A kò san owó kankan fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀ ìṣègùn tí wọ́n gb'òmìnira lákàtà ajínigbé - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti sọ pe awọn ko san owo kankan ki wọn to le gba itusilẹ awọn akẹkọọ ile-ẹkọ eto ilera ti awọn ajinigbe jigbe salọ nipinlẹ Benue laipẹ yii.
Ogun ni gbogbo awọn akẹkọọ ọhun, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju.
Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi fi sita lọjọ Abamẹta oni, fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ naa ti gba ominira.
Inu igbo nla kan to wa ni Ntunkon, ijọba ibilẹ Ado ni wọn ko awọn akẹkọọ ọhun lọ.
Ẹka ileeṣẹ oludamọran pataki apapọ lori eto aabo (NSA) la gbọ pe wọn lọ gba awọn akẹkọọ ọhun silẹ lọjọ Ẹti lai san owo kankan.
A gbọ pe ọkọ baluu agberapa (Chopper) mẹta ọtọọtọ ni wọn gbe wọnu igbo naa lati fi tọpinpin awọn ajinigbe ọhun, nibi ti ọwọ ti ba lara awọn afurasi, ti awọn miran ninu wọn si dero ọrun.
Ọjọbọ, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ni wọn ji awọn akẹkọọ ogun ọhun gbe, lasiko ti wọn n lọ sibi eto ipagọ wọn.
Atẹjade ti Adejobi fi sita sọ pe, “Lai san owo kankan. Lati tako awọn ọrọ kan ati awọn ayederu iroyin wi pe wọn san owo. A ko san kọbọ lati gba wọn silẹ. Wọn gba wọn silẹ pẹlu ọgbọn ati ikọṣẹmọṣẹ.
“A gbe oṣuba kare fun awọn ileeṣẹ eleto aabo, ibilẹ ati ONSA fun ifarajin wọn ati ọkan akikanju.”
Iroyin nipa bi wọn ṣe ji awọn akẹkọọ naa gbe lo jade sita lọjọ Ẹti, to si mu ki awọn ọmọ Naijiria maa bu ẹnu atẹ lu bi iwa ijinigbe ṣe n fi ojoojumọ peleke sii.
Ọjọ diẹ lẹyin ijinigbe wọn, awọn ajinigbe naa ti bẹrẹ sii beere fun aadọta miliọnu ko to di pe wọn tu wọn silẹ.















