Ọdún kan lẹ́yìn ìkọlù, Kibbutz Be'eri ṣì ń ṣòjòjò láti tẹ̀síwájú

Oríṣun àwòrán, Maya Meshel / BBC
- Author, Alice Cuddy
- Role, Southern Israel
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Èèyàn mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn ní agbègbè Kibbutz Be’eri lọ́dún kan sẹ́yìn nígbà tí àwọn agbébọn láti Hamas ṣe ìkọlù sí wọn, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní jó ilé, yìnbọn pa àwọn èèyàn. Bákan náà ni wọ́n tún èèyàn ọgbọ̀n àti ẹbí wọn sí àhámọ́ ní Gaza.
Àwọn tí orí kó yọ nínú ìkọlù náà ní àwọn wá yàrá tí ààbò wà fún àwọn láti sápamọ́ sí àti pé ọ̀pọ̀ wákàtí ni àwọn lò nínú ibi tí àwọn forí pamọ́ sí ni.
Wọ́n ní orí ìkànnì WhatsApp tó jẹ́ ti agbègbè náà ni àwọn ti ń bá ara àwọn sọ̀rọ̀ láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní agbègbè àwọn
Agbègbè Kibbutz jẹ́ èyí tó lágbára, tí àwọn olùgbé ibẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Àwọn olùgbé ibẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe bí ọmọ ìyá. Ó wà lára àwọn Kibbutz ní Israel tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan.
Àmọ́ láti ìgbà ìkọlù ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni nǹkan tí yípadà fún wọn.
Díẹ̀ lára àwọn tó móríbọ́ nínú ìkọlù náà ló ti padà sílé wọn. Àwọn míì máa ń lọ síbẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́ ajé àmọ́ tí wọn kò láyà láti sun agbègbè náà mọ́. Àwọn mìíràn, lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ní ilé ìtura, wọ́n ti lọ kọ́ ilé sí Kibbutz míì tó wà ní kìlómítà ogójì sí ti tẹ́lẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Níṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, tó ń ṣe ìrántí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìkọlù náà wà káàkiri gẹ́gẹ́ bí Dafna Gerstner ṣe sọ.
Be’eri ni Gafna dàgbà sí, tó sì lo wákàtí mọ́kàndínlógún nínú yàrá kan tó wà fún ààbò àwọn ará ìlú lọ́wọ́ àdó olóró lọ́jọ́ Keje.
“Kò sí ibi tí èèyàn kojú sì tí kò ti ní rí èèyàn kan tó pàdánù ìyá tàbí bàbá rẹ̀, gbogbo ibi ni.”
Nínú Be’eri, kò sì kí èèyàn má rì í ilé tí gbogbo rẹ̀ ti jóná tán tàbí tó ti bàjẹ́ tán.
Ọ̀pọ̀ àwọn ilé tí wọ́n ti jí èèyàn gbé tàbí pa èèyàn ni wọ́n so aṣọ dúdú mọ́ pẹ̀lú orúkọ àti àwòrán wọn lára rẹ̀.
Dafna àti àwọn ẹbí rẹ̀ ń ta ayò lálẹ́ ọjọ́ tí ìkọlù náà wáyé.

Dafna àti àwọn ẹbí rẹ̀ ń ta ayò lálẹ́ ọjọ́ tí ìkọlù náà wáyé.
Ó ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé bàbá òun tó jẹ́ àkàndá àti ọmọ ọ̀dọ̀ àwọn ṣì wà láyé lẹ́yìn tí wọ́n sápamọ́ sínú yàrá fún ọ̀pọ̀ wákàtí bí ilé àwọn ṣe ń jó mọ́ wọn lára.
Àmọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì fún Be’eri, pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n yìnbọn fun níbí ilé ìwòsàn ìtọ́jú eyín Kibbutz. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni Dafna wà nígbà náà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ de láti Germany fún àbẹ̀wò sile.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ní Be’eri ni ọta ìbọn ti bá gbogbo ara rẹ̀ jẹ́ tó fi mọ́ ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé.
Agbègbè náà tó máa ń dá páro ló tún máa ń rọ́ kẹ́kẹ́ nígbà tí àwọn àlejò bá ṣe àbẹ̀wò síbẹ̀.
Àwọn ọmọ ogun Israel àtàwọn ará ìlú Israel, tó fi mọ́ láti ilẹ̀ òkèrè máa ń ṣe àbẹ̀wò síbẹ̀ láti gbọ́ àti láti mọ ibi tí nǹkan bàjẹ́ dé
Méjì nínú àwọn tó gbà láti máa mú àwọn èèyàn káàkiri ni Rami Gold àti Simon King, tí wọ́n ní àwọn.yoo ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ yóò máa jẹ ìrántí lọ.

