Ìjọba Eko yóò dá àwọn tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ BRT àti reluwé lọ́lá

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe oun yoo da awọn to farapa ninu ijamba ọkọ akero BRT ati reluwee lọla.
Ninu atẹjade kan to jade lọjọ Isẹgun, ni ijọba Eko ti seleri lati pese isẹ fun ọkan lara awọn ọmọ awọn to di oloogbe.
Bakan naa lo tun ni oun yoo tun pese eto ẹkọ ọfẹ fun wọn pẹlu.
Eyi waye lẹyin ti igbimọ ẹlẹni mẹsan ti ijọba gbe kalẹ lori isẹlẹ naa gbe esi iwadii rẹ kalẹ.
Atẹjade naa wi pe, " Esi iwadi ọhun fihan pe eeyan mẹfa ninu eeyan mejilelọgọrun lo ba isẹlẹ naa lọ.
Yatọ si ipese isẹ, igbimọ naa tun ni ki ijọba fawọn to fori kaasa isẹlẹ naa ni ẹkọ ọfẹ
Atẹjade naa fikun pe igbimọ oludanimọran naa tun ti daba pe ki ijọba pese isẹ fun awọn ọmọ awọn eeyan to ku, ki wọn si tun pese eto ẹkọ ọfẹ pẹlu.
"Igbimọ naa ti bẹrẹ lati sawari awọn mọlẹbi to kasa isẹlẹ naa lati beere oun to yẹ lẹsẹkẹsẹ."
Bakan naa ni Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe dirẹba ọkọ BRT to pa eniyan mẹfa nipinlẹ Eko lọ si ileẹjọ.
Dirẹba ọkọ naa lo lọ ko si ẹnu ọkọ oju irin ni agbegbe Ikẹja nilu Eko, ti eniyan mẹfa si ku ninu ijamba naa, amọ eniyan mẹrindinlọgọrun lo fi arapa.
Ọkọ ojurin naa ni o gbe ọkọ BRT naa ha ẹnu pẹlu awọn to wa ninu ibẹ titi to fi de agbegbe Sogunlẹ ni Ikeja.
Obìnrin tó fi ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù lu jìbìtì ₦47m sálọ, Adájọ́ fi ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ pamọ́ dè é

Oríṣun àwòrán, @OfficialEFCC
Ajọ EFCC to n gbogun tiwa ibajẹ ti fi ẹsun kan obinrin kan, Adanu Blessing Ajumi, pe o da ẹgbẹ alajẹsẹku silẹ lati fi gba owo lọwọ araalu lọna aitọ.
Adanu lo da ileesẹ kan silẹ to pe orukọ rẹ ni Emerald Multipurpose to jẹ ẹgbẹ alajẹsẹku, to si fi n hu iwa jibiti.
EFCC ni iwa lilu jibiti yii lo lodi si ofin ilẹ wa tọdun 2006 ati ofin ole jija ti ipinlẹ Eko tọdun 2011.
EFCC ti wa gbe ẹsun afurasi onijibiti naa lọ sile ẹjọ.
Afurasi naa, nigba to n farahan nile ẹjọ ni oun ko jẹbi ẹsun naa to bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlogun osu kejila ọdun 2019.
Lasiko igbẹjọ naa, eeyan mẹrin lo jẹri, ti wọn si mu aridaju ẹri wa si iwaju ile ẹjọ pe lootọ ni obinrin afurasi naa huwa jibiti.
"Adanu lo ọna arekereke lati gba owo to to ₦47m lọwọ obinrin kan fun ilo ara rẹ"
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan Adanu, Adajọ Mojisola Dada, ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ibajẹ to kalẹ si Ikeja nipinlẹ Eko, sọ pe Adanu Blessing Ajumi jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan.
Adajọ Dada ni laarin ọgbọnjọ osu kọkanla ọdun 2018 ati ọjọ kọkanla osu kinni ọdun 2019 ni obinrin naa hu iwa jibiti yii nipinlẹ Eko.
Adajọ ni Adanu lo ọna arekereke lati gba owo to to milliọnu to le ni mẹtadinlaadọta naira lọwọ Favour Bukola Nnamani fun lilo ara rẹ.
Adajọ Mojisola Dada ni ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe Blessing fi ọna aitọ gba owo tuulu naa nitori o fẹ gbe igbe aye ọlọrọ lai naani awọn to gba owo lowo wọn.
Amọ lasiko igbẹjọ naa, ti adajọ gba oniduro afurasi naa ni Blesssing ba fẹsẹ fẹ.
Sugbọn sibẹ, adajọ Dada ni o jẹbi, ijiya rẹ si n duro de nigba tawọn osiṣẹ alaabo ba ri mu pada wa fun ijiya to tọ, nibamu pẹlu ofin ilẹ wa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
















