Orílẹ́èdè Nàìjíríà gba ìrànwọ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára 10,000 fún ìtójú àrùn mpox

Orilẹede Amẹrika ti fun Naijiria ni ẹgbẹrun mẹwaa abẹrẹ Jynneos fun itọju arun mpox.
Ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii ni Amẹrika fi abẹrẹ naa ṣe iranwọ fun Naijiria lati le gbogun ti arun naa.
Abẹrẹ ọhun eyi ti ajọ to n ṣakoso oogun lilo ati ounjẹ l’Amẹrika fontẹ lu ni o wa fun idena arun igbonna ati mpox fun awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti to ọdun mejidinlogun lọ soke.
Nigba ti o tẹwọ gba abẹrẹ naa niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, Minisita eto ilera, Ọjọgbọn Muhammad Pate, gboṣuba fun ijọba orilẹede Amẹrika fun itọrẹ aanu ti wọn ṣe.
Ọjọgbọn Pate ti akọwe agba ileeṣẹ ijọba eto ilera, Ọgbẹni Daju Kachollom, ṣoju nibi eto naa sọ pe ijọba apapọ ko ni kaarẹ lori ati jẹ ki eto ilera to peye wa fun araalu.
Ọjọgbọn Pate ni abẹrẹ naa yoo ṣe iranwọ nla fun orilẹede Naijiria lori ati gbogun ti itankalẹ arun mpox.
Minisita eto ilera fikun ọrọ rẹ pe gbogbo eto ti ijọba to wa lode n ṣe lo da lori ọna ati pese eto ilera to peye fawọn ọmọ Naijiria.
Ọjọgbọn Pate ko ṣai ki awọn alabaṣiṣẹpọ bi awọn ajọ USAID, WHO, UNICEF, PEPFAR atawọn ajọ mii fun atilẹyin wọn ni gbogbo igba.
Arun mpox lo ti tan kalẹ papaa julọ lawọn igberiko laarin gbungbun Afirika ati ẹkun Guusu Afirika bakan naa.
Ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Najiria ti kede pe o ti to ogoji eeyan to ti lugbadi arun naa ni Naijiria bayii.















