Mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tó lé gbé tó bá jẹ́ oúnjẹ tó ní májèlé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bi ọjọ mẹta yii, iroyin nipa bi awọn eeyan se n padanu ẹmi nitori bi wọn se jẹ ounjẹ to ni majele ninu lo n ba ọpọ lẹru, paapa ni apa oke ọya orilẹede Naijiria.
Laarin oṣu kan, o le ni eeyan mẹrinlelogun to ti padanu ẹmi wọn nipinlẹ Sokoto ati Zamfara,c lẹyin ti wọn jẹ majele.
Ọpọ lo ti sọ pe iṣẹlẹ yii n waye nitori bi ọwọngogo ṣe gbode lasiko yii lorilẹede Naijiria, ti wọn ko si owo lati ri ounjẹ to dara ra fun ago ara.
Eeyan mẹfa padanu ẹmi wọn lẹyin ti wọn jẹ Amala ti iyale le se fun wọn jẹ nipinlẹ Sokoto.
Ninu ile kan naa, eeyan mẹfa mii tun padanu ẹmi wọn lẹyin ti wọn jẹ ounjẹ tan.
Ọkọ, iyawo ati awọn ọmọ marun lo padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ naa.
Ẹwẹ, eeyan mejila mii tun padanu ẹmi wọn ni agbegbe Daki Akwas ni ijọba ibilẹ Anka nipinlẹ Zamfara lẹyin ti wọn jẹ ewe kan to ni kokoro ninu.
Olori eto ilera nipinlẹ Zamfara, Yusuf Abubakar sọ fun BBC pe “Agbẹ kan lo oogun finkofinko si ewe kan i ko fẹran, to si jẹ pe ara rẹ ni ewe ti awọn idile naa lo lati fi se ọbẹ.
“O fin oogun finkofinko yii ni owurọ, ti awọn si lọ ni ọsan lati lọ ja ewe fun ọbẹ.
“Wọn bẹrẹ si ni ma bi, ti wọn si n yagbẹ. Wọn suure gbe wọn lọ si ile iwosan sugbọn ẹ pa ko boro mọ fun awọn eeyan naa.
Dokita ni awọn diẹ lara awọn eeyan ti padanu ẹmi ti wọn to gbe wọn de ile iwosan, ti awọn kan si ku ni ile iwosan naa.
Bawo lo se le da eeyan to jẹ ounjẹ majele mọ?
Dokita Fatima Adamu, to jẹ dokita Amina Teaching Hospital niluu Kano ṣalaye, “O titọ ibẹ ni pe a ko le da eeyan to ba jẹ majele mọ pẹlu oju wa lasan, o ni awọn ibeere ti a ma bere, ka to le sọ pe majele ni eeyan naa jẹ.
Sugbọn o ṣalaye pe awọn apẹẹrẹ ti eeyan le ri lara eeyan to ba jẹ pe o jẹ majele
- Ṣiṣe aisan
- Inu riro
- Iba
Dokita Fatima ni awọn nnkan yii ni awọn onimọ iṣegun yoo se iwadii le lori lati mọ irufẹ ounjẹ ti eeyan bẹ jẹ.
O tẹsiwaju pe o pin dandan pe ko di igba ti eeyan ba n jade lati ẹnu eeyan ki wọn to mọ pe majele ni.
Ki ni yoo ṣẹlẹ si ara eeyan lẹyin to jẹ majele?
Dokita Fatima ni iṣoro ti wa lẹyin ti eeyan ba jẹ majele, to wọ ara rẹ.
“Ara wa ni nnkan tro fi n da bobo ara rẹ sugbọn yoo se akiyesi pe nnkan buburu ti wọ ara, ti yoo si ma ba ja. To ba di o pe o lulẹ, igba naa ni apẹẹrẹ yoo ma han ni ara eeyan. Awọn majele mi ni ko nilo itọju rara.
“Lẹyin ọjọ diẹ, alaafia le da ba eeyan naa sugbọn awọn mii wa ni wọn nilo itọju lati fi gbe ogun ti majele naa,”
Dokita wa gba ni imọran pe o lewu pupọ pe ki eeyan joko sile to ba ti ri pe o jẹ ounjẹ to ni majele ninu.
Ọna wo lo fi yago fun awọn ounjẹ majele?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Fatima ṣalaye igbesẹ to yẹ ki eeyan gbe lẹyin ti majele ba wọ ara rẹ ati ọna ti ko fi ni jẹ ki o jẹ ounjẹ oni majele.
- Jẹ ounjẹ to mọ tonitoni
- Ile idana rẹ gbọdọ wa ni tonitoni
- Tọju awọn ounjẹ rẹ si bi to koko to fi raye de ibẹ.
- Lo omi to mọ tonitoni
- Fi omi to mọ fọ awọn ohun to fi n jẹ
- Gbe ounjẹ rẹ sinu ẹrọ amu nnkan tutu
- Fọwọ rẹ lorekore
- Ma se gbẹ awọn kẹmika si tọsi ile idana rẹ















