Ọlọ́pàá márùn-ún fojú ba ilé ẹjọ́ fún ìpàníyàn ní America, wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró...

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa Memphis ni orile-ede America ti tu awọn ikọ akọni agbofinro ti won n pe ni Scorpion special Unit ka.
Eyi waye lẹyin ti awọn ọlọpaa marun un ninu awọn ikọ naa gba ẹsun pe wọn pa Tyre Nicholas.
Apeja oruko Scorpion ti wọn n jẹ ni: “Street Crimes Operation to Restore Peace in Our Neighborhoods”.
Olopaa aadọta lo maa n wa ninu ikọ akọni Scorpoion yii.
Iṣẹ wọn ni lati fopin si iwa ipa ati jagidijagan ni adugbo.
Fonran fidio kan lo kọkọ jade nibi ti wọn ti na Tyre eni ọdun mokandinlogbon pa ni ọjọ keje, oṣu kinni, ọdun.
Oga agba Davis ba BBc sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lori idi ti wọn fi da ikọ akọni SCORPION silẹ nibẹ.
O ni ki wọn le tubọ mojuto alaafia ati aabo agbegbe kọọkan ni wọn ṣe ro wọn ni agbara.
O gba pe nitooto ni ẹri ti fihan pe bi ikọ Scorpion ṣe lu Tyre naa ti pọju.
Davis tun sọ pe eyi ko ba ilana ti won fi ṣagbekalẹ won ati ẹtọ ara ilu mu.
O ni awọn ko si ni fi igbakan bọ ikan ninu ninu iwadii ti wọn n ṣe lori iṣẹlẹ naa.
Ati pe idajọ ododo yoo waye fun ika to ba ṣe lẹyin iwadii lori iṣẹlẹ iku Tyre Nicholas















