Reluwé láti Mile 2 sí Marina á bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Eko, wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ kí o tó lè wọ̀ ọ́

Oríṣun àwòrán, Jubril Gawat
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko ti ṣe ifilọlẹ ipari reluwee, to jẹ apa kan ọna ọkọ oju irin tí wọn pe ni Blue Line
Sanwo-Olu pẹlu awọn eekan ninu ìjọba ìpinlẹ Eko wọ reluwee ọhun lati National Arts Theatre sì Marina l'Ọjọru ana.
Gomina sọ pe ninu oṣu kinni ọdun 2023 ni wọn yoo ṣe ifilọlẹ naa ti yoo si bẹrẹ isẹ lori igun Mile 2 sì Okoko fun awọn araalu.
O salaye pe eeyan ọgọrun meji ati abọ ni yoo ni anfani lati wọ ọkọ reluwee ọhun lọjọjumọ

Oríṣun àwòrán, Jubril Gawat
Ipele akọkọ ree ninu ipele meje
Agbẹnusọ fun Gomina lori ọrọ iroyin, Jubril Gawat sọ pe ipele akọkọ ni eyi ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ yii nínú meje ti ijọba ipinlẹ Eko ni erongba lati ṣe fun araalu.
Gawat sọ eleyi lori opo ayelujara rẹ nigba to n ṣe afihan awọn aworan ifilọlẹ naa.
O tẹsiwaju pe igbesẹ yìí ni o jẹ ipele meje, eyi ti yoo bẹrẹ lati Marina lọ sí Okolomaiko nipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, Jubril Gawat
Bawo ni awọn eeyan yoo ṣe máa san owo fun lílo reluwee?
Ọga agba fun eto irinna nipinlẹ Eko, Onimọẹrọ Abimbola Akinajo salaye pe awọn arin irinajo yoo lo ilana ti ipinlẹ Eko ti gbé kalẹ lati fi san owo fun lílo reluwee náà.
O ni ilana yii awọn fi san owo fun lílo ọkọ oju omi ati ti bọọsi akero nipinlẹ naa.
"Ilana ti a gbe kalẹ yìí ni yoo fun awọn lafani lati ko awọn eeyan toto ọgọrun meji ati abọ lojojumọ, tí yoo si tun pele sì ti a ba parí oju ọna reluwee ọhun.
"Kaadi ti a lo fún ọkọ oju omi ìjọba ati ti bọọsi akero naa ni awọn eeyan yoo maa lo lati fi san owo fun lílo ọkọ reluwee náà ."















