'Àwọn jàndùkú ti gbàkóso ìlú wa, inú ilé wa ni wọ́n ń gbé, àwọn ló ń dá oko wa'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Niger sọ pe awọn janduku ti n gbe inu ile awọn araalu Alawa bayii, ti awọn janduku naa si ti jogun oko wọn.
O ti le ni oṣu marun un gbako ti awọn janduku naa ti gbajọba ilu Alawa ti wọn si le gbogbo awọn olugbe ibẹ sinu igbo.
Ọkan lara awọn olugbe ilu ọhun to ba BBC sọrọ sọ pe iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ijọba apapọ ko awọn ologun kuro nibẹ latari pe o fẹ ko awọn mii wa amọ ijọba ko ṣe bẹẹ.
O ni “titi di akoo yii, ijọba ko tii ko awọn ologun mii wa.
“Nigba ti a fi maa lọ sile, a ri pe wọn ti tu gbogbo ile wa yẹlẹyẹlẹ, wọn ji oogun ajilẹ ti a ni sile, awọn janduku naa lo n da oko wa bayii.”
Ọpọ igba lawọn janduku maa n kọlu ipinlẹ Niger ọhun to fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ipinlẹ Kaduna ati Kebbi.
Gẹgẹ bii ohun ti araalu naa sọ, ijọba ti kuna ninu ileri to ṣe fun awọn lori eto abo.
Ọkunrin naa, ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe awọn ko ni ireti kankan pe awọn yoo ṣi le pada sile wọn.
Amọ ṣa, ijọba ipinlẹ Niger ti sọ pe ko si ohun to jọ pe awọn janduku gba ilu kankan lọwọ oun.
Ki ni ijọba sọ?
Kọmiṣọna eto abo ipinlẹ naa, Bello Muhammad sọ pe lootọ ni awọn eeyan ilu ọhun ko si ninu ile wọn mọ, ṣugbọn irọ ni pe awọn janduku ti gbakoso ilu naa.
O ni “ti wọn ba n dako nibẹ, a maa lọ fi ṣikun ofin mu wọn.
“Bi awọn ologun ko ba tilẹ si nibẹ gan, gbogbo igba ni wọn n paara ibẹ, ko si agọ awọn janduku kankan ni ipinlẹ wa.”
Yatọ si awọn araalu ti awọn janduku n kọlu nipinlẹ Niger, wọn tun n kọlu awọn ologun naa pẹlu.















