Buhari gbàdúrà àṣeyọrí fún Tinubu; BAT kí Buhari kú iṣẹ́, ó ṣèlérí láti sin Nàìjíríà

Aworan Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede atilẹyin rẹ fun Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri Bola Ahmed Tinubu to tun jẹ oludijẹ sipo aarẹ ẹgbẹ oselu APC.

Aarẹ Buhari kede atilẹyin rẹ nibi eto aṣe kagba ipolongo ibo aarẹ to waye ni papa iṣere Teslim Balogun agbegbe Surulere,Eko.

Nigba ti aarẹ n gbe owo Bola Tinubu ati Gomina Ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu soke aarẹ Buhari ki wọn ku orire o si gbadura aseyọri rere fun wọn.

Ninu ọrọ rẹ Tinubu dupe lọwọ aarẹ Buhari fun atilẹyin lati igba idibo abẹle ẹgbẹ APC,

Tinubu ni “Aarẹ Buhari tẹle gbogbo ilana ati yan oludijẹ sipo aarẹ ẹgbẹ APC ti mo si bori,

Ko sọ wi pe ki wọn da eto idibo naa ru nitori aisẹ ẹẹya kan naa abi nitori mi kii jẹ ọmọ Daura nibiti o ti wa.

‘’Iṣẹ adari wa fun idagbasoke, ọkan to mo ati agbara lati sisẹ to ye bi o ti gba mi niyanju”.

"Mo ṣeleri làti sìn yìn" Tinubu

Aworan Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Tinubu ṣeleri lati ṣiṣẹ takuntakun ti wọn ba dibo yan gẹgẹ bi aarẹ Nigeria,Tinubu ṣeleri lati mu ireti ọtun ba awọn ọmọ orilẹede yi ti oun o si ri wi pe gbogbo ileri ti oun ṣe nigba ipolongo ibo ni oun o muṣẹ.

Alaga ẹgbẹ oselu APC Abdullahi Adamu ni eẹgbẹ oṣelu APC mohmo gbe ipolongo ibo wa si ilu ẹko ni ki awọn ololufẹ Bola Tinubu le dibo fun lọpọlọpọ.

Oni pẹlu iṣẹ ti Bola Tinubu ti ṣe gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Eko nigba kanri,o ṣetan lati mu idagba soke ba orilẹede yii.