Security tips: Wo àwọn ọ́nà méjìlá láti dáàbò bo ara rẹ lásìkò yìí

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin
Ni bayii ti opin ọdun ti de, oriṣiriṣi ipanija lawọn eeyan n koju lori ọrọ eto abo.
Bi wọn ṣe n ja awọn kan lole ni wọn n ji awọn mii gbe, bẹẹ naa ni wọn n ṣe awọn ẹlomiran ni ijamba.
Idi ree ti BBC Yoruba ṣe kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lati mọ nipa awọn nnkan ti awọn araalu le ṣe lati daabo bo ara wọn lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii.
Alukoro ileeṣẹ naa nipinlẹ Eko, Banjamin Hundeyin ṣalaye funn BBC awọn ohun ti awọn eeyan le ṣe lasiko yii lati daabo bo ara wọn.
Máa dagbere ko to kuro nile
Hundeyin ṣalaye pe ko tọna ki eeyan kuro nile lai sọ fun ẹnikẹni ibi to n lọ tabi akoko to ṣeeṣe ko pada de.
Sisọ ibi ti eeyan n lọ maa n ran awọn ẹbi tabi ọrẹ ẹni bẹẹ lọwọ lati ke gbajare ti irufẹ ẹni bẹẹ ko ba de ibi to n lọ tabi tete pada sile.
Ṣora fun didanikan rin
O fin kun pe ireti abo wa fun ẹni to n rin pẹlu awọn ẹlomiran ju ki eeyan maa da rin lọ.
Ifura looogun agba
Hyndeyin sọ pe o dara ki eeyan maa ni ifura nibikibi to ba n lọ.
O ni “Ti o ba ri eeyan to ṣajoji si ayika rẹ tabi ohun to fun ọ lara, tete ke sita.”
Ni nọmba ipe pajawiri lọwọ
O ni o dara ki gbogbo araalu ni awọn nọmba ipe pajawiri lọwọ eyii ti wọn le pe lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba ṣalabapade ohunkohun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, lara awọn nọmba naa ni nọmba ọkọ, aya, awọn obi tabi ti ijọba ipinlẹ bii 112 tabi 767.
Ṣora fun isọkusọ
Alukoro ọlọpaa Eko naa gba awọn araalu niyanju lati ṣọra fun nnkan ti wọn n sọ ni laarin ọpọ eeyan.
O ni “Ẹlomiran yoo kan maa sọrọ nipa irinajo rẹ nibi ti ọpọ ero wa lai fura.”
“Awọn mii a maa sọrọ lori ẹrọ ilewọ pe ‘ni iwoyi ọla maa ti wa ni Dubai’ lai mọ irufẹ awọn to wa nitosi.
“Ṣiṣẹ nnkan bayii lewo pupọ.”
Ṣọra fun ohun ti o n kọ lori ayelujara
Gbogbo igbesi aye ẹlomiran ni awọn ọrẹ wọn mọ lori ayelujara.
Ti wọn ba jẹun, ti wọn ba ṣu tabi tọ, gbogbo aye wọn ni wọn maa n kede fun ọpó ero lori Facebook tabi Instagram.
Hundeyin ni ki awọn eeyan ṣora fun irufẹ iwa bayii nitori ẹni to n ṣọ wọn ti wọn ko mọ.
Ṣora fun kọrọ gbigba lasiko yii
O tẹsiwaju pe o san ki eeyan gba ọna to han gbangba ko si pẹ de ibi to n lọ ju ko gba kọrọ ki wọn ja irufẹ ẹni bẹẹ lole lọ.
Hundeyin sọ pe “Ibi to ya, amọ to da, o lewu.”
Awọn nnkan mii ti Hundeyin sọ ree
- Ṣọra fun sọọlẹ, lọ wọ mọto ni ibudokọ
- Ti o ba n lo Uber tabi Bolt, ri daju pe ọkọ to wa ninu aapu rẹ lo wa gbẹ ọ
- Ti o ba ri nnkan ti ko ba ofin mu, ta ọlọpaa lolobo
- Ti o ba wa ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ, ko awọn ohun ini rẹ to ṣe pataki pamọ kuro ni ibi ti gbogbo yoo ti ri
- Ti awọn awọn adigunjale ba kọlu ọ, ma ba wọn jiyan, o san ki o wa laye ju ki o padanu ẹmi rẹ lọ
Ire o!












