Àwọn ọlọ́pàá Hisbah yawọ ibi ìgbéyàwó akọsákọ, wọ́n mú eèyàn 19 sátìmọ́lé ní Kano

Oríṣun àwòrán, KANO HISBAH BOARD
Ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbò ẹ̀sìn ní ẹkùn árìwá Nàìjíríà, Hisbah ti nawọ́ gán àwọn ènìyàn mọ́kàndínlógún fẹ́sùn wí pé wọ́n lọ sí ayẹyẹ ìgbéyàwó tó wáyé láàárín àwọn akọsákọ ní ìpínlẹ̀ Kano.
Ní ọjọ́ Àìkú ni ikọ̀ Hisbah nawọ́ gán àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀dógún àti obìnrin mẹ́rin níbi ayẹyẹ náà.
Agbẹnusọ Hisbah, Lawal Ibrahim Fagge sọ wí pé àwọn kan ló ta àwọn lólobó wí pé ìgbéyàwó náà ń wáyé ni àwọn fi gba ibẹ̀ lọ.
Fagge ní nígbà tí àwọn fi máa dé ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà, àwọn méjéèjì tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéyàwó akọsàkọ ọ̀hún ni wọn ò tíì sopọ̀ tí àwọn fi túwọn ká.
Ó ní bí àwọn ṣe dé ibẹ̀ ni wọ́n fi ẹsẹ̀ fẹ tí àwọn ọlọ́pàá sì ti ń wá wọn kiri báyìí.
Ìwà ìgbéyàwó láàárín akọsákọ tàbí abosábo jẹ́ èyí tó lòdì sí òfin Nàìjíríà àti pàápàá ní ìpínlẹ̀ Kano tó jẹ́ wí pé kìkìdá àwọn mùsùlùmí ló pọ̀ níbẹ̀.
Fagge sọ fún BBC pé àwọn kò ní èròńgbà láti fi ìyà jẹ àwọn èrò tí wọ́n lọ sí ibi ìgbéyàwó dípò bẹ́ẹ̀ àwọn máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún wọn ni.
Wọ́n ní lára àwọn tí àwọn mú jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń múra bí obìnrin àti àwọn tó jẹ́ wí pé ọkùnrin bíi ti wọ́n ni wọ́n máa ń bá lòpọ̀.
Ó ní àwọn ń gbèrò láti yí àwọn ènìyàn náà lọ́kàn padà pẹ̀lú kí àwọn tó gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́.
Ilé ẹjọ́ Hish=bah kò ì tíì rán ẹnikẹ́ni lọ sí ẹ̀wọ̀n fẹ́sùn wí pé wọn jẹ́ ẹni tó ń bá irú ẹ̀yà ara rẹ̀ lò pọ̀.
Fagge fi kun pé àwọn ènìyàn méjìdínlógún tí àwọn nawọ́ gán níbi ayẹyẹ kan ní ọdún tó kọjá ni àwọn ti tú kalẹ̀.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ènìyàn náà ti tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pé àwọn máa yí ìwà àwọn padà.















