Jimoh Aliu kọ́ ló ṣe àwárí Fadeyi Oloro àti Orisabunmi, ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ńlá kan ló sọ̀ àwọn méjèèjì di ìlúmọ̀ọ́ká - Yemi Farounbi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja onimọ nipa fiimu sise ati aṣoju Naijiria si orilẹede Philippine, Yemi Farounbi ti sọ bo ṣe ṣe awari gbajugbaja oṣere tiata, Ojo Arowosafe ti ọpọ mọ si Fadeyi Oloro ati arabinrin Folake Aliu, ti ọpọ mọ si Orisabunmi.

Farounbi sọ eyi lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin Nigeria Tribune sọrọ lori iriri rẹ ni ile aye ati iṣẹ to yan laayo.

O ni oun gbe igbeṣẹ lati bẹrẹ iṣẹ fiimu ṣiṣe lẹyin ti oun kuro ni ileesẹ mohunmaworan NTA nilu Ibadan, ti oun ti n ṣiṣẹ tẹlẹ.

Lẹyin naa lo ni oun si bẹrẹ si ni ṣe fiimu, ti oun si kọkọ ṣe fiimu ti wọn pe orukọ rẹ ni King Henri Christophe.

Bi mo ṣe mọ Fadeyi Oloro ati Orisabunmi - Farounbi

Farounbi ni ẹbun ni oun ri gba ni ọwọ Olorun lati jẹ ẹni to mu awọn gbajugbaja oṣere yii di ilumọọka.

"Agbegbe Ilepa ni Ikare akoko ni wọn n gbe lasiko ti mo n ṣiṣẹ ni NTV Akure.

Awọn ti wọn n ba mi ṣiṣẹ ni NTV Ibadan fẹ tẹle mi wa si Akure nigba naa, to fi mọ awọn ẹgbẹ Alawada, ẹgbẹ Ajimajasan ati ẹgbẹ Awada Troupe.

‘’Amọ mo pinnu ni ọkan mi lati wa awọn oṣere miran ni ilu Akure, ti wọn ti n ṣere tẹlẹ.’’

‘’Nigba ti mo de Akure ni mo pade awọn ẹgbẹ osere Jimoh Aliu abi Aworo pẹlu aya rẹ, Folake Aliu. ‘’

‘’Nigba naa, kii se Ojo Arowosafẹ lo n jẹ Fadeyi nigba naa, Daramola to n jẹ Egbeji bayii ati iyawo rẹ, iyawo Daramola lo n jẹ Fadeyi ati Orisabunmi nigba naa.’’

Yemi Farounbi

Oríṣun àwòrán, Yemi Farounbi/Facebook

‘’Nibi ere itage ti a lọ ṣe ni Fasiti Obafemi Awolowo ni mo ti sawari Fadeyi ati Orisabunmi’’

‘’Iṣẹlẹ kan lo waye ni ọgba Fasiti Ọbafẹmi Awolowo nilu Ile Ife nibi ti a ti fẹ ṣe ere Igbo Olodumare.

Amọ Daramola ati iyawo rẹ ti wọn n ṣe Fadeyi Oloro ati Orisabunmi nigba naa ko tete de ni gbagede Anphi Theatre ti ere itage naa ti n waye.

Ara awọn akẹkọọ to fẹ woran ere itage naa ko si balẹ mọ.

‘’Awọn akẹkọọ fasiti ifẹ naa ti bẹrẹ si ni pariwo pe ki a wa bẹrẹ ere, ti a ko si mọ bi a o ti ṣe e.’’

‘’Lẹyin naa ni Ojo Arowosafe ti o ma n ṣe ọmọ Fadeyi ninu ere ere tẹlẹ, ni oun le ṣe ere naa gẹgẹ bi Fadeyi fun ara rẹ, ti Shade Aliyu si ni oun yoo ṣe Orisabunmi.’’

‘’Nitori pe a ko ni ọna abayọ miran ni a ṣe lo Ojo Arowosafẹ gẹgẹ bi Fadeyi oloro, ti arabinrin Aliu si ṣe Orisabunmi.’’

"Inu awọn akẹkọọ dun si ere itage naa lai mọ pe Fadeyi ati Orisabunmi ko se ere naa ri"

Yemi Farounbi tẹsiwaju pe ‘’Wọn gba oriyin ni ọjọ naa, ti awọn akẹkọọ si ho gẹgẹ nigba ti wọn pari ere naa.’’

‘’Amọ nigba ti awọn Daramọla de pe awọn fẹ maa kopa lọ ninu ere itage naa ni ọjọ keji, mo sọ fun wọn pe rara, ko ṣeese.

Bi Fadeyi Oloro ṣe bẹrẹ iṣẹ oṣere ni gbagede niyẹn, to fi mọ Orisabunmi.’’

Bakan naa ni onimọ nipa ere itage naa sọ ọrọ iwuri nipa Fadeyi ati Orisabunmi gẹgẹ bi ẹni to ṣe e gbe ọkan le to si mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ.

O fikun un pe nigba naa, ko si iṣe ere itage ti ẹni ki wọn ṣe ti wọn ko le ṣee ni aṣeyọri.

''Lara awọn fiimu ti a jọ ṣe ni Igbo Olodumare, Igba Oro, Yanponyanrin, Arelu ati Agbarin.''