Ṣé abẹ́rẹ́ àjẹsára wà fún àrùn Mpox?

Ọwọ kan to wọ ibọwọ mu igo kékeré kan ti wọn lẹ ọrọ "mpox virus" sara rẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Natasha Preskey
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kokoro àrùn tuntun mii lati ara àrùn Mpox ti ṣe pa ọgọọrọ eeyan ni orílẹ̀ede Democratic Republic of Congo (DRC), ti ọwọja arun naa si ti tan kaakiri aarin gbungbun ati ila oorun Áfíríkà.

Ni ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, àjọ eleto ìlera ni agbaye, (WHO) kede àrùn náà gẹ́gẹ́ bíi àrùn to nilo amojuto pajawiri yika agbaye.

Kokoro aifojuri tuntun kan, ti wọn pe ni Clade 1b, ti ọwọja rẹ buru pupọ to n jẹ jade lati ara àrùn Mpox, si lo fa akọtun àrùn Mpox yìí.

Àjọ WHO si ti fi ọwọ idaniloju sọya pe oun yoo ri daju pe awọn abẹ́rẹ́ àjẹsára de àwọn àgbègbè to nilo wọn, lọ́nà ati tètè wa ọwọja itankalẹ àrùn náà bọlẹ.

Àmọ́ kí ni a mọ nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn Mpox, àti pé, irufẹ àwọn èèyàn wo lo yẹ ko gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà?

Ṣé abẹ́rẹ́ àjẹsára wà fún àrùn Mpox?

Orisi abẹ́rẹ́ àjẹsára méjì ni àjọ WHO dábàá fún àrùn Mpox -ti a mọ si àrùn Monkey Pox tẹ́lẹ̀ - àmọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀ede ni ko tii fontẹ lu lilo wọn.

Àjọ WHO daba abẹ́rẹ́ àjẹsára MVA-BN tàbí LC16, àbí ACAM2000 nigba ti awọn abẹ́rẹ́ àjẹsára yoku ko ti si ni arọwọto.

Ni ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, àjọ náà ṣe agbende lilo abẹ́rẹ́ àjẹsára fún itọju pajawiri fún àrùn Mpox kò le ṣe iranwọ fun àwọn orílẹ̀ede tí owó to n wọle sapo wọn kere jọjọ, ti wọn ko tii fontẹ lu lilo abẹ́rẹ́ àjẹsára náà, le ni anfaani si wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pinpin àwọn orílẹ̀ede sì iṣọri-iṣọri yìí túmọ̀ sí pe awọn àjọ bíi Unicef àti Gavi le e kóra jọ láti pín àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.

Àjọ WHO ko máa daba igbesẹ gbigba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ọgọọrọ eeyan. Àmọ́ o n daba pe abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí lee dojú kọ àwọn ènìyàn to wa ninu ewu pe o seese ki wọn tete lugbadi arun naa, àwọn ènìyàn tó ti fara kinra pẹlu àwọn alárùn Mpox àti àwọn olùgbé agbegbe ti àrùn náà tí bẹ silẹ.

Bákan náà ni àjọ WHO ni ẹni kan le gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà tí àjọ to ń ṣe akoso eto ìlera rẹ ba ri pe ẹni náà wa ninu ewu pe o le ko àrùn náà torí ìlànà irinajo to fẹ́ rìn.

Ni ọ̀sẹ̀ to kọjá, àjọ to ń dènà itankalẹ àrùn àti akoso rẹ nilẹ Yúróòpù, (the European Centre for Disease Prevention and Control, ECDC) daba pe káwọn arìnrìn-àjò ni lérò láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọn ba n gbèrò láti wa sáwọn agbegbe ti àrùn ọhun wa nilẹ Áfíríkà.

Àwọn ènìyàn tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà sẹ́yìn kan nílò láti gba ṣọọti abẹ́rẹ́ kan ṣoṣo kún èyí tí wọ́n ti gbà dípò kí wọn gba ṣọọti abẹ́rẹ́ méjì.

Àfikún abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí ni wón máa ń daba rẹ láàárín ọdún méjì si mẹwa ti enikan ba seese ko wa ninu ewu kiko àrùn náà.

Ṣé abẹ́rẹ́ àjẹsára àtijọ́ tí wọn fi ń wo àrùn Ẹ̀yi le e sisẹ fun ààbò lọ́wọ́ àrùn Mpox?

Kokoro aifojuri kan to jẹ mọlẹbi àrùn Ẹ̀yi (Smallpox) lo n fa àrùn Mpox.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára to ń dènà àrùn Ẹ̀yi, táwọn àgbàlagbà kan tí gba sẹ́yìn, naa le ṣètò idaabo bo.

