Ọdún Aheregbe dá rògbòdìyàn sílẹ̀ nílùú Akure, ọjà ṣòfò, aráàlú farapa

Awuyeye suyọ loni n'iluu Akure bi awọn olugbe Isinkan ṣe na ika aleebu si awọn ọdọ Akure pe wọn ṣe akọlu si oja Isinkan lasiko ọdun Aheregbe.
Awọn olutaja oja naa sọpe awọn ọdọ kan yabo ọja naa lati wa ba awọn ọja ti wọn patẹ rẹ jẹ.
Lara awọn olutaja to wa ninu ọja naa koro oju si igbesẹ yii ti wọn si rọ Iralepo Isinkan, Ọba Olugbenga Ojo lati gbe igbese ti o yẹ lori ọrọ naa.
Lasiko to n ba BBC sọrọ, Iralepo Isinkan Ọba Olugbenga Ojo sọpe Ilu Isinkan da duro, ti wọn ko si lẹtọ labẹ ofin lati kopa ninu ọdun Aheregbe to n waye ni Akure.
O ni ofin ọdun naa ko kan gbogbo olugbe agbegbe naa, eyi to fun gbogbo olutaja ilu Isinkan l'anfaani lati ta ọja wọn lai si wahala kan.
Ọba Olugbenga ṣalaye pe ẹnikẹni ko ni ẹtọ lati se idiwọ fun awọn ọlọja lati ma ṣe kopa ninu karakata lasiko ọdun Aheregbe naa.
Ọlọfin Adimula wa benuate lu bi awọn ọdọ ilu Akure ṣe ba awọn ọja ti wọn patẹ rẹ jẹ lawọn agbegbe ilu Isinkan papa julọ ọja Isinkan.
Ṣugbọn ninu ọrọ tiẹ, agbẹnusọ fun Deji ilu Akure, Oloye Taye Fagite sọ pe gbogbo ilu Akure lo gbọdọ kopa ninu ọdun Aheregbe ti ofin ọdun naa si mu gbogbo olugbe ilu Akure.
Oloye Fagite salaye rẹ pe gbogbo ilu ti wọn ba ti n sọ ede Akure lo gbọdọ kopa ninu ọdun naa nitori pe ara Akure ni wọn.
O salaye rẹ pe o pọn dandan fun gbogbo agbegbe tabi ilu to n sọ ede Akure lati kopa ninu ọdun yii lati le fopin si iku ọdọ laarin ilu ni ibamu pẹlu aṣẹ ifa ti Isinkan si jẹ ọkan ninu awọn ilu to n sọ ede yi.
Cele Deji Akure sọ ọ di mimọ pe ko si ọkan ninu awọn ọdọ Akure to fẹsẹ kan ọja Isinkan lati ba ọja ti wọn patẹ jẹ pe irọ to jina sootọ ni ohun ti Iralepo ati awọn olutaja ọjọ naa sọ.
Nnkan to yẹ ki o mọ nipa ọdun Aheregbe
Ọdọọdun ni ọdun Ahérégbé àti Amólè maa n waye nilu Akure ti tọdun yi ko si yatọ si tatẹyinwa.
Niṣe lawọn araalu bọwọ fun aṣẹ ti Deji pa pe ki wọn ma ṣe ṣi ṣọọbu itaja.
Lasiko ọdun ọhun ni awọn agbagba ilu Akure maa n gbadura fun alaafia ilu naa, to fi mọ ilu Oba Ile, eyii ti ko fi bẹẹ jina si Akure.
Ko ni si kata-kara ninu awọn ilu memeji lasiko ti ọdun Aheregbe ati ọdun Amole yoo maa waye.
Ẹnikẹni to ba taja ni ayajọ ọdun naa le padanu ọja rẹ nitori awọn to n kaakiri ilu lati ri daji pe ọdun naa bo ṣe yẹ ko lọ le ko ọja irufẹ ẹnio bẹẹ.
To n tumọ si pe awọn to n kaakiri naa laṣẹ labẹ aṣa ilu Akure lati ko tabi gbẹsẹ ọja irufẹ oniṣowo bẹẹ.
Bakan ni ilu yoo ko iṣọwọ awọn miran si aarin igboro pẹlu paṣan lọwọ ti wọn a si maa ko paṣan bo ẹnikẹni to ba tapa si ilana to rọ mọ ọdun ọhun, bii ṣiṣi ṣọọbu.












