Ọmọ Naijiria mẹ́rin di èèrò ẹ̀wọ̀n ní UK fún ṣíṣe ẹgbẹ̀rún méjì ayédèrú ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó

Oríṣun àwòrán, Others
Ọmọ orilẹede Naijiria mẹrin ti dero ọgba ẹwọn fun apapọ ọdun mẹtala lori ẹsun pipese iwe ẹri igbeyawo lo le ni ẹgbẹrun meji eyi to fun awọn eeyan kan ni anfaani lati wọ tabi duro si ilẹ UK ni ọna to lodi sofin.
Gẹgẹ bii ohun ti iwe iroyin UK Evening Standard gbe sita, awọn eeyan naa ni Abraham Olarotimi Onifade, ẹni ọdun mọkanlelogoji, Abayomi Aderinsoye Shodipo, ẹni ọdun mejidinlogoji, Nosimot Mojisola Gbadamosi, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Adekunle Kabir, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta.
Ikọ ẹlẹni mẹẹrin yii ni wọn n pese ayederu iwe ẹri igbeyawo ati awọn iwe ẹri mii lati se iranwọ fun awọn eeyan lati ri iwe igbelu gba ni orilẹede naa.
Iwadii ajọ to n mojuto ọrọ awọn ajoji ni UK, Home Office, se nipinlẹ Eko ati ni UK, ti wọn si ti fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ naa ti pese iwe ẹri ayederu igbeyawo lo le ni ẹgbẹrun meji.
Onifade ati Shodipo ni iwadii fihan pe wọn jẹbi ẹsun pe wọn lẹdi apo pọ lati gbe awọn eeyan wọle si UK ni ọna to lodi sofin.
Awọn eeyan mẹrin yii farahan ni ile ẹjọ Woolwich gẹgẹ bii ohun ti Home Office gbe sita .
Onifade, lati Gravesend, ni ile ẹjọ paṣẹ pe ko lọ ma gba atẹgun lọgba ẹwọn fun ọdun mẹfa, ti Shodipo, ẹni to wa lati Manchester ni wọn ran lọ ẹwọn fun ọdun marun un gbako.
Gbadamosi, lati Bolton, ni wọn ran lọ ẹwọn fun oṣu mejidinlogun , ti Kabir lati London ri ẹwọn oṣu mẹsan an he.
Agbẹnusọ ileeṣẹ Home Office, Paul Moran sọ pe, “Awọn eeyan pinnu lati se akoba fun ẹnu ibode wa sugbọn ọwọ tẹ wọn, ti wọn si foju wina ofin.
“Awọn eyi ti a mu ati awọn yooku, ohun to jẹ wọn logun ni lati fi ọna yii gba owo.
"Inu mi pẹlu awọn akẹgbẹ mi dun, pe a da erongba wọn ru, ti mo si lero pe eyi yoo se ikilọ fun awọn ikọ yooku to n hu irufẹ iwa ibajẹ yii."
Ọgbẹni Moran sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati ma ṣiṣẹ karakara lati ri pe aabo aabo wa fun ibode United Kingdom.















