Àbẹ̀wò Zelensky sí US ti fi hàn pé àláfíà ò tíì lè jọba– Russia

Oríṣun àwòrán, EPA
Orílẹ̀ èdè Russia ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ukraine, Volodymyr Zelensky ṣe rin ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Russia ní Amẹ́ríkà ń fi ọgbọ́n bá òun ja ogun láì kojú òun tààrà.
Ààrẹ Joe Biden ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fún Ukraine ní $1.85bn gẹ́gẹ́ bí owó àtìlẹ̀yìn fún àwọn ọmọ ogun Ukraine lórí ogun tí Russia ń gbé tìí.
Bákan náà ni Amẹ́ríkà tún fún Zelensky ní ohun ìjà ogun ìgbàlódé láti fi kojú ogun Russia.
Nínú ọ̀rọ̀ tí Zelensky sọ fún àwọn aṣòfin Amẹ́ríkà, ó ní inú òun dùn fún àtìléyìn náà.
Àmọ́ aṣojú Russia sí Amẹ́ríkà ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ọ̀nà láti tún mú inú bí Russia si ni àti pé ìpadàbọ̀ kò ní da rárá.
Anatoly Antonov sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé Russia ń gbìyànjú láti wá bí àláfíà ṣe máa jọba àmọ́ ìkéde nǹkan ìjà ogun tí Amẹ́ríkà fẹ́ fun Ukraine ń kan àwọn lóminú.
Agbẹnusọ Russia, Dmitry Peskov ní kò sí ìpè fún bí àláfíà ṣe máa jọba láàárín ohun àti Ukraine nígbà tí Ààrẹ Zelensky lọ sí Amẹ́ríkà, ní èyí tó ní ó ṣe àfihàn pé Amẹ́ríkà ló ń fi Ukraine bá àwọn jà.
Peskov fi kun pé fífún Ukraine ní nǹkan ìjà ogun kò lè dá Russia dúró láti ṣèkọlù sí Ukraine.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè Russia, Maria Zakharova náà ni US mọ̀-ọ́n-mọ̀ ń kó nǹkan ìjà ogun fún Ukraine nítorí kò fẹ́ kojú Russia láti bá Russia jà.
Ó ní ìgbésẹ̀ yìí ń fi hàn pé àti Ukraine àti US kò sí ẹni tó ń fẹ́ kí àláfíà jọba láàárín àwọn méjéèjì.
Aàrẹ Zelensky ṣe àbẹ̀wò àìròtẹ́lẹ̀ sí àwọn ọmọ ogun Ukraine bíi kóríyá fún wọn

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Ukaraine, Volodymyr Zelensky ti ṣe abẹwo airotẹlẹ si ilu Bakhmut, nibi ti awọn ọmọ ogun Ukarain ati Russia ti ja ogun fun igba pipẹ.
O pade awọn ọmọ ogun ile Ukraine ti o si fi amin ẹyẹ da wọn lola.
Fun igba pipẹ, Ilu Bakhmut jẹ ọkan lara awọn ilu ti ija laarin awọn ọmọ ogun Russia ati Ukraine ti gbona felifeli ilu naa wa ni ila-oorun Donetsk, ati pe o ti bajẹ kọja ila.
Sibẹsibẹ, awọn ọmọ-ogun Ukaraine ti o gbena woju awọn ọmọ ogun Russia ni anfani lati da awọn ọmọ ogun Russia pada ti wọn o si bori wọn.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Abẹwo ti aarẹ Volodymyr Zelensky ṣe si awọn ọmọogun naa fi atilẹyin ijoba si awọn ọmọ ogun orilẹede Ukraine han.
Agbẹnusọ Aare Serhiy Nikiforov sọ pe aare Zelensky ti kuro ni ilu Bakhmut ṣaaju ki o to kede abẹwo naa.
Aare Zelensky ti ṣabẹwo si awọn ilu miiran ti awọn ọmọogun Ukraine ti gba pada lọwọ awọn ọmọogun Russia,Ilu bi Kherson ati Izyum.
Awọn ilu mejeeji ti padanu ọpọlọpọ ọmọ ogun eyi ti awọn oga ogun ilu mejeeji ka si adanu nla
,ilu naa ti o ni awọn olugbe to to okemarundinlogoji saaju ki ogun naa to beere lọ ti di hahoro.
Igbakeji minisita fun ọrọ aabo Hanna Malyar ninu atẹranṣẹ to fi si oju opo ayelujara Facebook rẹ lẹyin igba ti o ṣe abẹwo si ily Bakhmut ni
bo tile jẹ ọjọ oodurun ti ija ti beere laarin orilẹede Russia ati Ukraine ko to ọdun oodunrun ti awọn fi ja gba ominira lọwọ ilu Russia.
Oni Ukraine yoo duro,yoo si ṣẹgun













