Iléẹjọ́ dá obìnrin tó n ṣe bí ọkùnrin láre lórí bí iléeṣẹ́ kan ṣe fi ẹ̀tọ́ obìnrin dùn ún

Oríṣun àwòrán, EPA
Obinrin kan to n ṣe iṣe ọkunrin lo ti bori ẹjọ kan to pe lati tako ikanni ayelujara ti awọn obinrin nikan, eyi ti wọn ni ko lẹtọọ lati wa nibẹ, nitori ti wọn sọ pe ọkunrin ni.
Ileẹjọ giga apapọ ti ṣakiyesi wi pe kii ṣe pe wọn tako Roxanne Tickle loju koroju bi ko ṣe pe ọna ẹyin ni wọn gba tako o – eyi to tunmọ si wi pe nigba ti ipinnu kan tabi eeyan paapaa nipa iṣesi kan – to si paṣẹ pe ki ikanni naa san owo to to A$10,000 ($6,700; £5,100) fun un gẹgẹ bii gba mabinu.
Idajọ to ni apẹẹrẹ rere nla eleyi jẹ to ba ti di ọrọ idanimọ akọ si abo, ti pe lọkan ẹjọ naa, awọn ibeere to maa n waye ni ‘taa ni obinrin?’
Lọdun 2021, Tickle gba ikanni kan ti wọn pe ni “Giggle for Girls” sori ẹrọ ibainsọrọ rẹ, ikanni ti wọn polowo fun awọ to wa aabo wa, nibi ti awọn obinrin ti le sọ iriri wọn nibi ti aabo wa, ti wọn ko si gba awọn ọkunrin laaye nibẹ.
Lati le ni anfaani sinu ikanni naa, o ni lati fi aworan rẹ nipa iru ẹni to jẹ sibẹ lati le mọ pe obinrin ni lotitọ, eyi ti imọ ẹrọ ti wọn ṣe lara ọtọ yoo ti ṣe ayẹwo idanimọ lati le ẹni to ba jẹ ọkunrin danu.
Ṣugbọn ṣa, lẹyin oṣu keje – lẹyin to ti darapọ mọ ikanni naa – niṣe ni wọn lee danu kuro nibẹ.
Gẹgẹ bi ẹni to n ri ara rẹ bi obinrin, Tickle sọ pe oun lẹtọ labẹ ofin si ohun to nii ṣe pẹlu obinrin, ati pe niṣe ni wọn fi ẹlẹyamẹya si ọrọ oun.
Eyi lo jẹ ko gbe ikanni naa lọ sile ẹjọ, to fi mọ oludasilẹ rẹ, Sall Grover, to si n beere fun A$200,000, pẹlu bo ṣe jẹ ko di mimọ pe bi ikanni naa ko ṣe faaye gba oun ti mu “oriṣiriṣi erokero ati ipororuru ọkan ba oun bii eyi to le jẹ koun deedee pinnu lati gba ara oun.”
“Awọn ọrọ Grover n kọ jade nipa mi n doju ti mi, o n ba iru eeyan ti mi jẹ jẹ, to si n mu ọgbẹ ọkan ba mi. Eyi si ti jẹ ki awọn eeyan maa kọ oriṣiriṣi ọrọ lati tako mi, to si n ro awọn miran lagbara lati maa wo awokọṣe rẹ,” Tickle sọ eyi ninu iwe to kọ.
Awọn igbimọ igbẹjọro Giggle sọ pe ẹya eeyan nii ṣe pẹlu ohun ti a n pe ni agbekalẹ biology (biological concept).
Wọn gba pe lotit]o ni wọn ya Tickle sọtọ - lori idi ti wọn pe ni iru eeyan to jẹ, dipo ohun to gbe sabẹ.
Nipa bi wọn ko ṣe gba Tickle laaye lori ikanni naa ṣagbekalẹ aala to wa laarin akọ ati abo, wọn sọ bẹẹ. Wọn ṣagbekalẹ ikanni naa lati yọ awọn ọkunrin kuro, ati pe nigba ti awọn alakoso ṣawari Tickle gẹgẹ bi ọkunrin – wọn ni bi wọn ṣe lee kuro lọ nibamu pẹlu ofin.

