Lẹ́yìn ọdún kan tó jáde láyé, ètò ìsìnkú Pa Akinwunmi yóò wáyé

Aworan Pa Tawio Micheal Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Akinwunmi Akinkunmi

    • Author, Blessing Aderogba
    • Role, Journalist
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin ọdun to jade laye, ọkunrin to sẹda asia orilẹede Naijiria yoo wọ ka ilẹ.

Pa Taiwo Micheal Akinkunmi, ẹni to sẹda asia Naijiria, jade laye ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 ni ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun.

Awọn mọlẹbi rẹ ni, ijọba apapọ se ileri lati fun Akinkunmi ni ẹyẹ ikẹyin.

Sugbọn lẹyin ọdun kan ti wọn ti n reti, mọlẹbi pinnu lati tẹsiwaju pẹlu eto isinku naa pẹlu ajọsepọ ijọba ipinlẹ Oyo, nibi ti Akinkunmu n gbe.

"A ni lati fun baba wa ni eto isinku to yẹ," Akinwumi Akinkunmi, ọmọ oloogbe sọ fun BBC.

"Baba mi to di oloogbe jẹ eeyan jẹjẹ, ti ko si ni fẹ ki nkankan tabuku si orukọ rẹ.,"

Awọ ewe ati funfun

Pa Akinkunmi lo ronu nipa lilo awọ ewe ati awọ funfun nigba to n kẹkọ niluu London ni ọdun 1950 lẹyin to ri iroyin kan to n pe fun idije ẹni to le sẹda asia orilẹede Naijiria ninu iwe iroyin.

O rin kaakiri Naijiria pẹlu awọn obi rẹ to jẹ oniṣowo lati ronu nipa sisẹda asia naa. Awọ elewe lo rumọ si pe orilẹede kun fun wara fun ohun ọgbin, ti awọ funfun tumọ si alaafia ati ifọwọsowọpọ laarin awọn ẹya Naijiria.

Ohun to sẹda lo gbe igba roke, ti wọn si se ifilọlẹ rẹ ninu ọjọ ayajọ ọjọ ominira ni ọjọ kinni, oṣu kẹwaa ọdun 1960, ti wọn si fun £100 fun aṣeyọri rẹ.

Nigba to pada si Niajiria, Akinkunmi gba isẹ ni ileeṣẹ ijọba to n risi agbẹ, to si gbe igbeaye ti ko pariwo, to si jẹ awọn perete lo mọ nipa ipa to ko fun orilẹeede Naijria

Aworan igba ewe Pa Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Akinwunmi Akinkunmi

Àkọlé àwòrán, Akinkunmi in August 1958 before travelling to Britain
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ọdun 2010, wọn fa Pa Akinkunmi kalẹ, to si wa lara aadọta eeyan ti wọn yan fun ami ẹyẹ aarẹ fun ayẹyẹ aadọta ọdun gbigba ominira orilẹede Naijiria.

"Gbogbo eeyan ro pe Baba mi ti di oloogbe ni sugbọn olori ile igbimọ aṣofin Oyo tẹlẹri, Monsurat Sunmonu fi ifẹ han si ," Ọmọ rẹ sọ.

Ni ọdun 2014, Sẹnetọ Oyo kọ lẹta si ijọba apapọ, to si n pe fun pe ki wọn ami ẹyẹ to ga ju lorilẹede Naijiria fi da Akinkunmi lọla.

Lọdun naa, Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan fi ami ẹyẹ Officer of the Order of the Federal Republic (OFR). da lọla.

Lẹyin iku Akinkunmi ninu oṣu kẹjọ ọdun to kọja, Sẹnetọ kan gbe aba kalẹ pe ki ijọba se eto isinku fun Akinkunmi. Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio buwọlu aba naa.

Ẹwẹ, ijọba ko ti gbe igbesẹ kankan, ti awọn ẹbi Akinkunmi si n san owo toto ẹgbẹrun meji lojojumọ lati gbe oku oloogbe naa si ile igbe oku si nigbt ti wọn duro.

Ni ọdun 2024, ileeṣẹ ijọba National Institute for Cultural Orientation (NICO) fi atẹjade sita pe ileeṣẹ ijọba to n risi Aṣa ati ise ti palasẹ fun awọn lati ri pe eto isinku naa yoo wyae.

"O jẹ ohun to ba ni inu jẹ pupọ. Idaduro ki se nitori ko si nnkan ti wọn fẹ fi ṣe sugbọn nitori wọn ko kọ ibi ara si," Ọjọbọn Adesina, ọjọgbọn nipa Itan ni fasiti ibadan nipinlẹ Oyo.

Aworan Pa Taiwo Akinkunmia ti ọdọmọkunrin kan

Oríṣun àwòrán, Akinwunmi Akinkunmi

Àkọlé àwòrán, Akinwumi and his son travelling from Abuja after presidential recognition

Lẹyin ọpọ ariwo, ijọba ipinlẹ Oyo ti pinnu lati seto iranlọwọ fun awọn mọlẹbi lori eto isinku fun oloogbe, ti yoo waye ni ọjọ diẹ lẹyin ayẹyẹ ọdun kan to jade laye.

Ninu ọrọ rẹ, Ọjọgbọn De-Velera Botchway, onimọ nipa itan lti fasiti Cape Coast niluu Ghana ni awọn akọni oloṣelu jẹm ilumọka ju awọn to kopa ninu aṣa nitori iru iṣẹ ti wọn n se.

O ni awọn eeyan to sẹda asia ati awọn nnkan mii fun orilẹede wọn ni ọpọ igba ni ọpọ ki n mọ wọn.