Ta a ni Johann Rupert tó gba ipò ẹni tó lówó jùlọ l’Africa mọ́ Aliko Dangote lọ́wọ́?

Dangote and Rupert

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni bayii, baba olowo ilẹ South Africa torukọ rẹ n jẹ Johann Peter Rupert, ti di ẹni to lowo ju nilẹ Africa.

Ọkunrin alaga ileeṣẹ Richemont yii ti gba ipo naa mọ Aliko Dangote, ọmọ orilẹede wa Naijiria lọwọ, lẹyin ti Dangote ti fi ọpọlọpọ ọdun jẹ olowo julọ l’Africa.

Eyi jẹyọ lẹyin ti ileeṣẹ to n ṣe agbeyẹwo ẹni to lowo julọ, Bloomberg Billionaire Index, (BMI), gbe abajade iwadii wọn jade lọtẹ yii.

Iṣẹ kan gboogi ti ileeṣẹ BMI yii gbe dani, ni lati maa ṣe akọsilẹ awọn olowo aye ati ipo ti kaluku wọn wa nipa owo nini bi ojumọ ṣe n mọ.

Awọn ni wọn kede Johann Rupert bayii gẹgẹ bii ẹni ti owo rẹ pọ julọ nilẹ Africa, lẹyin ti owo Dangote ja walẹ, ti adinku owo naa si ju biliọnu kan Dọla lọ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ tuntun lati ọdọ awọn BMI ṣe wi, owo ti Rupert ni bayii jẹ $14.3billion, o pọ ju ti Dangote to wa ni $13.4billion lọ.

Rupert jẹ ere 1.87 billion, nigba ti Dangote padanu owo to to $1.69bn.

Bo tilẹ jẹ pe ohun to mu owo Dangote ja walẹ ko fi gbogbo ara han, ohun to daju ni pe nnkan ko fi ara rọ laaarin Dangote ati ijọba Naijiria, paapaa lori ọrọ ibudo ifọpo ti ileeṣẹ Dangote gunle.

Bakan naa, gẹgẹ bi abajade BMI, wọn ko ka ibudo ifọpo ti Dangote n ṣe lọwọ naa mọ ọrọ̀ rẹ, idi si ni pe ileeṣẹ naa ko ti i bẹrẹ iṣẹ. Biliọnu mọkandinlogun (19billion) ni wọn pe owo rifainari yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ meji sẹyin ni ileeṣẹ BMI kede Dangote bii ẹni to wa ni ipo karun-din-ni- aadọjọ (145th) ninu olowo lagbaaye.

Ṣugbọn ni bayii, Dangote ti ja walẹ si ipo ọgọjọ (160) ninu awọn eeyan to lowo ju laye, nigba ti Johann Rupert wa ni ipo kẹrin-din-ni-aadọjọ (146th), gẹgẹ bi abajade ti wọn ṣẹṣẹ fi sita ṣe sọ.

Ta a ni Johann Rupert?

Baba olowo to lowo julọ l'Africa bayii, Johann Rupert.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Baba olowo to lowo julọ l'Africa bayii, Johann Rupert.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi iwadii ileeṣẹ Bloomberg, wọn ni Rubert n ri owo rẹ lati ara ileeṣẹ nla to ni, iyẹn Cie Financiere Richemont.

Ileeṣẹ naa ni wọn lo n ṣe awọn nnkan ẹṣọ, ti wọn si tun n ta a fun awọn alaratunta. Awọn naa ni wọn si n ṣe aago to wuyi ju lagbaaye.

Lara awọn ohun ti ileeṣẹ naa n ṣe to si gbajumọ ni Cartier ati Montblanc.

Ọdun 1998 ni wọn da ileeṣẹ yii silẹ, Rembrandt Group Limited ni wọn fi bẹrẹ, o ti di Remgro Limited), Baba Rupert, Anton lo da ileeṣẹ naa silẹ laarin awọn ọdun 1940.

Rupert to ti di ‘biliọnia’ bayii n ṣiṣẹ nibẹ nigba naa fun ẹbi rẹ.

Ọ kẹkọọ nipa ọrọ aje ati ofin to rọ mọ awọn ileeṣẹ ni Yunifasiti Stellenbosch.

O ṣiṣẹ ni ọpọlọpọ aaye, nigba to si di 1998, o da ileeṣẹ tiẹ ti i ṣe Richemont silẹ, o si di ọga agba pata fun ileeṣẹ naa.

Wọn fi oye ọmọwe ninu ofin, ọrọ aje ati okowo da Johann Rupert lọla, oun naa si ni Alaga ileeṣẹ Peace Parks Foundation ati Michelangelo Foundation.

Rupert tun ni Alaga South African PGA Tour, ọmọ ẹgbẹ to ti pẹ lo jẹ ni European Tour, oun lo si da ajọ Laureus Sport for Good Foundation, silẹ, eyi ti wọn fi n ran awọn ọdọ lọwọ lati ṣẹgun ìṣẹ́ ati òṣì, airi ile gbe, aarun ko gboogun (AIDS) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa ọdun 1950 ni wọn bi Johann Peter Rupert, ni Stellenbosch

Oun ni ọmọkunrin agba fun baba olowo nni, Anton Rupert ati iyawo rẹ, Huberte.

Wo èèyàn mẹ́wàá tó lówó jùlọ lágbàáyé àti àwọn ọmọ Africa mí-ìn tí wọ́n wà nípò olówó

*Elon musk

*Bernald Arnault

*Jeff Bezoz

*Mark Zuckerberg

*Bill Gates

*Larry Ellison

*Larry Page

*Steve Ballmer

*Warren Buffet

*Sergey Brin

Ọmọ Africa mi-in to tun wa nibẹ ni Nicky Oppenheimer, lati South Africa.

Ipo 213 lo wa ninu awọn 250 eeyan to wa nipo olowo.