Òfin oní póńpó ni pé akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ pé ọdún 18 kò tó lè ṣe WAEC, ó léwu fún ọjọ́ iwájú Nàìjíríà - Olùkọ́ fásítì

AWoran awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi awuyewuye ṣe n lọ lori ikede ijọba apapọ wi pe akẹkọọ ti ko ba tii pe ọdun mejidinlogun ko ni lanfani lati kopa ninu idanwo aṣekakagba ile ẹkọ girama, NECO ati WAEC mọ, Ọjọgbọn Emmanuel Ojo, ti ẹka eto ẹkọ nipa eto oṣelu nile ẹkọ giga Fasiti UNILORIN ti rọ ijọba lati yi ipinnu rẹ pada lori ọrọ naa.

Nigba ti o ba n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọjọgbọn Ojo ni igbesẹ yii yoo ṣakoba fun ọjọ iwaju orilẹede Naijiria ti ijọba ko ba yi ipinnu rẹ pada.

Ọjọgbọn onimọ nipa eto oṣelu sọ pe ijọba tiẹ le sọ pe akẹkọọ ti ko ba tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun le ma wọ ile ẹjọ giga fasiti, amọ, wọn ni lati fawọn akẹkọọ ti wọn ko tii pe ọmọ ọdun mejilogun laye lati maa ṣe idanwo aṣekagba ile ẹkọ girama WAEC tabi NECO.

Ọjọgbọn Ojo ni gbogbo agbaye lawọn obi ti n tete mu ọmọ wọn lọ sile ẹkọ tori iṣẹ ti wọn n ṣe.

‘’Eyi ko boju mu rara, yoo si jẹ akude nla fun eto ẹkọ wa ati idagbasoke orilẹede Naijiria.

Awọn ọmọ kan n bẹ ti wọn ni ọpọlọ lati ọrun, wọn le jẹ ọmọ mẹkunnu amọ ti wọn yoo mọ iwe ju ọmọ ọjọgbọn ni ile ẹkọ giga fasiti lọ.

Nitori naa, ko dara to ki a di awọn ọmọ lọwọ lati ṣe idanwo oniwe mẹwaa tori wọn o tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun.

Eyi to le mọgbọn dani ni pe kawọn akẹkọọ ti ko tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun ma lanfani lati wọ ile ẹkọ giga fasiti.

Awọn obi kan wa ti wọn maa n tete fi ọmọ wọn sile ẹkọ tori wahala iṣẹ ijọba ti wọn n ṣe.

Ki iru awọn ọmọ bẹẹ to pe ọmọ ọdun mejila, wọn ti kawe jinna.

Nigba miran kii ṣe ọjọ ori ni ẹbun ọpọlọ tabi ẹbun iwe, bi ẹni kọọkan ba ti kona mọ ara rẹ lati kekere lo maa n sọ bi ọpọlọ ṣe maa ji si iwe si,’’ Ọjọgbọn Ojo ṣalaye.

Ọjọgbọn Ojo rọ ijọba apapọ pe ko ma fi oolu lu iru aba yii tori yoo di itẹsiwaju Naijiria lọwọ.

Olukọ fasiti naa ni eyi tumọ si pe ọpọ obi ni yoo maa mawọn ọmọ wọn lọ si orilẹede mii lati lọ ka iwe mẹwaa.

Ọpọ obi lo kan awọn ọmo wọn loju lati le tete pari ile ẹkọ - Ọnimọ nipa eto ẹkọ

Aworan awọn akẹkọọ nita fasiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹjọ 2024 ni Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Tahir Mamman, kede pe awọn akẹkọọ ti ọjọ ori wọn ko ba to ọdun mejidinlogun ko ni lanfani lati kopa ninu idanwo JAMB ati wọle si ile ẹkọ giga fasiti, bẹẹ ni wọn ko tun ni lanfani lati ṣe idanwo WAEC ati NECO.

Ọjọgbọn Mamman ni awọn akẹkọọ ti ko ba lo iye ọdun ti wọn gbe kalẹ fun wọn lati lo ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama ko ni lanfani lati lọ wọ ile ẹkọ giga fasiti.

Ọpọ awọn obi ati alagbatọ lo ti kọ ẹyin si igbesẹ yii, ti wọn si n pe fun pe ijọba pe ki o wọgile igbesẹ naa.

Olukọ agba ni Fasiti Obafemi Awololwo, Ọjọgbọn Dipo Salami ti ẹka to ni ṣe pẹlu ede ni ọpọ awọn obi lo n kan ọmọ wọn loju lati te te pari ile ẹkọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọgbọn Salami sọ pe nnkan ti awọn akẹkọọ nilo lati fi ṣe aṣeyọri laye ju ọgbọn iwe lọ.

