Àwọn wo ni 'Ẹ̀gbọ́n Àdúgbò' tó n lépa Portable

Oríṣun àwòrán, Portable/Screenshot
Habeeb Okikiọla Badmus, gbajumọ akọrin takasufe, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Portable lo tun ti bọ sori ikanni ayelujara lati fi ẹsun kan awọn kan to pe ni ‘Ẹgbọn Adugbo’, to sọ pe wọn n dunkooko mọ oun.
Portable lori Instagram rẹ laipẹ yii jẹ ko di mimọ pe awọn ‘Ẹgbọn Adugbo’ naa yabo oun ati awọn ọmọ ẹyin oun, ti wọn si lu awọn nilukulu.
Ninu fọnran ti ọdọmọkunrin ti wọn tun n pe ni Idaamu Adugbo naa gbe sita, o sọ pe ibi toun ti lọ kọrin lagbegbe Iju-Ishaga nipinlẹ Eko ni awọn eeyan naa ti wa lati da ibẹ ru.
O ni ọrẹ oun kan to n ta mọto loun lọ ba ṣe ayẹyẹ, toun si tun kọrin nibẹ pẹlu, ko to di pe wọn kọlu awọn.
Portable ni niṣe lọrọ di ẹni ori yọ, o di ile, toun si sa asala fun ẹmi ara oun, ṣugbọn to loun ko tii ri awọn ọmọ ẹyin oun yooku.
Bakan naa lo sọ pe kii ṣe pe awọn ‘Ẹgbọn Adugbo’ naa lu awọn nikan, bi ko ṣe pe wọn tun ja ẹgba ọrun oun ati awọn dukia miran to jẹ olowo iyebiye gba.
O tẹsiwaju pe wọn ji foonu iPhone meji ọtọọtọ to jẹ ti ọkan lara awọn manija oun, to fi mọ ATM, mọto ati awọn dukia miran.
Ninu ọrọ to kọ lo ti sọ pe “Wahala, iṣẹlẹ nla lagbegbe Iju Iṣaga nibi ti a ti lọ ṣajọyọ pẹlu @lincon_orn to n ta mọto ... Ninu adugbo ti a wa, ti a ti n ṣere ni awọn kan ti wọn pe ara wọn ni Ẹgbọn Adugbo wọle wa, ti wọn si kona iya fun wa.
“A ṣi n wa awọn bọisi ZEHNATION oo.. wọn kọlu awọn ọmọ ẹyin mi lẹyin ti mo na papa bora ... ki @lincon_orn ba wa sọ fun Ẹgbọn adugbo lati da iPhone meji to jẹ ti @iam_sexyshay ati kaadi ATM mi pada..
“A ri awọn foonu ati mọto @dullarboi … ṣugbọn a ko ri oun funra rẹ…Nko tii ri @bamidola_, a gbọ pe wọn kọlu oun naa .. awọn akọrin mi niyẹn ti a ṣi n wa wọn oo.
“Ọlọrun ko nii doju ti wa, eeyan burku ni awọn wọnyi, bi wọn ṣe lọ mi lọwọ gba niyẹn. Awọn Ẹgbọn adugbo yii gba ṣeeni (ice chain) mi, wọn tun gba iyẹri eti to jẹ goolu mi, lẹyin ti mo fi ifẹ han si gbogbo wọn, ti mo si fun wọn lowo mi, wọn tun fẹẹ gba baagi mi ... Ṣe ọta ni wọn ni abi ololufẹ”.















