Tinubu kìí ṣe ọ̀tá mi àmọ́ n kò ni lọ síbi ayẹyẹ ìbúra rẹ̀ - Bode George

Oríṣun àwòrán, Collage
Igbákejì alága àpapọ̀ tẹ́lẹ̀ fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Oloye Olabode George ti ní kìí ṣe wí pé òun kórira ààrẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu rárá.
Bode George ní nígbà tí ọmọ òun ṣe aláìsí, Tinubu kọ̀wé ńlá ránṣẹ́ sí òun láti bá òun kẹ́dùn lórí ikú ọmọ náà.
Àgbà olóṣèlú lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP náà, nígbà tó ń kópa lórí ètò kan ní iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán kan ní Eko, ní òun àti Tinubu kìí ṣe ọ̀tá.
Àmọ́ Bode George ní àwọn nǹkan kan wà, tí òun kò le ṣe fún-un.
"Bí n kò bá lọ síbi ayẹyẹ ìbúra fún Tinubu, kò túmọ̀ sí pé ọ̀tá ni èmi àti ẹ̀"
Nígbà tí wọ́n ń bi Bode George léèrè pé tí Tinubu bá pè é láti kópa níbi ètò ìbúrawọlé rẹ̀ ṣe ó máa lọ?
Bode George fèsì pé òun kò ní bá wọn kópa níbẹ̀ nítorí kìí ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú òun ni Tinubu wà.
“Tí Tinubu bá pè mí síbi ìbúra-wọlé rẹ̀, mi ò ní lọ, kìí ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà ni a wà nítorí nǹkan ẹgbẹ́ ni ìbúrawọlé.
Àmọ́ ó ní ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ọ̀tá ni èmi àti Tinubu.”
“Èmi àti Tinubu kìí ṣe ọ̀tá, mi ò kórìíra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, mi ò ní ẹ̀tọ́ láti kórìíra ẹnikẹ́ni, nígbà tí mo pàdánù ọmọ mi ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí mi.”
Bode George ní ọ̀rọ̀ tó kan orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀, tí ìmọ̀ àwọn kò sì ṣọ̀kan lórí rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Twitter
"Mi ò kábàámọ̀ pé mi ò ṣàtìlẹyìn fún Jandor"
Bode George, nígbà tó ń kópa lórí ètò iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán míì l‘Eko, ní òun kò kábàámọ̀ pé òun kò ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje sípò gómìnà Eko lẹ́gbẹ́ PDP, Olajide Adeniran, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Jandor lásìkò ìdìbò tó kọjá.
Ó ní ẹgbẹ́ kan tí òun wà lára rẹ̀ ni àwọn ti ṣe ìpinu pé olùdíje tó bá dáńtọ́ ni àwọn máa ṣe àtìlẹyìn fún láì ní fi ti ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe.
“A jókòó, a ṣàyẹ̀wò àwọn olùdíje tó ń wá ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Eko tó fẹ́ dada fún ìpínlẹ̀ wa.
A ṣe àgbéyẹ̀wò ètò ẹ̀kọ́ tí wọn kọ́, bí wọ́n ṣe lájú sí àti àyípadà tí wọ́n le mú bá ìpínlẹ̀ wa.”
“Nínú gbogbo wọn, mo ri wí pé ẹni tó le ṣe iṣẹ́ náà kìí ṣe olùdíje lẹ́gbẹ́ PDP, ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn ni olùdíje náà wà.”
Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ni Bode George ṣe àtìlẹyìn fún níbi ètò ìdìbò náà.
Àmọ́ Rhodes-Vivour pàdánù ipò sọ́wọ́ Babajide Sanwo-Olu tẹgbẹ́ òṣèlú APC.
A tako Funke Akindele tí Jandor mú ní igbákejì rẹ̀ ló fi gba òdo nínú ìbò gómìnà - PDP Eko

