Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tò dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn gbígbé àsìá Russia sókè ní Kano ti gbòmìnira

Oríṣun àwòrán, X
Olukọ ati awọn akẹkọọ ọmọ orilẹede Poland tawọn agbofinro fọwọ ofin mu lasiko ifẹhonuhan ‘ebi n pa wa’ ti gbominira.
Minisita ọrọ ilẹ okeere orilẹede Poland, Radoslaw Sikorski, lo fidi ọrọ yii mulẹ loju opo X rẹ ni Ọjọru ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii.
Awọn ẹṣọ eleto abo fẹsun kan awọn ọmọ orilẹede Poland meje ọhun wi pe wọn wa lara awọn to n na asia orilẹede Russia soke niluu Kano lasiko ifẹhonuhan to waye laipẹ yii ni Naijiria.
Amọ, awọn alaṣẹ orilẹede Poland ti sọ pe olukọ ati awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti Warsaw lawọn eeyan naa.
Ijọba Poland sọ pe nibi tawọn agbofinro ti mu wọn ni iwọde to n lọ lọwọ niluu Kano nigba naa ti ba wọn.
‘’Ni bayii, mo le fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ orilẹede wa ti gba ominira, wọn si ti pada ṣenu ẹkọ wọn bayii niluu Kano.
Laipẹ yii ni wọn maa pada si orilẹede Poland ti wọn ba ti pari eto ẹkọ wọn tan,’’ Ọgbẹni Sikorski lo sọ bẹẹ loju opo X rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ni ibẹrẹ oṣu Kẹjọ yii ni ọpọ ọmọ Naijiria tu jade lati fẹhonuhan lori bi ilu ṣe le lasiko yii.
Iwọde naa si ba ẹyin yọ lawọn apa orilẹede Naijiria kan papaa julọ lapa ariwa.
Rogbodiyan bẹ silẹ lawọn ipinlẹ kan bii Kano ati Kaduna, koda awọn eeyan kan ba iṣẹlẹ ọhun lọ nigba ti ọpọ dukia ṣofo.
Eyi lo mu ki ijọba lawọn ipinlẹ kan loke Oya kede ofin konle o gbele ti nkan fi rọlẹ.
Lara ohun to ṣẹlẹ ni awọn oluwọde to n gbe asia orilẹede Russia soke nibi ifẹhonuhan papaa julọ niluu Kano ati Kaduna.
Eleyii lo si mu ki awọn ẹṣọ eleto abo fi ọwọ ṣinkun mu ọpọ awọn oluwọde to n ṣe eleyii.
Kinni gbigbe asia Russia soke lorilẹede mii tumọ si?

Oríṣun àwòrán, X
Ipa orilẹede Russia ti n pọ si ni ẹkun guusu ilẹ Afirika lẹyin tawọn ologun gba ijọba lorilẹde Niger, Burkinaso Faso ati Mali.
Koda, awọn orilẹede yii ti ologun n dari wọn bayii ni wọn ti kuro ninu ajọ ECOWAS ti o jẹ ajọ to n ṣagbatẹru eto ọrọ aje ẹkun guusu Afirika.
Bakan naa lawọn orilẹede yii tun le awọn ọmogun orilẹede France ati Amẹrika kuro nilẹ wọn.
Amọ, wọn gbe igbesẹ lati ri pe ibaṣepọ wọn pẹlu orilẹdde Russian dan mọran si.
Ẹwẹ, ijọba orilẹede Naijiria ti kede pe iditẹmọjọba ni ki gbigbe asia ọrilẹede mii mi soke yatọ si ti Naijiria tumọ si.
Eyi si jẹ ọkan lara awọn ẹsun iwa ọdaran to lagbara julọ ni Naijiria
Ki ni ijiya fun awọn eeyan to n gbe asia Russia ni Naijiria?

Oríṣun àwòrán, X
Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Abubakar Mohammad Usman ni ilana ofin ti orilẹede Naijiria fi aye gba awọn eeyan lati se ifẹhonuhan sugbọn gbigbe asia orilẹede mi soke lo jẹ.
O ṣapejuwe iwa yii gẹgẹ bii iditẹmọjọba, to si se koko ki awọn olufẹhonuhan mọ ohun ti ofin sọ nipa iwa yii.
“Ti ọwọ ba tẹ awọn eeyan, ti wọn gbe wọn lọ si ile ẹjọ, agbẹjọrọ wọn le sọrọ pe wọn lẹtọ lati se ifẹhonuhan sugbọn ofin ko sọ pe wọn ẹtọ lati gbe asia orilẹede mii soke.
Ki ni a n pe ni iditẹmọjọba?
Iditẹmọjọba, gẹgẹ bii ofin se gbe kalẹ, Agbẹjọro Umar Bala ni ẹnikẹni to ba to sẹyin tabi ransẹ si eeyan kan pe ko wa gba ijọba tabi se ikọlu si Aarẹ ni a n pe iditẹmọjọba.
O ni ijiya iku lo wa fun ẹsun yii labẹ ofin.
“Ẹnikẹni to gbe ogun ti ijọba, tabvi gbero lati gba ijọba, agbegbe jẹbi ẹsun iditẹmọjọba, to si jẹbi ijiya iku.
“Ẹnikẹni to ba lẹdi apupọ mọ eeyan mi lati ditẹmọijọba lorilẹede Naijiria tabi ni ita naa jẹbi ẹsun iditẹmọjọba, ti iku si le jẹ ijiya ẹsun naa.”















