''Kò sí ohun tó jọ ọ! Ìwé òfin Naijiria kò fi àyè gba ìjọba fìdíẹ'' - Olisa Agbakoba

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorilẹede Naijiria tẹlẹri, Olisa Agbakoba ti ni ko si iwe ofin to fi idi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni le gbe ijọba fidiẹ kalẹ ni orilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade ti agbẹjọrọ agba naa fi lede lo ti bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn n pero lati gbe ijọba fidiẹ kalẹ ni Niajiria.

Eyi ko ṣẹyin ikilọ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi lede lori ipetepero awọn eniyan kan lati da wahala silẹ ni Naijiria nipa gbigbero lati gbe ijọba fidiẹ kalẹ.

Awọn wọnyii ni DSS ni wọn ko fẹ ki ijọba to wa nibẹ gbe ijọba fun asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni ọjọ ti wọn bura wọle fun un.

Agbẹjọro agba naa ni idibo sipo aarẹ ti waye ni Naijiria, bio tilẹ jẹpe idojukọ wa ninu idibo naa, awọn eniyan gbọdọ bọwọ fun igbesẹ eto oṣelu tiwa n tiwa.

’’Aarẹ ti wọn dibo yan ti wa nitori naa, ẹ gbọdọ eto ijọba tiwantiwa laaye.’’

Bakan naa lo kesi awọn ọmọ Naijria lati kọ ipe fun ijọba fidiẹ naa nitori ko ni ṣeeṣe, iwe ofin ko fi aye gba a.

Ero Agbakoba ni pe nigba ti awọn oludije ti gba esi idibo ti wọn si ti gba ileẹjọ lọ, ko si aaye fun ki ẹnikẹni da alaafia orilẹede naijiria ru, eyi ko bofin mu rara.

DSS, àlàyé kò kájọ, ẹ tètè lọ kó àwọn tó fẹ́ dojú ìjọba alágbádá dé sí àhámọ́ - APC, PDP

Osisẹ DSS

Oríṣun àwòrán, DSS

Igbimọ olupolongo ibo aarẹ fẹgbẹ oselu APC ati PDP ti rọ ileesẹ oͅteͅleͅmuyeͅ DSS lati gbena woju awọn to fẹ doju ijọba alagbada bolẹ.

Bola Tinubu ni ajọ INEC kede gẹgẹ bi ẹniti o jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ orilẹede yii.

Ṣaaju ni ileesẹ DSS ti kede pe awọn oloselu kan ti n dete lati doju ijọba tiwantiwa bolẹ,ti wọn si fẹ da ijọba awarawa ru.

Lasiko to n ba iwe iroyin Punch sọrọ, Idris Mohammed to jẹ ọmọ igbimọ olupolongo ibo fẹgbẹ APC rọ ajọ naa lati fofin mu awọn to eeyan to ba jẹbi iditẹ naa ni kiakia.

Mohammed ni igbimọ olupolongo ibo fun ẹgbẹ oselu APC fọwọ si igbesẹ ajọ otẹlemuyẹ naa pẹlu iroyin ti wọn gbe sita.

Muhammed ni DSS gbọdọ siṣẹ karakara lati mu awọn to n gbero iwa ibi naa si ahamọ.

Ẹnikẹni ko gbọdọ sọrọ nigba ti wọn ba n fi pampẹ ofin mu awọn to jẹbi iwa naa - Keyamo

Nigba to n sọrọ lori ikede ileesẹ DSS naa, Festus Keyamo ni atẹjade ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ naa lo fidi iroyin ti oun fi lede lọsẹ to kọja mulẹ pe awọn kan n gbero lati doju ijọba alagbada kodo.

Keyamo ni nibayi ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti kẹẹfin, ti wọn si tun kede ipalẹmo awọn mọdaru naa, ẹnikẹni ko gbọdọ sọrọ nigbati wọn ba n fi pampẹ ofin mu awọn to jẹbi iwa naa.

O ni ọpọ awọn to n ru ofin madaru ni ko mọ oun ti oju ọpọ ri nigba isejọba ologun ati bi wọn ko se fayegba etọ ọmọniyan.

Igbayi laarọ DSS, ibo lo wa nigba ti wọn n dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ wa - LP

Ibrahim Abdullahi, ti ẹgbẹ oselu PDP ni o ya oun lẹnu bi DSS ko se ti i mu ẹnikẹni fun ẹsun lati pagidina iselu alagbada.

