Báyìí, Mo ti ṣetán láti ṣe ìponlogo ìbò fún Tinubu àti àwọn Olùdíje APC- Buhari

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni oun ti setan lati ìpolongo ibo fun oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ati awọn olujide yooku saaju eto ìdibo lọdun 2023.
Agbẹnusọ aarẹ, Garba Shehu lo kede ọrọ naa sita lasalẹ ọjọru pe gbogbo aarẹ fi setan lati kopa ninu ìpolongo ọhun.
Aarẹ fi atẹjade naa lati koro ju si ọrọ to bu ẹnu atẹlu aarẹ bii ko ṣe kopa ninu ìpolongo ibo ẹgbẹ oṣelu naa yatọ si ti ifilọlẹ to waye nipinlẹ Jos.
"Mo ṣetan lati tẹle ìlana ẹgbẹ oṣelu APC, tí mo sì gbogbo ṣe isẹ gẹgẹ bii aarẹ Orilẹede Naijiria.
"Lakọ ni mo wa fun ẹgbẹ oṣelu APC saaju eto ìdibo aarẹ lọdun 2023."
Aare tẹsiwaju pe ìpolongo ibo ẹgbẹ oṣelu APC lo lokiki julọ lorilẹede Naijiria ti awọn yooku si n fi ṣe awukọse ninu eto ìpolongo ibo wọn.
Aarẹ ni o da oun loju pe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo bori ninu eto ìdibo ọdun to bọ lai si rogbodiyan kan kan tabi ni mago mago ninu.








