Lẹ́yìn fídíò BBC, Agbala Gabriel ra ilẹ̀ fún Ìyá ìbejì ọmọ aráyé le, Foluke Daramola gba ilé fún ún- Ọmọ Mama Iya Ibeji Ọmọ Araye le

Oríṣun àwòrán, Others
Mama Iya Ibeji Ọmọ Arayele ti ri aanu gba lọwọ awọn ọmọ Naijiria lẹyin fidio ti wọn ṣe pẹlu BBC Lati ṣalaye ailera ti mama n la kọja.
Agba osere tiata, Arabinrin Adenike Adegboye lo wa ni idubulẹ aisan rọpa-rọṣẹ fun ọjọ pipẹ ti o si ti ṣe idena fun ọrọ ṣiṣọ ati lati rin.
O ri ijoko ni Mama wa lasiko ti ọmọ wọn obinrin to ku, Aderonke ba BBC Yoruba sọrọ lori ipenija wọn.
Ọkan lara ipenija ti wọn n la kọja ni ile gbigbe ti wọn si fun wọn ni gbedeke Ọjọ kejidinlọgbọn lati kuro ni ibi ti wọn wa.
Amọ ki ọjọ ti wọn fun wọn ni gbedeke naa de ni aanu jade si wọn lati ọwọ Woli Agbala Gabriel lẹyin ti ileeṣẹ BBC gbe fidio ibi ti ilera mama osere naa de duro.
Agbala Gabriel ra ile fun Mama mi si Ilu Ibadan – Aderonke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Agbala Gabriel
Arabinrin ọmọ Mama Iya Ibeji ọmọ Arayele ti kede pe lọọtọ ni Agbala Gabriel ra ilẹ fun mama ọun
Lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ nibi ti ọrọ de duro lo ti ṣalaye bẹẹ
Fidio to wa lori ẹrọ ayelujara ṣafihan ibi ti alagba naa ti fi ilẹ naa han mama, ti mama si fi idunnu rẹ han.
Ninu fidio naa ni wọn ti ṣe ipinlẹ ile naa ti mama si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aanu ti oun ri gba naa.
Alagba naa ṣeleri lati kọ ile ọhun pari fun mama ki o le ri ile gbe ati itọju to peye.
‘’Gbajugbaja osẹrebinrin Foluke Daramola gba ilé fún Mama mi ni Ikorodu’’

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu ọrọ rẹ, Ọmọbinrin Aderonke naa dupẹ lọwọ gbajugbaja osẹrebinrin, Foluke Daramola fun aduroti rẹ lati igba ti mama ti n ṣe aisan
Aderonke ni Daramọla lo ti n pese ounjẹ fun mama lati igba ti mama ti bẹrẹ aisan to si n tọju wọn.
Bakan naa lo fikun un pe nibayii Foluke Daramola ti gba ile fun Mama ni agbegbe Ikorodu ni ilu Eko lẹyin ti o gbọ pe wọn ni iṣoro ile gbigbe.
Aderonke ni wọn ti gba ile oniyara meji (2-bedroom flat) fun mama ti wọn si ti san owo ile ọdun kan fun wọn.
Amọ o ni iṣoro ti awọn ni bayii ni pe onile naa ni awọn gbọdọ san owo ile ọdun meji.
Ọmọ mama Iya Ibeji ọmọ Arayele naa fikun un pe gbajugbaja oṣere ọhun ṣeleri lati ba awọn eniyan sọrọ ti wọn le ṣe iranwọ fun wọn ati san owo ọdun kan to ku.
‘’Mo fẹ lọ gbe Mama wa si Ikorodu ki ọkan wọn le balẹ’’

Nibayii, Aderonke ni ohun to kan ni lati gbe mama wa si ilu Eko ni agbegbe Ikorodu ti wọn ti gba ile tuntun fun wọn.
O ni eyi yoo fi ọkan mama balẹ, ti yoo si wa ni ọdọ awọn eniyan rẹ.
Bakan naa lo ni eyi yoo fi ọkan mama balẹ ki oogun le ṣiṣẹ ni ara wọn.
Ninu ọrọ rẹ, o fikun un pe Agbala Gabriel to gba mama si ile ijọsin wọn ni ilu Ibadan, to si n tọju wọn ti fun oun laaye lati wa gbe mama wa si ilu Eko titi ti yoo fi kọ ile tuntun naa tan fun mama.












