NBC ní kí Channels san N5m lórí àbùkù Datti Ahmed nípa Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bola Tinubu
Ileesẹ to n sakoso eto igbohunsafẹfẹ nilẹ wa, NBC ti pasẹ pe kileesẹ agbohunsafẹfẹ Channels san miliọnu marun naira .
Owo naa ni NBC yoo jẹ owo itanran lori bi ileesẹ Channel se lu ofin to de eto igbohunsafẹfẹ lasiko to gbalejo oludije dun ipo igbakeji aarẹ fẹgbẹ oselu Labour, Datti Baba-Ahmed
Gẹgẹ bi ileesẹ akoroyinjọ nilẹ wa, NAN se salaye, igbesẹ yii lo foju han ninu lẹta kan ti NBC kọ si Channel lọjọ Ẹti ana.
Saaju ni aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Ahmed Tinubu ti kọwe si NBC pe ki wọn fiya jẹ ileesẹ agbohunsafẹfẹ Channels fun bi wọn sẹ sofin lasiko ti wọn se ifọrọwerọ pẹlu igbakeji oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Datti Baba Ahmed.
Ninu iwe ẹsun naa, ti ẹni to se kokari ipolongo ibo fun Tinubu, Bayo Onauga buwọlu fun awọn akọroyin ni "Pẹlu ilana ofin ajọ to n sakoso eto igbehunsafẹfẹ pe ki awọn ileeṣẹ gba gbo ọrọ abuku ti ẹni to ba binu ba sọ, ki wọn si se iwadii to peye sugbọn Ileeṣẹ Channels kọ lati tẹle ofin yii rara."
Tinubu fi ẹsun kan Baba Ahmed pe gbogbo ẹsun to fi oun lo tabuku ilana ti eto idibo aarẹ to waye kẹdọgbọn oṣu keji.
"Sisọ pe Labour Party lo bori eto idibo lori ẹrọ agbehunsafẹfẹ lodi sofin"
Ninu iwe ẹsun naa, Tinubu ni ẹni to se kokari eto naa yẹ ko Baba Datti lẹnu pe nnkan to sọ lodiu sofin, to si yẹ ki oun naaa ri ya labẹ ofin.
"Alejo Ileeṣẹ Channels, Datti Baba Ahmed ni kI Aarẹ Muhammed Buhari ma se buru Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan nitori ko ni ida mẹdọgbọn ibo ni oluilu AAbuja, to jẹ ọakn lara ohun ti oludije nilom lati fi bori ibo.
"Ọrọ yii ko yẹ ko jade lẹnu Baba Datti nitori ọrọ si wa ni ileẹjọ ati pe ileẹjọ nikan lo le yi asẹ ajọ INEC pada.
Onanuga tẹsiwaju pe gbogbo ti Datti sọ ni ko ba ofin mu rara ati ko ki n se ajọ INEC, ti ko si ẹtọ lti kede pe oludije kan lo bori eto idibo.
"Ọrọ ti Datti sọ pe ẹgbẹ oṣelu Labour Party lo bori eto idibo ni lodi si asẹ ti ofin fun ajọ INEC lọdun 1999 pe ajọ nikan lo asẹ lati kede ẹnikẹni pe oun lo bori. Yatọ si iyẹni ni ileẹjọ kotẹmilọrun.
"Gbogbo ọrọ ti Datti Baba Ahmed sọ ni o lodi sofin paapa ibi to ti ki Aarẹ Buhari maa gbe agbara fun Tinubu nitori o sese ko jẹ opin si ijọba awarawa lorilẹede Naijira ni ko ba ofin mu.
"A yẹ ki agbehunsafẹfẹ ṣe ikilọ fun irufẹ ọrọ ko yẹ lati sọ sita
"A wa rọ ajọ to n sakoso igbehonusafẹfẹ pe ki wọn gbe igbesẹ to yẹ lori ileeṣẹ agbehunsafẹfẹ Channels fun bi wọn tapa sofin."
''Ọmọ Naijiria mílíọnù 25 yóò kojú ìyàn ní oṣù kẹ́fà sí ìkéje ọdún 2023''

Oríṣun àwòrán, UN
Ajọ Iṣọkan agbaye, UN ti ni okere tan ọmọ Naijiria miliọnu marundinlọgbọn ni iyan ati aisi ounjẹ yoo ba finra ni Oṣu Kẹfa si ikeje ọdun 2023 yii.
Ninu atẹjade ti ajọ October 2022 Cadre Harmonisé ti ajọ UN ṣe onigbọwọ fun lo gbe iroyin naa jade lasiko iwadii eleyii ti wọn ma n ṣe ni ẹẹmeji ni ọdọọdun.
Eyi ju iye awọn eniyan ti wọn sọ ṣaaju pe miliọnu mẹtadinlogun ni yoo koju ọwọngogo ounjẹ.
Lara awọn ohun ti wọn kede pe yoo fa iyan yii ni awọn eniyan to n koju ija si ara wọn, oju odo ti ko dara, ọwọngogo ounjẹ ati ọwọngogo ohun elo ounjẹ.
Ajọ naa kede pe awọn ti wọn n da wahala silẹ ni agbegbe Borno, Adamawa ati Yobe nipa ijinigbe nibẹ ni o ṣokunfa iyan ni agbegbe naa.
Bakan naa ni wọn fikun un pe ojo arọrọda ni agbegbe Katsina, Sokoto, Kaduna, Benue ati Niger.
Gẹgẹ bi akọsilẹ wọn, ojo arọrọda ba ọgba oko ounjẹ to le ni hectares 676,000 jẹ.
Wọn si fikun un pe ojo arorọda ko ṣẹyin oju ọjọ to n gbona jainjain, eleyii to n ba ere oko jẹ.

Oríṣun àwòrán, UN
Eniyan 3m ninu 17m lo n koju aisi ounjẹ ni ariwa Naijiria - UN
‘’Awọn eniyan miliọnu mẹta ninu miliọnu mẹtadinlogun ti wọn n koju aisi ounjẹ lọwọ wa lati ariwa orilẹede Naijiria.’’
‘’Lai si igbesẹ ni kiakia, ọpọ eniyan ni yoo fi oju wina aisi ounjẹ’’
‘’O ṣeni laanu pe awọn ọmọde naa n faragba ninu iṣẹlẹ iyan yii, to si ṣeeṣe ko ru soke si.’’
Ajọ UN wa kesi ijọba orilẹede Naijiria, awọn ajọ oluranlọwọ lagbaye to fi mọ awọn ileeṣẹ aladan,i lati ṣeranwọ ni kiakia lati gba awọn eniyan ninu iyan to n bọ naa.
UN fikun un pe awọn mọlẹbi ti ko ri ọwọ rọri ni yoo fi ara gba ninu iṣẹlẹ naa julọ nitori naa ki ijọba wa ọna abayọ lati pese ounjẹ fun awọn araalu ni kiakia.
















