A kò ní jẹ́ kí ogun ó mí títí a ó fi rẹ́yìn ikọ̀ Hamas – Natanyahu

Oríṣun àwòrán, EPA
Olootu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ni oun yoo tẹsiwaju ninu jija ogun pẹlu Hamas titi oun yoo fi ri pe oun rẹyin gbogbo ọmọ ikọ Hamas ati awọn ikọ mii to n dunkoko mọ orilẹede Israel.
Natanyahu ni gbogbo nnkan ti o ba gba ni oun yoo fun lati ri pe oun daabo bo awọn eeyan orilẹede Israel ati dukia wọn.
Ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni ogun bẹ silẹ laarin orilẹede Israel ati Gaza.
Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn, ti ọpọ si farapa yanna-yanna,
Ninu ọrọ rẹ, o ni ijọba Israel ko gbagbe awọn eeyan Israel to wa ni ahamọ ikọ Hamas, ti wọn si n gbe gbogbo igbesẹ lati ri pe awọn gba itusilẹ.
“A yoo se gbogbo ohun to tọ lati gba awọn eeyan wa ti wọn jigbe pada,” Natanyahu ṣalaye.
O ni o ṣeeṣe ki ogun naa tẹsiwaju titi awọn yoo fi rẹyin gbogbo ikọ to n dunkoko mọ orilẹede Israel.
Ko pẹ ti Natanyahu ba awọn eeyan sọrọ tan ni ileeṣẹ ologun Israel kede pe ikọ Hamas ti fi ado oloro ransẹ lati Gaza si Israel.
Ileeṣẹ ologun ni ado oloro mi wa lati Yemen si Israel sugbọn wọn pana rẹ ni kiakia.
Saaju, lọdun to kọja ni Benjamin Netanyahu ti ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ Hamas lawọn yoo ri pe awọn ran lọ sọrun.
Iye awọn eeyan ti rogbodiyan to bẹ silẹ laarin Hamas ati Israel ti ran lọ sọrun ko ni onka rara.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan si lo ti di alanilelori bayii, ti wọn si n sa kijokijo bọ si ibi kan lati ibi kan.















