"Mò ń gba ₦100 lórí ₦10,000 torí mi ò fẹ́ ìnira fáráàlú bíi oní POS"

Àkọlé fídíò, Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni Oluwaseun Peter Adedeji tó ni iléeṣẹ́ PoS kan.
"Mò ń gba ₦100 lórí ₦10,000 torí mi ò fẹ́ ìnira fáráàlú bíi oní POS"

Láti ìgbà tí ọ̀wọ́n gógó owó náírà ti wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wàhálà tí àwọn ènìyàn ń kojú kí wọ́n tó rí owó gbà ni púpọ̀ nínú àwọn tó ń fi PoS ṣiṣẹ́ ti fi owó kún iye tí wọ́n ń gbà lórí owó.

Ṣaájú ọ̀wọ́n gógó yìí, ọgọ́rùn-ún náírà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ PoS máa ń gbà tí ènìyàn bá fẹ́ gba ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà ní ọwọ́ wọn.

Àmọ́ láti ìgbà tí ọ̀wọ́n gógó náà ti wà ọ̀pọ̀ wọn ló bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ọgọ́rùn-ún náírà, igba náírà, ọ̀ọ́dúnrún náírà lórí ẹgbẹ̀rún kan náírà péré.

Èyí sì ń mú kí àwọn ènìyàn máa kọminú kí wọ́n sì máa kígbe pé kò yẹ kí àwọn ènìyàn máa ni àwọn ènìyàn pàápàá mẹ̀kúnnù bíi ti wọn lára.

Iléeṣẹ́ PoS Adedeji ní Aklure, ìpínlẹ̀ Ondo
Àkọlé àwòrán, Iléeṣẹ́ PoS Adedeji ní Akure, ìpínlẹ̀ Ondo

Bí gbogbo ṣe wá rì yìí, àwọn òṣìṣẹ́ PoS kan kò jẹ́ kí iye èrè tí wọ́n máa rí tí wọ́n bá ń gba owó gegege yìí kó síwọn lójú, tó sì jẹ́ wí pé iye tí wọ́n ń gbà kí ọ̀wọ́n gógó yìí tó wáyé náà ni wan ṣì ń gbà títí di àsìkò yìí.

Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni Oluwaseun Peter Adedeji tó ni iléeṣẹ́ PoS kan ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Adedeji nígbà tó ń BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ṣàlàyé ìdí tí kò fi máa gba owó gọbọi lórí iye tí àwọn bá fẹ́ gbà lọ́wọ́ rẹ̀ lásìkò yìí.

Ó ní ọgọ́rùn-ún kan náírà ni òun ń gbà lọ́wọ́ àwọn tó bá fẹ́ gba owó lọ́wọ́ òun nítorí òun kò fẹ́ mú ayé nira fún àwọn ènìyàn.

Tí Nàìjíríà bá máa dára àárín ará ìlú ló ti ma kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀

Àwọn èrò tó tò láti gba owó níbi PoS Adedeji ní Akure
Àkọlé àwòrán, Àwọn èrò tó tò láti gba owó níbi PoS Adedeji ní Akure
Ènìyàn tó ti gba owó
Àkọlé àwòrán, Ènìyàn tó ti gba owó

Ó ṣàlàyé pé òun gbàgbọ́ pé tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bá máa dára, àárín àwọn ènìyàn àti ìdílé oníkálukú ló ti máa bẹ̀rẹ̀.

Adedeji ní owó tí àwọn ènìyàn tó máa ń fún òun náà ni òun ń pín fún àwọn tó bá fẹ́ gba owó lọ́wọ́ òun.

“Mo ri wí pé ìlú le mo dẹ̀ wo àwọn nǹkan ta le fi rọ ara wa lọ́rùn ni mi ò ṣe ń gba owó gọbọi àti pé àwọn oníbàárà mi tí wọ́n máa ń gba owó lọ́wọ́ nígbà tí gbogbo nǹkan dẹ̀ náà ni wọ́n ń wá lásìkò tí gbogbo rẹ̀ le yìí.”

Ó fi kun pé òun gbàgbọ́ pé kìí ṣe gbogbo nǹkan lowó àti pé gbogbo nǹkan ló ní àkókò àti pé ìbùkún Ọlọ́run lọ máa ń mú ènìyàn là.

“Bí ènìyàn bá ṣe pọ̀ nílẹ̀ sí ni a ṣe máa ń pín owó náà sí tó ma fi kárí gbogbo àwọn tó bá wà nílẹ̀.”

Bákan náà ló rọ àwọn tí wan ń ṣe irú òwò òun láti ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run kí wọ́n yé fi ayé ni àwón ènìyàn bíi ti wọn lára.