Odò Ado Awaye l'Oyo àti Colorado l'Amẹrika nìkan ni àdágún omi órí àpáta tó wà lágbàáyé
Oriṣii ibudo Kayeefi lo wa lagbaye ni eyi ti Naijiria naa ni awọn ibudo kọọkan to fi agbara Olodumare han.
Odo Ado Awaye ni adagun odo ti iwadii fihan pe ko kun ri, bẹẹ ni ko si bi ojo ṣe le rọ to; ko lọlẹ sii ri bo ti wu ki ọgbẹlẹ mu to lasiko ẹrun to.
Ogbeni Ayo Adams to jẹ alakoso irinajo afẹ nibẹ ṣalaye fun BBC Yoruba ni kikun lori odo adagun naa.
O ni awọn kan ti wọn ko sinu odo naa ko pada jade bẹẹ nigba ti wọn sọ okuta sinu odo adagun ọhun, ìlú to jina si ilu Oyo ni wọn ti lọ ri awọn nkan naa.
Odo adagun meji lo jẹ iru eyi to wa ni gbogbo agbaye.
Ọkan ni Colorado ni orilẹ-ede Amerika ati ikeji ni odo Adagun Ado Awaye nipinlẹ Oyo lorilẹ-ede Naijiria.
Ọpọ eeyan lo ti sọ pe nání, nànì, nání, bi ọmọ ọdẹ ṣe n nání apó, ti ọmọ aṣẹgita n naaani epo igi naa lo ṣe yẹ ki awọn ijọba Naijiria naani odo adagun Ado Awaye yii.
Gbogbo awọn ti BBC Yoruba fọrọ wa lẹnu wo lori odo adagun Ado Awaye yii ni wọn ke si ijọba lati wa ṣe ohun to yẹ fun ipese ohun amayedẹrun bii akasọ lati gun oke ti omi adagun yii wa ati awọn nkan mii ti yoo sọ ibẹ di ibudo irin ajo afẹ ti gbogbo agbaye a wá maa wò.
















