Àwọn ọmọ ọdún méjìlá pèsè ìmọ̀ ẹ̀rọ tó le dín ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ́ kù ní Naijiria
Yoruba bọ, wọn ni ti ebi ba ti kuro ninu iṣẹ, iṣẹ ti buṣe.
Ko jẹ tuntun m pe lati bi ọdun sẹyin ni ọwọn gogo ounjẹ ti gbode ni orilẹ-ede Naijiria, eyi to mu ki inira o ba ọpọlọpọ araalu.
Botilẹ jẹ pe ijọba ti gbe oriṣiriṣi igbesẹ, bii pipin ounjẹ ọfẹ, owo ati awọn nnkan mii fun araalu lati mu itura ba wọn, ko da bi i pe awọn nnkan naa ṣe nkankan rara.
Eyi ni awọn ọmọdebinrin mẹrin, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkanla si mejila, ro, ti wọn fi gbe imọ ijinlẹ kan kalẹ lati mu adinku ba ọwọngogo ounjẹ ni Naijiria.
Awọn ọmọbinrin naa – Oghenemaro Tejiri, Salome Akhabhau, Excel Barile-Nwika, ati Goodness Nwonanne - to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ girama sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo pe awọn gbe imọ ẹrọ ‘Agriconnect’, eyi to jẹ ‘app’ lori foonu, lati di laafo to wa laarin awọn to fẹ dako ti ko lowo lọwọ ati awọn to lowo ṣugbọn ti ko mọ nipa iṣẹ agbẹ, to fi mọ awọn oniṣowo, papọ.


Nipasẹ imọ ẹrọ ‘Agriconnect’, wọn ti gba ami ẹyẹ Combat Hunger Awards, eyi to fun wọn ni anfaani lati koju awọn akẹgbẹ wọn to ti gba ami ẹyẹ ni California, America.
Awọn ọmọ naa ni lootọ ni awọn ko ni agbara lati pa oṣi tabi ebi run patapata, ṣugbọn pẹlu aapu Agriconnect, adinku yoo de ba ọwọngogo ounjẹ.




