Àjọ NCC kéde gbèdéke tuntun fún àwọn tí kò tíì so nọ́mbà fóònú wọn pọ̀ mọ́ NIN

Oríṣun àwòrán, NIMC
Ajọ NCC to n ṣakoso awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ni Naijiria ti kede ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an to n bọ gẹgẹ bi gbedeke ọjọ tawọn eeyan ni lati so nọmba foonu wọn pọ mọ kaadi idanimọ NIN wọn.
Ajọ naa kede loju opo X rẹ lalẹ Ọjọru wi pe oun ti sọ fun gbogbo ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ ni Naijiria lati pari eto siso nọmba foonu pọ kaadi NIN titi ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan an.
Ninu atẹjade ti ọgagba ọrọ to ni ṣe pẹlu araalu ni ajọ NCC, Ọgbẹni Reuben Muoka, ti sọ igbesẹ waye lati jẹ ki gbogbo eeyan so nọmba foonu pọ mọ kaadi NIN wọn gẹgẹ bi alakalẹ ijọba.
Ọgbẹni Muoka sọ ninu atẹjade naa pe ọpọ Naijiria lo ti so nọmba wọn pọ mọ kaadi idanimọ NIN wọn.
Amọ, ajọ naa tun rọ awọn ọmọ Naijiria ti ko tii so nọmba wọn pọ mọ kaadi NIN wọn ki o too di ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan an.
Ọgbẹni Muoka ṣalaye ninu atẹjade naa siso nọmba foonu pọ mọ kaadi NIN yoo ṣeranwọn fun eto ọrọ aje ati eto abo bakan naa.
‘’Siso nọmba foonu pọ mọ kaadi yoo jẹ ko rọrun lati maa gba owo ati sanwo lori ẹrọ kọmoputa tabi lori foonu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Eyi yoo tun mu adinku ba iwa jibiti ori ayelujara tawọn kan n la awọn ọmọ Naijiria.
A fẹẹ ri wi pe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹsan an to n bọ, ko ni si nọmba foonu kankan ti ko tii di siso pọ pẹlu kaadi idanimọ NIN.
Nitori naa ni a ṣe n rọ gbogbo eeyan ti wọn ba n koju iṣoro kan tabi omiran lori ati sọ nọmba foonu pọ mọ kaadi NIN wi pe ki wọn tete lọ si ọfiisi ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ wọn ki o ti ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan an.
Bakan naa, a tun fẹ ki araalu mọ pe rira tabi tita nọmba foonu eyi ti wọn ti forukọ silẹ lodi sofin, koda ẹni ti ijọba ba gbamu pe o ṣe bẹẹ lo dero ẹwọn,’’ Ọgbẹni Muoka lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita lorukọ ajọ NCC.















