Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí obìnrin ajínigbé àtàwọn míì lẹ́yìn tí wọ́n gba #6m gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀

Afurasi ajinigbe

Oríṣun àwòrán, OGUN/POLICE

Arábìnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún, Mariam Ayila ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá fẹ́sùn wí pé ó jí ọmọ ọdún mẹ́tàlá, Sofiat Yusau gbé.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde ní ọjọ́rú, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kejìlá ọdún 2022 ló ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Oyeyemi ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ogúnjọ́ oṣù Kejìlá ni ọwọ́ tẹ ọmọbìnrin náà lẹ́yìn tí Ismail Yusau tó jẹ́ bàbá Sofiat tí Mariam jígbé lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Agbara, ìpínlẹ̀ Ogun.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ṣàlàyé pé Ismail ní òun rán ọmọ òun, Sofiat lọ sí ọjà Agbara láti lọ ra nǹkan wá fún òun ní nǹkan bí i aago mọ́kànlá òwúrọ̀.

Ó ní kò pẹ́ ni Ismail gba ìpè láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan wí pé àwọn ti jí ọmọ rẹ̀ gbé àti pé tí kò bá san ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lé ní igba náírà fún àwọn kò ní rí ọmọ náà mọ́ láyé.

Oyeyemi fi kun pé bí ọ̀gá ọlọ́pàá Agbara ṣe gbọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló da àwọn ọlọ́pàá sí ìgboro láti ṣe àwárí ọmọ náà kí wọ́n sì fojú àwọn ajínigbé tó bá wà nídìí ìjínigbé náà winá òfin.

Ó tẹ̀síwájú pé ìwádìí àwọn ọlọ́pàá ló ṣe okùnfà bí wọ́n ṣe ṣàwárí afurasí náà ní agbègbè Atan Ota ní ìpínlẹ̀ Ogun bákan náà tí wọ́n sì rí ọmọ náà gbà kalẹ̀ láì fi ara pa.

“Ìwádìí wa tún ṣe àfihàn pé afurasí yìí ti ṣaájú jí ọmọbìnrin kan gbé ní agbègbè Itele Ota ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2022 bákan náà.”

“Àwọn ẹbí ọmọ náà ní láti san owó fún Mariam kí wọ́n tó rí ọmọ wọn gbà padà lọ́wọ́ rẹ̀.”

Oyeyemi ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Lanre Bankole ti ní kí ẹ̀ka tó ń ṣe ìwádìí ìjínigbé ní ẹ̀ka ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ náà ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Ọwọ́ tún tẹ àwọn afurasí ajínigbé ní Kwara náà

Awọn afurasi ajinigbe

Oríṣun àwòrán, KWARA POLICE

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti fi ṣìkún òfin gbé àwọn afurasí ajínigbé mẹ́ta èyí tó ń yọ àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Kogi àti Kwara lẹ́nu.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Paul Odama nígbà tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn ní ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 ṣàlàyé pé ní ìlú Oro-Ago ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí náà.

Odama ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2022 ni àwọn ènìyàn méjì kan, Shina Luke Abiodun àti ẹnìkan kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní agbègbè Eruku ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Egbe ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Ó ní àwọn ajínigbé náà dáná ìbọn yá àwọn ènìyàn yìí ṣùgbọ́n orí kó wọn yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa lásán ni tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ fẹ.

Ó fi kun pé nígbà tí àwọn ènìyàn náà sá dé ibi tí àwọn ọlọ́pàá wà ní àwọn lọ sí ibi tí ìkọlù náà ti wáyé tí wọ́n sì rí fóònù Tecno kan nílẹ̀.

“Fóònù yìí ni àwọn ọlọ́pàá lò láti fi ṣèwádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì ṣe àwárí rẹ̀ pé Oro-Ago ni àwọn ajínigbé náà wà.”

“Nígbà tí à ń ṣe ìwádìí ni awọn afurasí náà jẹ́wọ́ wípé àwọn ni àwọn ti ń da agbègbè náà láàmú.”

“Ìwádìí tún fi hàn pé àwọn ni wọ́n jí bàbá àti ọmọ kan gbé tí wọ́n sì gba mílíọ̀nù mẹ́fà kí wọ́n tó túwọn sílẹ̀.”

Odama ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ wí pé àwọn ni àwọn pa òṣìṣẹ́ NSCDC kan, Segun Ayegbulu tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ó fi kun pé lára àwọn nǹkan tí àwọn rígbá lọ́wọ́ wọn ni ìbọn méjì àti fóònù méjì.

Bákan náà ló ni iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti nawọ́ gán àwọn ènìyàn yòókù tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn.

Ọwọ́ tún tẹ àwọn afurasí ajínigbé méjì míì ní Oke-Ode

Yàtọ̀ sí àwọn wọ́nyí, ọwọ́ ṣìnkú òfin ti tẹ àwọn afurasí ajínigbé méjì mìíràn ní agbègbè Oke-Ode, ìjọba Ifolodun ìpínlẹ̀ Kwara.

Paul Odama sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá ni ìròyìn kan àwọn lára wí pé àwọn ajínigbé jí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún kan gbné ní òpópónà Share sí Oke-Ode.

Ó ní ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Garuba Abubakar tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Elero ti ìlú Lokongoma àti Abubakar Adam ló wà nídìí ìjínigbé ọ̀hún.

Ó ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ ọ̀gá àwọn tó gbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta náírà owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ẹbí àwọn ọmọ tí àwọn jí gbé náà ti na pápá bora.

Bákan náà ní wọ́n ní ni ìbọn tí àwọn máa ń lo láti fi ṣọṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá wá sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo ìgbìyànjú ni àwọn ń sà láti ri dájú pé àwọn nawọ́ gán ọkùnrin náà.

Odama wá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọ̀daràn láti pọ̀ sókè rajà nítorí kò sí ààyè fún àwọn oníṣẹ́ ibi ní ìpínlẹ̀ Kwara.