Aráàlú sọ̀kò pa bàbá, ìyá àti ọmọ lẹ́yìn tí wọ́n rí òkú ọmọdébìnrin tí wọ́n ti ń wá nínú ṣáláńgá ìgbọ̀nsẹ̀ wọn

Aworan ọkọ ati ile ti wọn da ina sun

Oríṣun àwòrán, SAPS/Facebook

Awọn ọlọpaa lorilẹede South Africa sọ pe awọn ko tii fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni lori iṣẹlẹ to ṣe okunfa iku awọn ewyan mẹta kan nibẹ.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ni South Africa ṣe sọ, arakunrin ẹni ọdun mẹtalelaadọta kan, ọrẹbinrin rẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọta ati ọmọ wọn ọkunrin to jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn lawọn eeyan sọ okuta pa.

Lagbegbe S3notlelo ni Vaalbank lẹyin ti wọn ba oku ọmọ ọdun mẹjọ kan ti wọn n wa ninu ṣalanga igbọnsẹ wọn lopin ọsẹ to kọja.

Bawo lọrọ naa ṣe ṣẹlẹ?

Awọn ọlọpaa sọ pe lati ọjọ kejila oṣu keji ọdun 2023 lawọn obi ọmọ ọdun mẹjọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Nomsa Sambo ti n wa a ti wọn si ti lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa Vaalbank SAPS leti.

Lẹyin ti wọn fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ni iroyin kan ba gbode pe wọn ri arakunrin kan to gbe Nomsa lọ sinu ile rẹ.

Awọn ọlọpaa dide si ọrọ naa, wọn si mu arakunrin naa ni ọjọ kẹtala oṣu keji fun ifọrọwanilẹnuwo lori ẹsun ijinigbe.

Awọn ọlọpaa ni awọn fi arakunrin naa silẹ nigba to sẹ pe ohun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.

Aworan ile ti wọn jo naa

Oríṣun àwòrán, south africa police service

“Lowurọ yii ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun 2023 ni iroyin jade pe ọmọ to sọnu naa wa ninu ṣalanga igbọnsẹ ni ile afurasi ọhun.

“Awọn ọlọpaa lati Vaalbank at’awọn ọmọ ikọ adoola ẹmi lọ sibẹ ti wọn si ba oku eeyan mẹta, ọkunrin meji, obinrin kan loju popo.

“Apa egbo wa lara wọn to ṣe afihan pe o ṣeeṣe ko jẹ pe wọn sọ wọn ni okuta pa ni, awọn onimọ isegun si fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti ku.”

Ṣalanga igbọnsẹ ti wọn ni wọn tiri oku ọmọ ọdun mẹjọ naa

Oríṣun àwòrán, South Africa police service

Awọn ọlọpaa ni awọn tun ri ọkọ meji ti awọn eeyan da ina sun, bakan naa ni wọn tun gbe oku ọmọbinrin naa jade kuro ninu ṣalanga igbọnsẹ naa.

Awọn ọlọpaa ni orukọ awọn mẹtẹta ni Arakunrin Zele Papo Machika (53) ọrẹbinrin rẹ Pauline Maubane (51), pẹlu ọmọ wọn Thabi Maubane (32)

A ti yi iwadi iṣẹlẹ naa kuro ni ijinigbe si ti ipa eeyan - Ọlọpaa

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti yi iwadii naa pada kuro ni ti ijinigbe si ti ipaniyan bayii.

Bakan naa ni wọn ni awọn tun n wadi iṣẹlẹ iku awọn mẹtẹta naa

“A ko tii mu ẹnikẹni lori rẹ, iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ buruku yii

“Ikọ otẹlẹmuyẹ kan labẹ kọmiṣọ a ọlọpaa lẹkun SAPS ni Mpumala ga, ti bẹrẹ iwadi naa