Ọwọ́ tẹ ọmọ ogun mẹ́rìn tó gbèrò láti gbàjọba ní Gambia, wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijoba Orilẹede Gambia tí kede pe awọn gbegi dina igbesẹ kan ti awọn ọmọ mẹrin kan gbe lati yoo Aarẹ Adama Barrow kuro nipo gẹgẹ aarẹ.
Ninu atejade kan ti wọn fi lede, ìjọba Gambia ni ọwọ ti tẹ afurasi ọmọ ológun mẹrin tí mẹta yooku sì ti salọ.
Iwadi ko ti fihan pato ẹni to wa ìdí bii awọn ọmọ ologun ṣe fẹ tipatipa yoo Aarẹ Ballow.
"Gbogbo tí wa labẹ akoso bayii."
Idunkooko àwọn ọmọ ológun tí kọ́kọ́ waye láìpẹ́ yìí
Ọjọ Isẹgun ọsẹ yii ni awọn eeyan ti n fi imu filẹ pé àwọn ọmọ ológun fẹ ṣe ikọlu si ìjọba sugbọn Ọga agba fun Ileeṣẹ ologun ni irọ lasan ni.
"A ṣe idaraẹni lẹkọ ni, a ko ni erongba lati ṣe ikọlu ijoba Orilẹede Gambia."
Pupọ awọn Ọga ni ileeṣẹ ológun lo kọwe fipo silẹ lẹyin ti aarẹ Barrow gba isejọba
Barrow nigbogbo wa pe ko fi ọkan tan awọn ọmọ ologun, to si lo gba àwọn ọmọ ogun Senegal lati maa sọ lorilẹede rẹ
Bakan naa, ni awọn papa ofurufu Orilẹede naa, awọn ọmọ ologun Naijiria ati Ghana lo n sọ ibe e
Eyi ni ko jẹ ki awọn araalu ìlú naa fẹran ẹ nitori wọn gbagbọ pe awọn wa labẹ awọn Orilẹede kan.















