Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Ondo, Ọgagun Tuoyo dágbére fáyé

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ologun nipinlẹ Ondo nigba kan ri, Ọgagun Sunday Esi Tuoyo ti jade laye.
Laarin ọdun 1978 si 1979 ni Ọgagun fẹyinti Tuoyo fi ṣe akoso ijọba ipinlẹ Ondo.
Ọkan lara awọn ọmọ rẹ fẹ gomina ipinlẹ delta nigba kan ri, Emmanuel Uduaghan.
Ọdun 1938 ni wọn bi alagba Sunny T, gẹgẹ bi ọpọ awọn eeyan ṣe maa n pe e.
Oun si lo fa akoso iṣejọba ipinlẹ Ondo le Pa Micheal Adekunle Ajasin lọwọ, ti oun pẹlu ti jade laye.
Nigba to n kọrin aro lẹyin akọni to lọ, gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu juwe iku oloogbe Tuoyo bii adanu nla fun ipinlẹ Ondo.
Akeredolu ni Tuoyo wa lara opo to di ipinlẹ Ondo mu ati pe ipa rẹ nigba to fi ṣe gomina ipinlẹ Ondo ko kere rara.











