bayẹn mọ tori ijọba ti yọ owo iranwọ ori epo.

Eyi n sọ fun wa nipa akitiyan ijọba lati ri pe epo bẹntiroolu ko wọn ju fawọn araalu lati ra.

Lootọọ ni wi pe ko si owo iranwọ ori epo mọ, amọ, ijọba lo n fara gba owo ti ko jẹ ki owo epo bẹntiroolu wọn ju agbara awọn eeyan lọ.

Iye ti wọn ba n ta epo lọja ni awa alagbata n ra a bayii ti a fi n ri epo ta,'' Ọgbẹni Okoronkwo lo sọ bẹẹ.