Ayantunde, ọmọ orílẹ̀èdè Germany tó ń fi ìlù gáǹgan dárà káàkiri àgbàyé

Àkọlé fídíò, Ayantunde, ọmọ orílẹ̀èdè Germany tó ń fi ìlù gáǹgan dárà káàkiri àgbàyé
Ayantunde, ọmọ orílẹ̀èdè Germany tó ń fi ìlù gáǹgan dárà káàkiri àgbàyé

Ni ilẹ Yoruba, lara awọn aṣa to da ẹya Yoruba yatọ ni eto igbafẹ ati idanilaraya rẹ. Bẹẹni lara awọn ohun to mu u da yatọ naa ni ilu gangan. Ko si ibikibi ti a ba ti ri ilu gangan lorilẹ agbaye ti kii ṣe iran Yoruba lo kọkọ maa n sọ lọkan ẹni to ba ri iran bẹẹ.

Amọṣa o, ni ilu Vienna lorilẹede Austria, BBC Yoruba ri iran ara ọtọ nibi ti arakunrin oyinbo kan ti n lu ilu gangan ni alugbadun.

Ọmọ orilẹede Germany ni Ayantunde Akano. Alawọfunfun ni amọṣa. Ede Yoruba dantọ lẹnu rẹ bi ẹni wọn bi si ilẹ Ifẹ ni.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ayantunde ṣalaye pe oun ni Oloye Agbaṣaga ilẹ Yoruba, ni ibi gbogbo ti oun ba si ti wa ni oun maa n rii gẹgẹbi ojuṣe wi pe ina aṣa Yoruba ko jo ajorẹyin.

‘Lati ọdun 1996 ni mo ti n lu ilu Yoruba’

Ayantunde pẹlu awọn ọmọ Yoruba nibi ọdun Adirẹ ni Vienna lorilẹede Austria.

Oloye Ayntunde Akano ṣalaye siwaju sii pe lati ọdun 1996, iyẹn ọdun mejidinlọgbọn sẹyin loun ti n lu ilu gangan.

O ni ifẹ ti oun ni si orin ilẹ Afirika lo sun oun de idi ilu Yoruba paapaajulọ ilu gangan.

O ni bi ilu Yoruba ṣe maa n fọhun bi eniyan ti awọn onilu ba ti kọngọ bọlu lo jẹ ki oun tubọ fẹran ilu Yoruba ju ilukilu lọ.

Ayantunde ni yatọ si gangan, oun a tun ma a lu awọn ilu Bata bii, iya ilu Bata ati omele mẹta bata.