“Awọn obi n kan awọn ọmọ wọn loju lati kawe, mo ti ri ọmọ ọdun mẹrinla ati mẹẹdogun ti wọn wọ fasiti ni Naijiria.

“Ko si ilu kankan lagbaaye ti eyi ti n sẹlẹ, eyi ko tọna rara,'' Ọjọgbọn Salami lo sọ bẹẹ.

Olukọ naa sọ pe ''ti ẹ ba ri awọn akẹkọọ to kere bayẹn ni ile ẹkọ ni oke okun, wọn gbọdọ jẹ akẹkọọ ti oye wọn pọ gan an, ti wọn yatọ sugbọn iru wọn ṣọwọn.''

Salami ni ọpọ obi lo fẹ ki awọn ọmọ pari ẹkọ ni ọmọ ọdun mẹrinla, awọn ọmọ yii le mọ iwe sugbọn Yoruba ni eeyan gbọdọ ni nnkan mẹta, Imọ, ọgbọn ati oye.

O tẹsiwaju pe ọpọ awọn akẹkọọ to wa lode yii ni wọn ni imọ sugbọn wọn ko ni ọgbọn ati oye nitori awọn obi ko fi aye silẹ lati kọwọn ni awọn nnkan yii ki wọn to da wọn lọ si ile ẹkọ.

“Awọn akẹkọọ kan wa, wọn ma ni imọ sugbọn wọn ma gọ, ti wọn ko kọ wọn lẹkọ, ti wọn si jẹ ọmọ Yoruba.”

Ọjọgbọn Salami ṣalaye pe awọn oyinbo to gbe ẹkọ sọ iye ọjọ to yẹ ki akẹkọọ pe ko to di pe o bọ kilaasi kan.

“Ni ilẹ UK, o ni lati pe ọmọ ọdun mejidinlogun ko to le se awọn idanwo kan, o gbọdọ pe ọmọ ọdun mejidinlogun, bo se ri kaakari agbaye niyẹn.

”Mo ti ri ọmọ ọdun mẹrinla, to fidi janlẹ ni ọdun akọkọ ni fasiti, to si fẹ lọ pa ara rẹ, eyi tumọ si pe oye ko pe to nipa pe ki eeyan lulẹ."

Ìjọba ṣàlàyé ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tíì pé ọdún 18 kò fi ní lè ṣe ìdánwò WAEC àti NECO mọ́

Aworan awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, WAEC

Ijọba apapọ ti kede wi pe akẹkọọ ti ko ba tii pe ọdun mejidinlogun ko ni lanfani lati kopa ninu idanwo aṣekakagba ile ẹkọ girama, NECO ati WAEC mọ.

Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Tahir Mamman lo sọ eyi nigba to n sọrọ pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan Channels lọjọ Aiku, ọjọ Kẹdọgbọn, oṣu kẹjọ,. ọdun 2024.

Ọjọgbọn Mamman ṣalaye pe ijọba apapọ ti pa a laṣẹ fun gbogbo ajọ to n risi idanwo WAEC ati NECO lati ri pe wọn tẹ le aṣẹ ijọba yii.

Bakan naa lo ni igbesẹ ijọba apapọ yii kii se igbesẹ tuntun.

O fikun ọrọ rẹ pe iye ọjọ ori fun akẹkọọ lati se idanwo idanwo JAMB ati wọ ile ẹkọ giga fasiti si wa ni ọdun mejidinlogun.

“Ọdun mejidinlogun ni ọjọ ori , nnkan ti sọ ninu ipoade wa pẹlu JAMB ninu oṣu keje ni fi aye silẹ ni ọdun yii lati jẹ ki awọn obi mọ nipa igbeṣẹ ijọba .

“Idanwo Jamb gba awọn akẹkọọ ti ojọ ori wọn ko ti to ẹni ọdun mejidinlogun ni ọdun yii sugbọn wọn o ni igba bẹẹ ni ọdun to n bọ.

“Ajọ Jamb yoo ri pe ọjọ ori awọn akẹkọọ ti wọn yoo wọ, ile ẹkọ fasiti pe ọdun mejidinlogun.

“Ti ẹ ba se isiro ọjọ ori to yẹ ki awọn akẹkọọ lo ni ile ẹkọ, apapọ ọdun naa yoo jẹ ọdun mẹtadinlọgbọn ati abọ, bẹrẹ lati igba ewe wọn.

“Igbesẹ yii ki n ṣe igbeṣẹ tuntun, lati fi tako ọrọ kan ti awọn eeyan sọ.”