APC kéde ààwẹ̀ àti àdúrà ọjọ́ mẹ́ta ṣaájú ìdìbò gbogbogbò

Oríṣun àwòrán, INEC
Bí ó ṣe ku ọjọ́ péréte kí ètò ìdìbò gbogbogboò wáyé káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ẹ gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìpínlẹ̀ Osun ti darí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ àwẹ̀ àti àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́ta.
Ohun tí ààwẹ̀ àti àdúrà náà dá lé lórí ni láti fi wá ojú rere Ọlọ́run lórí ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà.
Adelé alága APC Osun, Tajudeen Lawal ló kéde ìdarí yìí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ìlú Osogbo, olú ìlú ìpínlẹ̀ Osun.
Lawal ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC mọ ìwúlò àti pàtàkì àdúrà ni àwọn ṣe darí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn láti bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ àti àdúrà láti ọjọ́rú ọjọ́ Kejìlélógún sí ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kejì tó jẹ́ àìsùn ọjọ́ tí ètò ìdìbò máa wáyé.
Ó fi kun pé ohun tí kókó àdúrà àti ààwẹ̀ àwọn máa dá lé lórí ni pé kí Ọlọ́run gba àkóso lórí ètò ìdìbò náà àti pàápàá lórí olùdíje àwọn Bola Ahmed Tinubu àti àwọn olùdíje sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Bákan náà ló tún rọ̀ wọ́n láti gbàdúrà kí ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọ̀wọ́ rọsẹ̀ kí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn sì mókè.
Nígbà tó ń rán wọn létí pé káàdì ìdìbò wọn ni èròjà wọn láti dìbò fún ẹni tó wù wọ́n lásíkò ìbò, ó gbà wọ́n níyànjú láti tẹ̀lé gbogbo òfin tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò INEC là kalẹ̀ lórí ìbò náà.
Lawal fi kun pé àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ fi àyè gba ẹnikẹ́ni láti mú wọn da ètò ìṣèjọba àwaarawa rú ṣaájú, lásìkò àti lẹ́yìn ìdìbò náà.












