Ìjọba àpapọ̀ yóò pín mítà iná lọ́fẹ̀ẹ́, àmọ́ ọdún mẹ́wàá lẹ ó fi san owó rẹ̀

Mita ina
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita fun ipese ina mọnamọna lorilẹede Naijiria, Adebayo Adelabu, ti tan imọlẹ si iroyin kan to n lọ kiri pe, ọọfẹ ni awọn olubara ina mọnamọna n gba mita ina.

Adelabu ni ko si nnkan to jọ mọ bẹ ati awọn olubara to gba mita ina tuntun yii yoo ni lati san owo fun ọdun mẹwaa.

O sọ eyi nigba to n sọrọ pẹlu awọn akọroyin niluu Ibadan, o ni otitọ ni pe ọwọ mita ina ti lọ soke, to si jẹ pe a ti ri owo jẹ idojukọ nla fun wọn.

Adelabu ni ijọba apapọ yoo wa ọna lati san owo mita ina, ti awọn araalu to n jẹ anfani yii yoo si ma san owo naa pada diẹdiẹ.

O tẹsiwaju pe ijọba yoo ma yọ owo ina lara owo ti awọn araalu ba fi n ra ina mọnamọna sori mita wọn.

“A ni owo fi ra mita yii, ti awọn araalu yoo si ma san owo naa diẹdiẹ.

“Nigba ti ijọba bẹrẹ igbesẹ yii, a yoo gbe fun awọn onibara , ti a si ma yọ owo naa fun ọdun mẹwaa, pẹlu eyi, awọn eeyan ko ni mọ lara,” o ṣalaye.

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ti onibara ba ra ina mọnamọna ẹgbẹrun mẹwaa, wọn yoo yọ N100 kuro ninu owo to san fun ijọba.

Adelabu fikun pe ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ yoo wa owo toto N100bn lati fi ra mita ina mọnamọna.

“Aarẹ ti da nnkan ti a pe ni ‘Presidential Metr Initiative’ silẹ lati wa ojutu si ọrọ yii, to sọ mi di alaga.

“Olubadamọran si Aare lori ọrọ agbaara ni akọwe ẹgbẹ. Ohun ti a agbọdọ se ni pe o kere ju milọnu meji eeyan gbọdọ gba mita yii ni ọdọdun.”

O tun ṣalaye pe Banki apapọ ti gba lati se iranlọwọ fun orilẹede Naijiria lati ra mita le ni milọnu meji laaarin ọdun meji.