Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe rí òkúta iyebíye tó tóbi jùlọ kejì nílẹ̀ Afrika

Oríṣun àwòrán, Lucara Diamond
Wọn ti ṣawari okuta iyebiye to wa ni ipo keji eyii to tobi julọ lagbye lorilẹede Botswana.
Iye iwọn okuta iyebiye naa jẹ 2,492 karaati.
Okuta iyebiye ọhun ni ekeji iru rẹ lẹyin eyii ti wọn kọkọ ṣawari ni South Africa lọdun 1905, lara eyii ti wọn ge ti wọn si lo fun ade ọba ilẹ Gẹẹsi.
Oriko iwakusa Karowe, to wa ni nnkan bii ẹẹgbẹta kilomita si ilu Gaborone, to jẹ olu ilu ilẹ naa, ni wọn ti ri.
Ijọba orilẹede naa sọ pe okuta ọhun ni iru rẹ to tobi ju ti wọn yoo ṣawari nibẹ.
Eyii to tobi bii rẹ ti wọn kọkọ ri nibi iwakusa kan naa ni wọn ri lọdun 2019.
Botswana wa lara awọn orilẹede ti wọn ti maa n ri okuta iyebiye julọ lagbaye, ida ogun okuta iyebiye agbaye lo si wa lati orilẹede naa.
Adari ileeṣẹ Lucara Diamond to ri okuta naa, William Lamb sọ pe inu awọn dun pe awọn ri okuta iyebiye ọhun.
O ni ẹrọ igbalode ti wọn fi n wa okuta iyebiye ni wọn fi ṣawari rẹ.
Amọ ṣa, ileeṣẹ naa ko mẹnuba iye owo idiyele okuta iyebiye naa.
Ẹwẹ, owo to le ni $53m ni wọn ta okuta iyebiye to ni iwọn 1,109 fun ileeṣẹ Graff Diamonds, niluu London.
Ibi iwakusa yii kan naa ti wọn ri okuta ọhun lọdun 2016, ti wọn si ta a lọdun 2017.