Simon, ẹni ọgọ́ta ọdún ní iṣẹ́ náà le díẹ̀ àmọ́ tó ní ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe àbẹ̀wò ni kìí mọ ìbéèrè tí wọ́n lè bèèrè àmọ́ wọ́n lè rí, wọ́n sì lè gbọ́ òórùn ohun tó ṣẹlẹ̀.
Rami ní tirẹ̀ ní níṣe ni àbẹ̀wò náà máa ń mú ohun rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá.
Rami wà lára àwọn tó padà sí Be’eri lẹ́yìn ìkọlù náà.
Simon ní àwọn kan kò fẹ́ràn bí àlejò ṣe ń wá síbẹ̀ nítorí pé ilé wọn tó jẹ́ àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ máa sọ̀rọ̀ ibẹ̀ láì rí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan àti pé ibẹ̀ máa di ohun ìgbàgbé bí wọn kò bá máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Rami àti Simon ní àwọn ń wòye ọjọ́ iwájú bí wọ́n ṣe ń tún àwọn odi tó ti wó kọ́. Bákan náà ni àwọn èèyàn míì ń kọ́ ilé láti fi dá èyí tó ti bàjẹ́ padà.
Simon júwe bí wọ́n ṣe ń tún àwọn ilé náà kọ́ bí ohun tó ń mú ìtùnú bá ọkàn rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Maya Meshel / BBC

Be’eri, tí wọ́n dá sílẹ̀ lọ́dún 1946 jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìletò Júù ní ẹkùn náà kí wọ́n ń tó orílẹ̀ èdè Israel sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ sì jẹ́ àwọn tó máa ń pe fún àláfíà láàárín Israel àti Palestine.
Lẹ́yìn ìkọlù ọdún tó kọjá, ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú náà ni wọ́n kó lọ sí ilé ìtura David Hotel.
Shir Guttentag ní láti ìgbà tí ìkọlù náà ti wáyé, gbogbo ọ̀rọ̀ tí òun máa ń bá àwọn ará Be’eri sọ ló máa ń dá lórí ìkọlù náà.
Shir ṣàlàyé pé inú yàrá ààbò òun ni òun sápamọ́ sí lọ́jọ́ ìkọlù náà, tí òun sì ń mú dá àwọn ọmọ òun lójú pé nǹkan máa padà sípò láìpẹ́.
Ó ní nígbà tí wọ́n wá kó àwọn kúrò, òun kò lè gbójú sókè nítorí òun kò fẹ́ mọ́ bí nǹkan ṣe ti bàjẹ́ tó ní ìlú àwọn.
Ó sọ pé kìí ṣe ohun tó jọjú fún àwọn mọ́ tí èèyàn bá ń sunkún tàbí bá ọkàn jẹ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí ṣáájú ìkọlù náà.
Shir àtàwọn ọmọ rẹ̀ méjì, àtàwọn èèyàn ìlú Be’eri míì ni wọ́n ti kó lọ sí Kibbutz Hatzerim tí ìjọba Israel pèsè fún wọn báyìí tí kò sì ju irin ogójì ìṣẹ́jú pẹ̀lú ọkọ̀ lọ.


Oríṣun àwòrán, Handout
Ó ní inú òun dùn gidi nígbà tí òun dé ilé òun tuntun àti pé òun lọ wo yàrá ààbò tí àwọn ọmọ òun yóò máa sùn, òun ri pé ilẹ̀kùn rẹ̀ wúwo ju ti Be’eri lọ tí òun sì lérò pé ilẹ̀kùn tó lè rò ọta ìbọn dànù ni.
Ó fi kun pé òun kò mú nǹkan kúrò nínú ilé òun tó wà ní Be’eri nítorí òun ní ìgbàgbọ́ pé òun máa padà síbẹ̀ lọ́jọ́ kan.
Kíkó lọ sí Hatzerim jẹ́ ìpinnu tó wáyé lẹ́yìn tí àwọn ará ìlú náà fẹnukò. Ìwòye ni pé ìdá àádọ́rin àwọn èèyàn Be’eri ló máa má gbé ibẹ̀ fún ìgbà kan ná, táwọn tó sì ti tó ìlàjì ara B’'eri ti kó lọ báyìí.

