Kí ló dé tí àwọn èèkàn akọrin ẹ̀mí kò fi yọjú sí ibi ètò ìsìnkú Aduke Gold? Mọ́lẹ̀bi ṣàlàyé

Ki lo de ti awọn eekan olorin ẹmi ko fi farahan nibi eto isinku, paapaa isin idagbere fun gbajumọ akọrin ẹmi, Adukẹ Ajayi ti ọpọ mọ si Adukẹ Gold ni ibeere to gba ẹnu awọn eeyan, paapaajulọ awọn to peju sibi eto naa.
Eto isinku Adukẹ Gold waye lọjọ Ẹti pẹlu isin ikẹyin ni agbegbe Ọgba nilu Eko ki wọn to lọ sin oku rẹ si Ogijo ni ilu Ikorodu.
Pasitọ Noah Oluyemi ni mọlẹbi ri ọpọ iranlọwọ gba lọwọ awọn agba olorin ẹmi, ti wọn si gba ruku ti ẹbi Aduke Gold lasiko ti nnkan nira fun wọn.
Bo ti lẹ jẹ pe ọpọ awọn olorin ẹmi bi Tobi Alabi, Yinka Alaseyọri ati awọn mii ni ko yọju sibi ẹto isinku naa to waye ni agbegbe Ọgba niluu Eko.
Oluyemi, ẹni to ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹgbọn si Aduke Gold lo sọ eyi fun BBC Yoruba lasiko eto isinku rẹ to waye ni ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹjọ ọdun 2024.
O ni awọn olorin bii Tope Alabi ati awọn akọrin ẹmi yooku duro ti mọlẹbi Aduke Gold.
“Aburọ mi sọ fun mi gbogbo iha ti awọn olorin bi Tope Alabi ati awọn yooku kọ si idile wa, wọn gba ruku ti ẹbi pe ki eto isinku na le jẹ aṣeyọri.
“Wọn gbiyanju, wọn duro ti idile wa pupọ, awọn naa si n gba ladurua pe ki Ọlọrun duro ti wọn.”
Ẹwẹ ninu ọrọ rẹ, Oluyemi tun ṣalaye pe ọpọ awọn Mọlẹbi ni ko ti gbagbọ pe o ti ku, ti iṣẹlẹ si jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ sugbọn gbagbọ pe igbesi aye rere ni Aduke gbe.
“Ọmọ ti Ọlọrun fun ni ẹbun nla ni Aduke Gold, iroyin iku rẹ da bi pe ọmọ ku lọwọ eeyan.
“Ọpọ nnkan ni ma fi ma ranti Aduke nitori o jẹ eeyan ni rẹ ara rẹ silẹ.
“Mo le pe ni woli, n ko le gbagbe rẹ liala”
Àwọn akọrin ẹ̀mí kórajọpọ̀ láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Adukẹ Gold

Oríṣun àwòrán, aduke gold/facebook
Ọkanojọkan akọrin ẹmi lo korajọpọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun olokiki akọrin ẹmi, Adukẹ Gold to jade laye.
Ni ibi aṣalẹ orin to waye ninu ọgba ile ẹkọ alakọbẹrẹ 'Ayanlẹyẹ Primary School', ni agbegbe lleeṣẹ ijọba to n bẹ ni Ifakọ/Ijaye ni awọn akọrin ẹmi naa ti pejupesẹ l'Ọjọbọ fun akanṣe eto ti wọn la kalẹ saaju eto isinku ti yoo waye l'owurọ ọjọ Ẹti.
Lara awọn akọrin ẹmi to wa ni ibi eto naa ni, Taiwo Ojodu, Mama Lati Abule, Modupe Essien, Alayọ Singer, Rẹmilẹkun Amos, Pasuma Jesu ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn adẹrinpoṣonu naa ko gbẹyin nibi eto nibi eto aṣalẹ orin ti wọn ṣe fun Adukẹ Gold

Oríṣun àwòrán, Akinwale Stephen Opeoluwa ( Stephano)

Oríṣun àwòrán, Akinwale Stephen Opeoluwa ( Stephano)

Oríṣun àwòrán, Akinwale Stephen Opeoluwa ( Stephano)
Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe gbajugbaja akọrin ẹmi, Arabinrin Tope Alabi naa ran aṣoju wa si ibi aṣalẹ orin naa.
Afihan ara oloogbe yoo waye ninu ọgba ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti awọn akọrin ẹmi ti ṣe akanṣe eto aṣalẹ orin ni owurọ ọjọ Ẹti, ki eto isinku to gbee lọ fun eto isinku ni Ogijo n'ipinlẹ Ogun.
Adukẹ Gold jade laye ni ẹni ọdun mẹrindinlogoji nibi ti o ti lọ gba itọju nile iwosan UCH niluu Ibadan. Ọpọlọpọ awuyẹwuyẹ lo si rọ mọ koko ohun to fa ipapoda akọrin ẹmi naa.













