Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Lori Ko Ṣe e ma gbọ ọ wa fun ti ọsẹ yiii…

Odun Isese waye kaakiri ilẹ Yoruba lọjọ Iṣẹgun

Oniruuru ara isembaye ati adura sawọn alalẹ lawọn oniṣẹse gbe kalẹ lasiko ajọdun naa

Ipinlẹ Osun, Oyo, Eko Ekiti ati Ogun ni ayajọ yii ti waye titi kan oke okun

Koda, awon onisese ni ipinlẹ Kwara pẹlu ko gbẹyin

Mo tilẹ gbọ pe wọn fohun silẹ fawọn oba to n tako ẹsin iṣẹṣe

Bẹẹni, awọn oniṣẹse nipinlẹ Osun ni awọn yoo fi gbogbo agbara wọn ba iru oba bee ja ni

Gbogbo ileri ti wọn ṣe wa loju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

Awọn ọmọ Naijiria kan ti bẹrẹ si n sokọ ọrọ si ijọba apapọ lẹyin to ra baalu tuntun fun Aarẹ

Wọn ni pẹlu bi ilu ṣe kan gogo yii, ṣe baluu rira lo kan abi kinla

Ijoba apapọ Naijiria ra baluu tuntun naa lẹyin ọjọ diẹ ti araalu ṣe iwọde ‘ebi n pa wa’

Amọ ijọba ti fesi pe baalu naa ṣe pataki lasiko yii nitori ọjọ ti lọ lori baalu ti Aarẹ n lo tẹlẹ

Ti ẹ ba fẹ mọ bo ṣe n lọ….