Oríṣun àwòrán, Maya Meshel / BBC

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ìrìnàjò sí Be’eri láti Hatzerim yá ju láti ilé ìtura lọ tí ọ̀pọ̀ wọn sì máa ń ṣe ìrìnàjò náà ní ojoojúmọ̀ fún iṣẹ́ oòjọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.
Shir máa ń ṣe ìrìnàjò lọ sí Be’eri láti lọ ṣiṣẹ́ ni ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú nǹkan ọ̀sìn àmọ́ tó ní òun kò ì tíì ṣetán láti padà láti máa gbé.
Ó ní òun ti lọ bèèrè fún àṣẹ láti lè máa lọ ìbọn gẹ́gẹ́ bí àwọn míì nítorí òun kò fẹ́ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tún bá òun lójijì mọ́.
“Nítorí àwọn ọmọ mi àti ara mi ni mo ṣe fẹ́ gba ìbọn nítorí lọ́jọ́ ìkọlù náà mi ò ní nǹkan ààbò kankan.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú Be’eri tí wọ́n máa ń pè fún àláfíà tẹ́lẹ̀ ni wọn kò sọ nǹkankan mọ́ báyìí.
Àwọn Kibbutz ní owó tí wọ́n máa ń dá láti fi ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ará Gaza. Bákan náà ni wọ́n máa ń ṣètò ìtọ́jú ìlera fún àwọn ará Gaza ní ilé ìwòsàn Israel.
Àmọ́ ìpinnu ọ̀pọ̀ wọn ló ti yípadà lẹ́yìn ìkọlù ọdún kan sẹ́yìn.
Rami wòye pé kò sí ohun tí àwọn fẹ́ ṣe tí wọ́n fi máa gba àwọn bí ọ̀kan náà.
Ọ̀pọ̀ ló tún ń sọ̀rọ̀ ikú Vivian Silver - ẹni tó jẹ́ pé ó máa ń pè fún àláfíà bí ohun tó mú wọn lọ́kàn le.
Àwọn èèyàn Be’eri ṣì ní ìrètí pé àwọn èèyàn wọn tó ṣì wà ní àhámọ́ Gaza máa padà sílé láyọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti tú àwọn méjìdínlógún sílẹ̀.
Àwọn méjì ti jáde láyé, táwọn mẹ́wàá ṣì wà ní àhámọ́ Gaza pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé mẹ́ta ṣì wà láyé nínú wọn.
Ní àpapọ̀, èèyàn ẹgbẹ̀fà ló jáde láyé ní ẹkùn gúúsù Israel lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 tí wọ́n sì fi 251 sí àhámọ́. Láti ìgbà náà, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera tí Hamas ń ṣàkóso rẹ̀ ṣe sọ, èèyàn 41,000 ni iléeṣẹ́ ológun Israel ti pa ní Gaza.
Bákan náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti nù ní Lebanon bí Israel ṣe ń ju àdó olóró síbẹ̀ láti ṣe ìkọlù sí ikọ̀ Hezbollah.
Ṣáájú ìkọlù ọ̀hún, àwọn ènìyàn Be’eri ní bí àwọn ṣe súnmọ́ Gaza tó, àwọn máa ń gbàgbọ́ pé ààbò tó dájú wà fáwọn látọwọ́ iléeṣẹ́ ológun àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́.

Oríṣun àwòrán, Maya Meshel / BBC
Simon ní gbígbé àwọn òkú náà padà máa ń bí ìpòruru ọkàn àmọ́ inú àwọn dùn pé wọ́n padà sílé.
Ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú ló máa ń kópa nínú ètò ìsìn ìkẹyìn bẹ́ẹ̀.
Shir sọ pé Hatzerim tí òun wà báyìí kìí ṣe ibi tó pé fún òun àmọ́ òun ń mú ara òun lọ́kàn le pẹ̀lú ìgbàgbọ́.
“Ìlú tó ń ṣòjòjò ni – pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti ìbínú - ṣùgbọ́n agbègbè tó lágbára ni.”