Àjọ WHO kedere pé wọn tí wa ọwọja arun Ẹyi bọlẹ lọdun 1980 (àrùn to n tan kalẹ kan ṣoṣo tí wọn tí fún ní ipò yìí) tí wọn sì ti dẹkùn fífún àwọn ènìyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí o le ni ogójì ọdún sẹ́yìn.

Ṣé abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn Mpox tó tó wà bí?

Ọmọ ọdún mẹ́fà tí wọ́n fura si pe àrùn Mpox ń ba finra, jókòó lórí ibùsùn nibudo ìlera Yalolia health centre, Tshopo, ní orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo, lọ́jọ́ Kẹwàá, oṣù kẹwàá, ọdún 2022.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ibùdó to wà fún ìdènà itankalẹ àrùn àti akoso rẹ nilẹ Áfíríkà, tí ni òun ni "eto tó ye kooro" láti gba miliọnu mẹwa abẹ́rẹ́ àjẹsára náà kì ọdún 2025 to parí.

Orílẹ̀ èdè DRC àti Nàìjíríà yóò bẹ̀rẹ̀ gbigba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà lọsẹ to n bọ, ti orílẹ̀ èdè DRC yóò sì máa lo abẹ́rẹ́ àjẹsára láti ilẹ Amẹ́ríkà àti Japan, tí Naijiria yóò sì gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tiẹ̀ láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Minisita feto ìlera ni orílẹ̀ede Democratic Republic of Congo, Roger Kamba, ní àwọn ọmọdé ni yóò kọ́kọ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà nítorí ọwọja itankalẹ àrùn Mpox láàárín àwọn ọmọdé tó wà ní ọmọ ọdún mẹẹdogun wa si ìsàlẹ̀ tí ga pupọ.

Ibùdó tó ń dènà itankalẹ àrùn àti akoso rẹ nilẹ Áfíríkà ti ní òun ti ṣe àdéhùn pẹlu ileisẹ kan nilẹ Denmark ti wọn n pe ni Bavarian Nordic lati lo àwọn imọ ẹ̀rọ ìgbàlódé rẹ fi ṣe àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ilẹ Áfíríkà.

Àjọ WHO sọ fún àwọn ileesẹ to ń pèsè oogun laipẹ yìí pe ki wọn sagbekalẹ àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọn pèsè fún ìlò pajawiri, kódà, bí wọn kò bá tíì fi ontẹ lu àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára náà fún lilo.

Orílẹ̀ede Nàìjíríà ni òun ń reti láti tẹwọ gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá iṣọri àkọ́kọ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára láti ọ̀dọ̀ ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́jọ́ Isẹgun.

Orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ni ijọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ṣèlérí láti fún òun ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta abẹ́rẹ́ àjẹsára náà nígbà tí ilẹ Japan ni òun yóò gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára to to miliọnu mẹta àti aabọ silẹ.

Ṣé abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn Mpox ń ṣiṣẹ́ bí?

Àjọ WHO ni abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn Mpox "ń pèsè ipele aabo kan láti dènà kiko àrùn náà àti àrùn to burú gidi."

Ṣáájú nínú ọ̀sẹ̀ yìí, Olùdarí ẹkùn fún àjọ WHO nilẹ Yúróòpù, Dókítà Hans Kluge, ní àrùn Mpox kii "ṣe àrùn Covid-19 tuntun" - lai naani kòkòrò aifojuri tuntun to jẹyọ lati ara àrùn náà - nítorí àrùn náà ṣe e ṣe akoso láti ipasẹ igbesẹ ìlera aráàlú tí kò ní iyapa - igbesẹ ìlera àti nini anfaani sí gbigba abẹ́rẹ́ àjẹsára.

Àjọ WHO wa gba àwọn ènìyàn tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn Mpox ní ìmọ̀ràn láti ṣọraṣe, kí wọn yàgò fún kiko àrùn naa tàbí ṣe itankalẹ rẹ, nítorí ó máa ń gba to ọpọlọpọ ọ̀sẹ̀ kí wọn to ni àjẹsára láti dènà kiko àrùn náà lẹ́yìn tí wọ́n bá gba abẹ́rẹ́ tán.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára náà sì lè ma sisẹ lára èèyàn díẹ̀.

Ti wọn ba tiẹ̀ kò àrùn Mpox lẹ́yìn tí wọ́n ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára, síbẹ̀ abẹ́rẹ́ naa yoo si pèsè ààbò tako ọwọja arun naa to burú pupọ àti wíwà lórí ibùsùn nílé ìwòsàn.