Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹ gbaradi o!

Ki lo n bọ?

Ajọ to n mojuto oju ọjọ ni Naijiria lo ma n ṣekilọ fawọn ipinlẹ mọkanla lati joye oju lalakan fi n ṣọri lori iṣẹlẹ omiyale agbara ya ṣọọbu to ṣeeṣe ko waye

Ṣe nitori odo Lagdo Dam ti orilẹ ede Cameroon ṣi silẹ lati ọjọ Iṣẹgun ti yoo si waye fun ọjọ meje gbako?

Bẹẹni! Adari ajọ naa ni bi o tilẹ jẹ pe odo River Niger ti omi naa le yawọ ko mu ewu dani bayii

O pọn dandan fawọn ipinlẹ to wa leti omi River Niger lati gbaradi gidi

Kan si oju bbc.com/Yoruba lati mọ boya ipinlẹ rẹ ko si ninu awọn mọkanla naa

Gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti yọju sajọ EFCC

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti EFCC ti n gbiyanju lati fofin gbe e to si n ja si pabo

Fẹsun mọkandinlogun to nii pẹlu ṣiṣe owo to le ni ọgọrin biliọnu naira kumọkumọ

Orilẹ ede Britain, Amẹrika ati ajọ iṣọkan agbaye UN ti fi ikilọ sita

Lori bi awọn ẹrọ kekeke ti ikọ Hezbolllah n lo fun ibanisọrọ ṣe n bu gbamu mọ wọn lapo lorilẹ ede Lebanon

Eeyan bii mẹsan-an ti jade laye, ọpọ si farapa

Kò ṣe é mà gbọ̀ ọ́