Ibrahim ni ọpọ awọn to ni ariwisi lori abajade esi idibo lo ti wa nile ẹjọ, bẹẹ ni ko si idi kankan lati da wahala silẹ.

O ni ile iṣẹ DSS ko ni awijare kankan mọ lati fofin mu ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun naa.

Ibrahim Abdullahi ni wọn gbọdọ fofin mu wọn fun ẹsun iditẹ gbajọba ni.

Amọ Yunusa Tanko, to jẹ agbẹnusọ fẹgbẹ oselu Labour Party, ninu esi rẹ si atẹjade ajọ DSS naa ni DSS ko le dunkoko mọ awọn ọmọ orileede yii.

Tanko ni ibo ni DSS wa nigba ti awọn kan fipa ji ibo gbe.

O ni “nigba ti awọn kan halẹ mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu Labour, ti wọn si tun di wọn lọwọ lati dibo, nibo ni ajọ DSS wa”.

Àkọlé fídíò, Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni Oluwaseun Peter Adedeji tó ni iléeṣẹ́ PoS kan.

DSS kéde ọ̀nà méjì táwọn olóṣèlú kan ń déte láti dojú ìjọba alágbádá bolẹ̀

Ileesͅeͅ oͅteͅleͅmuyeͅ ni Naijiria, DSS ti ni lootoͅ ni awoͅn kan n gbimoͅ pọ lati da alaafia orileͅede Naijiria ru nipa gbigbe ijoͅba fidieͅ kaleͅ.

Agbeͅnusoͅ fun ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, Peter Afunaya lo sisọ loju ọrọ yii loju opo Instagram woͅn pe awoͅn oloselu kan n gbimoͅ ika si orileͅede Naijiria.

Afunaya ni awoͅn yoo sa gbogbo ipa awoͅn lati gbogun ti eͅnikeͅni to ba gbimoͅ lati da rogbodiyan sileͅ ni Naijiria.

Bakan naa ni woͅn ni awoͅn ti sͅawari awoͅn oloselu kan ti woͅn n gbimoͅ lati gbe igbeseͅ yii ti woͅn si ni woͅn yoo fi oju wina ofin.

Awọn osisẹ DSS

Oríṣun àwòrán, DSS

"Gbogbo awoͅn to feͅ diteͅ gba ijoͅba nipa sise iwọde tako idibo gboͅdoͅ dakeͅ ni kiakia"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‘Ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ti kẹfin awọn kan to n gbẹro lati doju ijọba tiwantiwa bolẹ, a si ri igbeṣẹ yii, eyi ti awọn kan gẹgẹ bi ọna aitọ lati doju iwe ofin ilẹ wa bolẹ ati lati da ilana isejọba awarawa ru, ki wọn si da rogbodiyan silẹ .

Ọna aitọ yii ko ba ofin mu ninu eto ijọba awarawa ati si alafia awọn ọmọ orilẹede yii, paapaa julọ, pẹlu bi ipejọpọ wọn ti n waye lẹyin eto idibo to kẹsẹ jari ni ọpọ ibi gbogbo lorilẹede yii.

Awọn to n gbero nnkan wonyi, ninu ipade wọn ti n ronu ọpọ ọna lati gbe ero wọn sita, ninu eyi ti wọn fẹ lo ifẹhonuhan ni awọn ipinlẹ to se pataki julọ, ki ijọba le kede ilu o fararọ nilẹ yii.

Lara awọn ohun ti wọn tun n gbero ni lati gba iwe asẹ nile ẹjọ lati da eto ibura wọle fun igbimọ ẹka alasẹ ati tawọn asofin tuntun.

Ile isẹ ajọ to risi ipese aabo labẹnu faramo ipinnu Aarẹ Buhari ninu ilakaka rẹ lati gbe ijọba kalẹ laisi rogbodiyan.

Bakan naa si la fara mọ igbimọ ti Aarẹ Buhari gbe kalẹ lati seto igbejọba silẹ fun ijọba tuntun to n bọ.

A o si ba awọn osisẹ alaabo yoku sisẹ papọ lati ri daju wi pe eto igbajọba ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbon oṣu karun ọdun 2023 kẹsẹjari.

A wa kilọ fun awọn to n gbẹro iwa madaru naa lati jawọ, a si rọ awọn osisẹ ẹka idajọ, Akọroyin atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lawujọ lati mase jẹ ohun elo ti yoo da alafia ati ifọkanbalẹ orilẹede yii ru

A ko ni siyemeji lati gbe igbẹsẹ to yẹ lọna ofin lati koju oro sawọn to n gbero lati da omi alafia Orilẹede yii ru”.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post