"Ọlọ́run tó da mi mọ ìdí tó fi ṣe mí ní akọ tó fẹ́ràn ìbálòpọ̀ akọsákọ"

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní orílẹ̀ èdè Uganda, lọ́sẹ̀ tó kọjá, buwọ́lu òfin kan tó lágbára, èyí tó ń fa ìfaǹfà ní àgbáyé.
Òfin náà ni òfin tó dènà ìbálòpọ̀ láàárín akọ sákọ àti abo sábo.
Káàkiri àgbáyé ni wọ́n ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Uganda yìí.
Èyí tó jẹ́ wí pé tí ààrẹ bá fi lè buwọ́lùú, ẹni tí wọ́n bá mú tó ní ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo, ló ṣeéṣe kó lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére.
Tí òfin náà bá fi lè jẹ́ ìbuwọ́lù, gbogbo àwọn ènìyàn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo tó ń ṣe àtìpó ní àwọn ìbùgbé kan, nígbà tí wọ́n lé wọn kúrò nílé, ni wọ́n máa pàdánù ilé wọn.
"Òfin yìí tún le ṣàkóbá fún àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo"
Àbá yìí, èyí tó ku kí ààrẹ Uganda buwọ́lù kó tó di òfin fi ìjìyà ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹnikẹ́ni tó bá jáde láti sọ pé òun ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo.
Bákan náà ni ẹni tó bá ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo tó bá fipá bá ọmọdé lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin náà ṣe sọ yóò gba ìdájọ́ ikú.
Bẹ́ẹ̀ náà ni òfin yìí tún le ṣàkóbá fún àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo tí wọ́n ń ṣe àtìpó ní àwọn ilé ìgbé kan lẹ́yìn tí wọ́n lé wọn kúrò nílé nítorí ó ti di ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹnikẹ́ni láti gba àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sílé.
Orílẹ̀ Uganda wà lára àwọn orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ méjìlélọ́gbọ̀n tó sọ ìwà ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo di ìwà ọ̀daràn.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo kọminú lórí òfin tuntun yìí
Ní ọdún 2019 ní àṣírí Ali tó ti fi irú ìbálòpọ̀ tó fẹ́ràn pamọ́ fún ọjọ́ pípẹ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ko ní ilé ìgbáfẹ́ àwọn tó máa ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo kan ní olú ìlú Uganda, Kampala.
Ali ní ìgbà náà ni bàbá òun sọ fún òun pé òun kò fẹ́ rí òun mọ́ àti pé òun kìí ṣe ọmọ òun nítorí òun kò lè bí ọmọ bí irú rẹ̀.
Ali, èyí kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan, tó jẹ́ ọmọ ogun ọdún ó lé díẹ̀ ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ojú àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsáko tàbí abosábo ń rí ní orílẹ̀ èdè Uganda.
Lẹ́yìn tí Ali kúrò nílé ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, ilé àwọn aṣàtìpó tí kò níṣẹ́ ló kọ́kọ́ ń gbé kí àwọn ọlọ́pàá tó lọ kó wọn tí wọ́n sì fi ojú wọn hàn fún aráyé.
“Àwa tí wọ́n kó nígbà náà tó ogun tí wọ́n sì kó wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n fẹ́sùn wí pé a lu òfin kónílé gbélé lásìkò tí Covid-19 ń jà.
“Mo mọ̀ wí pé Ọlọ́run ló da mi, ó sì mọ ìdí tó ṣe dá mi báyìí”

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ń tutọ́ sí àwọn lára nígbà tí àwọn dé ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ló mọ̀ nípa ìròyìn àwọn tí àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n sì lu àwọn bíi kúkú bíi yíyè nítorí pé àwọn jẹ́ ẹni tó máa ń ní ní ìbálòpọ̀ akọsáko.
Àmọ́ nígbà tí BBC kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Uganda, Frank Baine kò sí ẹnikẹ́ni tó fìyà jẹwọ́n nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn.
Ali ṣàlàyé pé oríṣiríṣi ìkọlù ni àwọn ènìyàn máa ń ṣe sí òun tí wọ́n bá ti mọ irú ènìyàn tí òun jẹ́, tí ọ̀pọ̀ sì máa ń sọ pé àwọn máa pa òun ni.
Ó ní inú fu àyà fu ni àwọn wà báyìí nítorí tí ààrẹ bá fi lè buwọ́lu àbá tuntun yìí, àwọn kò ní ibi tí àwọn máa ma gbé nítorí ẹni tó ni ilé ìgbé àwọn ti ń sọ fún àwọn láti kó ẹrù àwọn.
Ó ní ìrònú tó bá òun báyìí ni pé níbo ni òun máa lọ nítorí gbogbo ènìyàn ló ń sọ pé àwọn kìí ṣe ènìyàn tó dá pé.
Ali ní pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí òun ń fojú wì, òun kò fi ẹ̀sìn Islam tí òun ń ṣe sílẹ̀.
“Mo mọ̀ wí pé Ọlọ́run ló da mi, ó sì mọ ìdí tó ṣe dámi báyìí nítorí náà mo ṣì máa ń kírun.”
“Mò ń gbàwẹ̀ bí Ramadan ṣe ń lọ lọ́wọ́ yìí.”












