'Fóònù tí ìyàwó ń ṣáàjì ló fẹ́ lọ mú kóun àtàwọn mẹ́sàn-án mìíràn tó gan mọ́ná'

Ilé tí ìjàmbá iná náà jó gbogbo rẹ̀ pátá

Ọjọ́ mánigbàgbé ni ọjọ́rú, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá ọdún 2022 jẹ́ nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn agbègbè Gwargwaje ní ìlú Zaria, ìpínlẹ̀ Kaduna bí wọ́n ṣe pàdánù ènìyàn mẹ́wàá sọ́wọ́ ikú gbóná.

Iná mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n gan mọ́ ló ṣokùnfà ikú àwọn ènìyàn náà.

Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀mí tó nù sínú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí, ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé ní aago kan òru tún ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé àti ṣọ́ọ̀bù.

Báwo ni ìjàmbá iná náà ṣe bẹ̀rẹ̀?

Iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná ní ìpínlẹ̀ Kaduna nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ìwádìí fi hàn pé yáwà iná tó kan ara wọn ló fa ìjàmbá náà.

Iléeṣẹ́ náà tó bá àwọn ẹbí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ sí kẹ́dùn ní àwọn ti paná àdúgbò náà láti mú àdínkù bá ìpalára tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kó bá àwọn ènìyàn.

Ọ̀kan lára àwọn olùgbé àdúgbò náà, Bala Jubril pàdánù ìyàwó rẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó sì sọ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.

Jubril ní òun wà nínú yàrá òun nígbà tí òun gbọ́ tí ọmọ òun pariwo iná iná yí òun sì sọ fun wí pé kó lọ pá.

“Nígbà tí mà á fi jáde kúrò nínú yàrá mi, ariwo ti gba gbogbo àdúgbò kan, tí èmi àwọn ẹbí mi sì sá síta.”

“Ìyàwó mi wá ní òun fẹ́ lọ mú fóònù òun tó ń ṣáàjì lọ́wọ́ kí ìjàmbá iná náà tó bẹ̀rẹ̀.”

“Lásìkò tó ń yọ fóònù náà lọ́wọ́ ni iná gbe, tí kò sì wọ bàtà tí èyí sì dákún nǹkan tó ṣẹlẹ̀.”

Ó fi kun pé gbogbo ẹbí òun ni ìjàmbá iná náà ṣe àkóbá fún àmọ́ ìyàwó òun nìkan ló pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Jubril ṣàlàyé pé àwọn gbé ìyàwó òun dé ilé ìwòsàn Gambo Sawaba àmọ́ wọn kò tètè dá àwọn lóhùn títí ẹ̀mí fi bọ́ lára ìyàwó òun náà.

Murtala Muhammed Sani ti òun náà bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Ẹlòmíràn tó tún bá BBC sọ̀rọ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú ẹ̀, Ahmed Zubairu ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ogún ìṣẹ́jú ni òun ti ń gbọ́ òórùn wáyà tí òun sì ri tí èéfí ń jáde.

Zubairu ní bí òun ṣe dìde láti lọ yọ wáyà iná àwọn kalẹ̀ ni iná òun tún mọ́lẹ̀ ju tẹ́lẹ̀ lọ tó sì gbá màmá òun ṣubú lulẹ̀.

Ahmad Umar Siddan tí ẹ̀gbọ́n àti ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ tún kéde lórí ayélujára Facebook pé ìdílé kan pàdánù ènìyàn mẹ́fà.

Emir Zazzau ṣàbẹ̀wò síbi tí ìjàmbá náà ti wáyé

Emir Zazzau bá àwọn ènìyàn kẹ́dùn

Emir ìlú Zazzau, Nuhu Bamali wà lára àwọn èèkàn ìlú tó kọ́kọ́ ṣe àbẹ̀wò sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ti wáyé.

Ìmọ́mù àgbà ìlú Zaria, Dalhatu Kassim tún ṣe àdúrà fún àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Agnẹnusọ iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná ìpínlẹ̀ Kaduna, Adulaziz Abdullahi ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wáyà náà múlẹ̀.

Ó ní láti òwúrọ̀ ọjọ́rú tí àwọn ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni àwọn ènìyàn àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.

Bákan náà ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń ṣe ìwádìí lórí nǹkan tó fa iná ọ̀hún.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kaduna, Mohammed Jagile ní ó di ìgbà tí àwọn bá parí ìwádìí ni àwọn tó le sọ ohunkóhun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.