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti fesi si ẹsun ti oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, Abdulazeez Olajide, ti wọn n pe ni Jandor fi kan ẹgbẹ lẹyin idibo sipo gomina to waye nipinlẹ Eko.
Jandor lo fidi rẹmi ninu idibo naa, ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oṣelu APC si wọle fun saa keji.
Ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun osu kẹta ọdun 2023 ni eto idibo naa waye.
Lẹyin idibo naa ti Jandor ba BBC Yoruba sọrọ, lo ti ni awọn agba ẹgbẹ to n ṣiṣẹ tako oun lo jẹ ki oun fi idi rẹmi ninu idibo naa.
Jandor ko dibo ri, ko si fi ara balẹ, se lo n se bii ẹni to mọ gbogbo nnkan - PDP Eko
Amọ awọn asaaju ẹgbẹ oselu PDP ti kan si BBC Yoruba lori ẹsun ti Jandor fi kan wọn naa, ti wọn si salaye idi tawọn se tako aseyọri oludije gomina ti ẹgbẹ fa kalẹ naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Abiola Ismail ni yiyan gbajugbaja oṣerebinrin, Funke Akindele ni ko ba awọn agbaagba ẹgbẹ lara mu, ti wọn si sọ fun Jandor to jawọ ninu igbesẹ naa.
Amọ o ni se ni Jandor fi aake kọri lati se bẹẹ, to si tẹsiwaju lati kede Funke Akindele bii igbakeji rẹ fun gbogbo araye.
Abiola ni ‘’Igbakeji oludije to mu, lo kọkọ fa wahala nitori o lodi si ẹgbẹ lori ẹni to yan gẹgẹ bi igbakeji rẹ.’’
‘’O tun kọ lati ba awọn ẹgbẹ ṣe lati ijọba ibilẹ, n se lo n ṣe bi ẹni pe o mọ gbogbo nkan, bẹẹ ko ṣe idibo ri amọ ko fi ara balẹ rara.’’
‘’Ninu ẹgbẹ PDP ta wa yii, ẹgbẹ to ni ẹtọ ni ti Jandor si gbọdọ bọwọ fun ni.’’
‘’Nitori naa oun fun ara rẹ lo ṣiṣẹ to fi gba ọdọ nitori awọn igbesẹ to gbe.’’

Àìbọ̀wọ̀ fún àgbà ló mú kí Jandor gba òdo nínú ìbò gómínà l‘Eko- PDP
Abiola Ismail tun tẹsiwaju pe aibọwọ fun awọn agbaagba ẹgbẹ oselu PDP lo mu ki Jandor gba odo ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Eko.
‘’Jandor ko farabalẹ lati tẹlẹ ofin ẹgbẹ, n ṣe lo n tẹlẹ garagara’’
Abiola ni ki eniyan to le wa sinu ẹgbẹ PDP lati wa dije du ipo gomina , o yẹ ko ti lo ọdun kan si meji ninu ẹgbẹ.
Amọ ko ri bẹẹ fun Jandor, ti awọn agba ẹgbẹ si gba laaye ki o darapọ mọ wọn.
‘’Nigba to wa, n ṣe lo dọbalẹ pe ki wọn gba oun tọwọtẹṣẹ amọ to wa kẹyin si wọn bayii.
‘’Awọn ọrọ to sọ yii ko fidi imulẹ rara nitori Jandor ko farabalẹ lati mọ ilana ẹgbẹ, n ṣe ni Jandor n bẹ lati ibi kan si omiran’’
‘’O gbiyanju lati gba ẹgbẹ lọwọ awọn to ni ẹgbẹ, eleyii ti wọn ko gba a laye ko ṣe.’’
‘’Iwadii ta a se fihan pe Jandor kii ṣe ọmọ Eko ni’’

"Ọmọ Eruwa nipinlẹ Oyo ni baba Jandor, ti iya rẹ si jẹ Awori nipinlẹ Ogun"
Abiola Ishmael wa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ‘’Iwadii wa fihan pe Jandor kii ṣe ọmọ ipinlẹ Eko, amọ ọmọ Eruwa nipinlẹ Oyo ni baba Jandor, ti iya rẹ si jẹ Awori.’’
‘’Nitori naa o yẹ ki o fi ara balẹ ni lati bọwọ fun awọn agba to ba ni ipo.’’
‘’Ki o lọ tun iwa ara rẹ ṣe, ti o ba fẹ duro ninu ẹgbẹ lai yaju si ẹnikẹni ninu ẹgbẹ.’’
‘’Igba akọkọ kọ niyii to n hu iwa ti ko tọ si awọn ẹgbẹ, ti wọn si n fi ori jin amọ o ti kọja aye rẹ bayii.’’












