Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹ́ Ìlànà ọmọ Oòduà

Oríṣun àwòrán, screenshot
Olori ẹgbẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua Worldwide, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti fi ipo silẹ gẹgẹ bii adari ẹgbẹ naa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn iroyin kan n gbe e jade pe awọn edeaiyede ati dukuu kan to n waye laarin ẹgbẹ ajijangbara ominira ilẹ Yoruba naa lo n muu fi ipo silẹ, Ọjọgbọn Akintoye ni ko ri bẹẹ rara.
Ninu iwe kan to kọ si Ọjọgbọn Adeniran ti wọn ṣẹ̀ṣẹ yan lati maa dari ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Akintoye ṣalaye pe kii ṣe ohun to faa ni yi.
“Gẹgẹbi o ṣe mọ ju ẹnikẹni lọ, o ti le ni ọdun kan ti mo ti n fẹ fi ipo yii silẹ nitori awọn ẹru wuwo ojuṣe oun ati ọrọ ijijangbara ti a n le fun ọjọ ori mi. Inu mi si dun pe iwọ, gẹgẹbi ẹni to sun mọ mi julọ, atawọn ọmọ ẹgbẹ ilana ọmọ Oodua pẹlu igbimọ rẹ gbogbo lo n rọ mi pe ki n ṣi tẹsiwaju.”
Ọjọgbọn Akintoye ṣalaye pe ipade awọn agbaagba eto ijijangbara fun ominira Yoruba to waye ni nnkan bii oṣu kan sẹyin ni wọn ti fohun ṣọkan pe ki oun o fi ipo naa silẹ nitori awọn ipenija ojuṣe rẹ ati ọjọ ori oun.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
“Ni ti awọn wahala to wa ni ẹgbẹ Ilan, mo gbagbọ pe iwọ pẹlu le jẹri sii pe mi o fi ipo yii silẹ nitori eyi, ati pe, ipenija to ga julọ ninu ohunkohun ko lee mu mi ṣojo rara. Mo ni idaniloju Ọlọrun pe mo lee kogoja ninu wahala to butru julọ laarin awọn eniyan nitoriSlọrun ti fun mi ni ẹbun ọkan to ni ifẹ gbogbo eniyan.”
Atẹjade kan ti akọwe agba ẹgbẹ naa, Tunde Amusat fi sita lọjọbọ sọ pe Ọjọgbọn Wale Adeniran to jẹ igbakeji rẹ ni yoo maa di ipo naa mu bayii.