Oríṣun àwòrán, Giggle/Facebook
Ṣugbọn Onidajọ Robert Bromwich sọ ninu ipinnu rẹ lọjọ Ẹti wi pe ofin ti fi gbogbo igba sọ wi pe ẹya eeyan ṣee yipada, to si tako awijare Giggle.
Tickle jẹ ko di mimọ pe idajọ naa “ṣafihan pe gbogbo obinrin ni wọn wa labẹ abo ẹya” ati pe oun ni ireti pe ẹjọ naa yoo mu “ilera ba iru awọn ẹya to ni nnkan akọ ati abo laarin gbogbo eeyan.”
“Ju gbogbo rẹ lọ, a gba idajọ ti a ti n foju sọna fun. Ijamgbara fun awọn obinrin tun ṣi n tẹsiwaju,” Grover kọ ọ soju opo ‘X’ rẹ nigba to n dahun si ipinnu ile-ẹjọ.
Ti a mọ si “Tickle vs Giggle”, eyi ni ẹjọ akọkọ iru ẹ ti iru igbẹjọ yiya ẹya kan sọtọ to nii ṣe pẹlu akọ ati abo yoo waye nile-ẹjọ giga apapọ tilẹ Australia.
O ti wa ṣafihan nipa akori to ti n jẹyọ lọpọ igba, to si ti fa ariyanjiyan nipa ẹya akọ ati abo ati ẹtọ onikaluku labẹ, ti yoo si ni ipa to maa ko nile ẹjọ.
Gbogbo eeyan ni wọn n tọju mi bi obinrin
Ẹya ọkunrin ni wọn bi Tickle, ṣugbọn to yi ẹya rẹ pada si obinrin, igbe aye to ti n gbe lati ọdun 2017.
Nigba to n fi ẹri rẹ han niwaju ile-ẹjọ, o ṣo pe “Titi di asiko yii, bi obinrin ni gbogbo eeyan ṣe n ṣe mi.”
“Loore-koore ni mo maa n koro oju, ti mo si maa n woye nipa ibeere awọn lori bi wọn ṣe n wo mi, eyi to maa n kọ mi lominu...ṣugbọn wọn maa n jẹ ki n ba iṣẹ oojọ mi lọ.”
Ṣugbọn Grover gbagbọ pe ko si eniyan naa to le yi ẹya rẹ pada kuro ni bo ṣe wa saye, eyi to lo jẹ gbongbo iṣẹda to ta koko.
Nigba ti agbẹjọro Tickle, Georgina Costello KC ṣagbeyẹwo ohun ti Grover sọ, o ni:
“Koda bi ẹni ti a bi gẹgẹ bi ọkunrin ba sọ ara rẹ di obinri nipa iṣẹ abẹ, ayipada agọ ara, lilọ fun iṣẹ abẹ oju, wiwu irun to gun, lilo ohun atun-oju ṣe, wiwọ aṣọ obinrin, ti wọn n pe ara wọn ni obinrin, ti wọn n jẹ ki awọn eeyan mọ pe obinrin ni awọn, ti wọn n lo yara ipaarọ fawọn obinrin, yiyi iwe ibi wọn pada, ṣe o ko tilẹ tun gba pe obinrin ni ẹni naa?”
Grover sọ pe “Rara”.
O tilẹ tun sọ pe oun yoo ṣi tun maa kọ lati ri Tickle gẹgẹ bi “Arabinrin”, ati pe “Ọkunrin ni iṣẹda Tickle.”

Oríṣun àwòrán, EPA
Grover jẹ ẹnikan to n pe ara rẹ ni ‘TERF’ – eyi to tunmọ si “trans-exclusionary radical feminist.” Awọn agbeyẹwo TERF nipa iru eeyan pọ loriṣiriṣi lati mu awọn eeyan sigbekun.
“Ẹnikan to jẹ ọkunrin, ṣugbọn to n pe ara rẹ ni obinrin lo gbe mi lọ sile ẹjọ giga apapọ nitori to fẹ maa lo anfaani kan ṣoṣo to wa fun awọn obinrin,” ohun to kọ soju opo ‘X’ rẹ ree.
“Ko tii si obinrin ọhun lagbaye to le gbe mi lọ sile ẹjọ lori nipasẹ ikanni yii. Ọkunrin nikan lo wu iru ẹjọ bayii dide.”
O sọ pe ọdun 2020 loun da ikanni ayelujara naa to pe ni “Giggle for Girls” silẹ, lẹyin to ti gba ọpọlọpọ adojukọ lati ọdọ awọn ọkunrin lori ayelujara nigba toun ṣi n ṣiṣẹ gẹgẹ bi onkọwe ni Hollywood
“Mo fẹẹ da agbegbe ti aabo silẹ, agbegbe fun awọn obinrin nikan ni ikawọ rẹ,” o ṣalaye.
“O jẹ ohun irori ẹni wi pe Tickle jẹ obinrin. O ti ṣe ipaarọ iwe ẹri ọjọ ibi rẹ lati ọkunrin si obinrin, ṣugbọn iṣẹda jẹ ti ọkunrin, ti yoo si maa ri bẹẹ lọ.”
“A n duro lori aabo ati ẹtọ awọn obinrin lori ikanni yii, ṣugbọn fun ohun to foju han ati otitọ, eyi ti ofin naa duro fun.”
Grover ti tilẹ sọ pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ipinnu ile-ẹjọ naa, toun yoo si tako ẹjọ n aa titi de ile-ẹjọ giga nilẹ Australia.
Ojusaaju ofin
Idajọ naa ṣafihan ojusaaju fun iyanju si awuyewuye nipa ẹtọ idanimọ ẹya eeyan ati irufẹ nnkan ọmọkunrin ati ọmọbinrin lawọn orileede miran.
Lati ni oye kikun lo mu ipade gbogboogbo waye ti wọn pe ni Elimination of Discrimination Against Women (CEDAW). Eyi jẹ ipade agbaye ti ajọ iṣọkan agbaye (UN) wọn buwọ lu lọdun 1979 – to si fẹsẹ mulẹ nipa ẹtọ awọn obinrin lagbaye
Itako Giggle jẹ ko di miọ pe agbekalẹ CEDAW sọ pe wọn ni lati daabo bo ẹtọ awọn obinrin, to si mọ ẹni to ni ẹya kan ṣoṣo labẹ.

Oríṣun àwòrán, Grata Fund
Fun idi eyi idajọ toni to da Tickle lare yoo ni apẹẹrẹ nla si awọn orileede mọkandinlaadọwa (189) nibi ti wọn ti gbagbe ofin CEDAW – lati Brazil ti India si South Africa.
To ba ti di ọrọ atupalẹ ati itunmọ, awọn ile ẹjọ ilẹ kọọkan maa n ṣagbeyẹwo awọn ohun ti w]ọn ti ṣe tẹlẹ lawọn orileede miran.
Itumọ idajọ Australia to ni ọpọlọpọ aofjusun awọn ileeṣẹ akọroyin yii yoo ni atubọtan ipa ti yoo ko lagbaye.
Bi awọn ile ẹjọ ba tubọ n da irufẹ ẹjọ bawọnyi – o tunmọ si pe ohun ti awọn orileede yooku yoo maa tẹle niyẹn.















