Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ ìdí àti ìwúlò wọn

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọ awọn obinrin ode isin yii ni wọn fẹran lati ma wọ ilẹkẹ si ibebe idi fun orisirisi idi sugbọn eyi to jẹ gbajumọ ni fun sise oge.
Ilẹkẹ idi ṣe pataki fun obinrin de bi pe iru ilẹkẹ ti obinrin ba wọ ni yoo ṣọ bí yoo ṣe maa da awọn ọkunrin lọrun si.
Sugbọn lodi isin yii, ileke idi jẹ ohun to n ba ọpọ ọkunrin lẹru, de pe wọn ko ki n fẹ sumọ obinrin to ba lo ileke si ibadi.
Ọpọ ọrọ ti a ko le fidi rẹ mulẹ lo wa lori ayelujara nibi ti ọpọ ti ṣapejuwe ileke idi gẹgẹ bii ohun ti obinrin n lo lati de ọkunrin mọlẹ tabi lati ma fi gba owo lọwọ ọkunrin.
Orisun ilẹkẹ wiwọ
Ọjọ ti pẹ ti awọn eeyan ti n lo ilẹkẹ.
Koda ilẹkẹ ti wa lati ọdun 15th sẹntiuri.
Ọpọ awọn onimọ gbagbọ pe ilẹkẹ wiwọ lati orilẹ-ede Egypt laye ọjọ-un
Wọn ní awọn obinrin to rẹwa lo maa n wọ ilẹkẹ nigba naa fún oge.
Lapa iwọ oorun ilẹ Afrika, awọn onkọtan ni awọn Yoruba lo sọ ilẹkẹ wiwọ di gbajugbaja.
Wọnyii ni iwulo ilẹkẹ ibadi ni wiwọ fawọn obinrin:

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkọ lara iwulo ileke ni lati fi se ami wi pe obinrin ni wọn, to si ma n mu da yatọ lawujọ ní ọpọ fi maa wọ ilẹkẹ si ibadi.
Ọkọ tabi ololufẹ obinrin to ba wọ ilẹkẹ ni yoo riri ilẹkẹ wiwọ julọ. Ọpọ obinrin gbagbọ pe ileke ma n da ololufẹ wọn lọrun pupọ.
Bakan naa, Ilẹkẹ wiwọ tun maa n ṣe afihan pe ọdọmọbìnrin ti to ile ọkọ lọ.
Ilẹkẹ wiwọ tun le tumọ si pe ọdọmọbìnrin le ni afẹsọna.
Abilekọ to ba n wọ ilẹkẹ oni woroworo tumọ si pe ko ti pẹ to fi ṣe igbeyawo.
Wọn tun maa n wọ ilẹkẹ fun ọmọ ikoko lọjọ suna
Eyi wa lati jẹ ki ibadi ati itan ọmọ naa dagba daadaa.
O le jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan pe ilẹkẹ wiwọ si ibadi maa n wo aisan papaa julọ awọn ilẹkẹ to ba mi okuta iyebiye nidi.
Laye ode oni, eeyan perete lo maa n wọ ilẹkẹ si ibadi ṣugbọn maa n wọ ilẹkẹ si ọrun ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ kan tabi omiran.















