''Ìná ètò òsèlú Naijiria ń jó àjórẹ̀yìn nítorí àìsí ọ̀pọ̀ obìnrin tó díje dupo òselú''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Catrina Laing

Aṣoju Ilẹ Gẹẹsi si orilẹede Naijiria, Catriona Laing ti fi ero rẹ han lori idibo sipo aarẹ ati ti ipinlẹ to waye lorilẹede Naijiria

Laing ni awọn obinrin to wa lorilẹede Naijiria ni wọn ko fun ni anfaani lati dije du ipo oṣelu ni Naijiria.

O sọ eyi lasiko to n ba BBC sọrọ lori bi ko ṣe si ọpọ obinrin to n dije du ipo oṣelu ni idibo to ṣẹṣẹ kọja.

Asọju orilẹede Gẹẹsi si Naijiria ni iye awọn obinrin to dije su ipo aṣojuṣofin ni ile igbimọ aṣofin agba ti dinku ju ti saa to kọja ni ọdun 2019.

O ni eyi ti mu ki ina eto oṣelu ni Naijiria jo ajorẹyin.

Abilekọ Laing to ti wa lorilẹede Naijiria fun bi ọdun marun un ni obinrin akọkọ ti yoo di ipo aṣoju orilẹede Gẹẹsi si Naijiria mu.

O ni orilẹede Naijiria lo di ipo mẹtalelọgọfa ninu ipo mẹrindinlogoje ninu awọn orilẹede to gboriyin fun idọgba laarin akọ ati abo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọ o ni idunnu lo jẹ fun oun pe ọpọ obinrin ni Naijiria lo n fi akinkanju han kaakiri agbaye, amọ ti wọn ko gba wọn laaye lati fi akọ han ninu eto oṣelu lorilẹede wọn.

‘’Awọn obinrin ni Naijiria ni ẹbun loriṣirisi, amọ o ṣe ni laanu pe bi o tilẹ jẹpe awọn ni wọn di ida aadọta iye eniyan to wa lorilẹede Naijiria, wọn ko lẹnulọrọ ninu eto oṣelu ni Naijiria.

Arabinrin naa ni idunnu lo jẹ fun oun pe awọn akọni wa to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn di ipo nla mu ni agbaye.

Ìwọ́de ńlá bẹ́ sílẹ̀ ní Isreal torí òfin tuntun tí ìjọba gbé kalẹ̀

Awọn oluwọde ni Isreal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ń ṣe ni ìwọ́de tó lágbára bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Isreal lẹ́yìn tí olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè náà, Benjamin Netanyahu fọwọ́ òsì júwe ilé fún mínísítà fétò ààbò rẹ̀.

Yoav Gallant tó jẹ́ mínísítà fétò ààbò ló ti ṣaájú pariwo síta lórí ìgbésẹ̀ olóòtú ìjọba láti ṣe àtúntò àti àyípadà sẹ́ka ètò ìdájọ́.

Ní Jerusalem, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọmọ ogun lo ìbọn olómi láti fi tú àwọn tó ń ṣe ìwọ́de ní ẹ̀gbẹ́ ilé Netanyahu ká.

Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Ajé, ààrẹ Isreal Isaac Herzog ké sí ìjọba láti láti ṣe ìdádúró ètò náà.

Herzog lórí Twitter ní “fún ìṣọ̀kan àwọn ènìyàn Isreal, mo rọ̀ yín láti ṣe ìdádúró ìgbésẹ̀ yìí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀”, tó sì fi kun pé gbogbo ojú àwọn ènìyàn Isreal wà lára ìjọba.

Àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń fọ́n omi sí lára
Àkọlé àwòrán, Àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń fọ́n omi sí lára

Koko ohun to wa ninu ayipada ẹka eto idajọ to n bi araalu ninu ree

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà náà ní àwọn ń kọminú lórí ìgbésẹ̀ ìjọba yìí tí wọ́n sì ń pé fún ìfẹnukò gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.

Ṣíṣe ìwọ́de fún ọ̀sẹ̀ kan ni àwọn ènìyàn ti ń gbèrò lórí òfin tuntun yìí.

Lára àwọn tí wọn fẹ́ ṣe àtúnṣe rẹ̀ ni pé ìjọba yóò ní àṣẹ lórí ìgbìmọ̀ tó wà fún yíyan àwọn adájọ́.

Bákan náà ni yóò tún ṣòro fún ilé ẹjọ́ láti máa yọ adájọ́ tí wọ́n bá ri wí pé kò kájú òṣùwọ̀n èyí tó bí àwọn ará ìlú nínú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ gbé òfin náà kalẹ̀ láti fi ṣègbè fún olóòtú ìjọba Benjamin Netanyahu tó ń kojú ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu lọ́wọ́.

Netanyahu ní àwọn ń gbé òfin náà kalẹ̀ láti ṣe ìdádúró àwọn ilé ẹjọ́ láti yé lo agbára wọn kọjá bó ṣe yẹ, kí wọ́n sì lè máa rántí pé àwọn ènìyàn ló yàn wọ́n sípò.

N ko ni sun afi ti a ba fopin si ọrọ to wa nilẹ yii tori Netanyawu n se kọja agbara rẹ"

Ẹnìkan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba sọ fún BBC pé òun rò pé Netanyahu ti ń ṣe kọjá agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè tó ń ṣètò ìjọba àwaarawa.

Ó ní “mò ń ṣe ìwọ́de yìí láti fi dá ààbò bo ìjọba àwaarawa, mi ò sì le sùn àfi tí a ba fòpin sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí.”

Gallant ní ọjọ́ Àbámẹ́ta sọ̀rọ̀ lòdì sí òfin yìí, bó ṣe ní àwọn àwọn ọmọ ogun ni inú wọn kò dùn sí òfin tuntun náà.

Netanyahu ní òun kò ní ìgbàgbọ́ nínú Gallant mọ́ gẹ́gẹ́ bí mínísítà fétò ààbò òun mọ́ tó sì yọ́ kúrò ní ipò rẹ̀.

Lẹ́yìn tí Netanyahu yọ Gallant nípò ni Gallant kọ̀rọ̀ sórí Twitter rẹ̀ pé dídáààbò bo Isreal jẹ́ ohun tí òun mú ní òkúnkúndùn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí òun.

Olórí ẹgbẹ́ alátakò ní Isreal, Yair Lapid júwe yíyọ Gallant nípò gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò bójúmu fún ìjọba rárá.